Kí ni èrè rẹ nínú ilẹeṣẹ ìfọpo Dangote bayìí tí iléeṣẹ́ náà yóò bẹ̀rẹ̀ sí ń ta ìpín rẹ̀? Àlàyé rèé

Ileeṣẹ ifọpo Dangote, Dangote Petroleum and Petrochemical FZE, ti kede pe anfani ti wa bayii fun araalu lati ni ipin ninu ileeṣẹ naa.
Ileeṣẹ ọhun, to jẹ ibi ti wọn ti n fọ epo to tobi julọ nilẹ Afrika sọ pe 4.1 biliọnu ipin ọhun, iyẹn Initial Public Offer (IPO) ni oun gbe jade lasiko yii ti oun yo si maa ta ipin kan ni 525 naira.
Nibi ti wọn ti kede tita ipin naa niluu Eko lọjọ Aje, alaga ileeṣẹ ọhun, Alhaji Aliko Dangote sọ pe igbesẹ naa waye lati kowo jọ fun ileeṣẹ naa ko le gberu si.
Dangote sọ pe iye to kere julọ ti eeyan kan le ra ninu ipin naa ni mẹwaa pere, ti iye rẹ jẹ N5,250.
O sọ siwaju si pe awọn ti awọn nifẹ si julọ ko kopa ninu rira ipin naa ni awọn ti ko fi bẹẹ ri jajẹ lati ni ipin ninu ileeṣẹ naa.
Bẹrẹ lati ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹsan an, ọdun 2026 yii lawọn araalu yo lanfani lati bẹrẹ si n ra ipin ọhun.
Eyii ni igba akọkọ ti ileeṣẹ ifọpo Dangote yoo ta ipin rẹ lati ọdun 2023 ti wọn ti bẹrẹ si n fọ epo nibẹ.
Ki ni tita ipin ileeṣẹ ifọpo Dangote tumọ si fun ọmọ Naijiria?
Lati mọ ohun ti tita ipin ileesẹ ifọpo Danogte tumọ si fun awọn ọmọ Naijiria ati ohun ti yoo jẹ ere wọn ninu ileeṣẹ ọhun, BBC Yoruba kan si oluṣiro to tun jẹ onimọ nipa ọrọ to n lọ, Oluṣesan Okunade lati tan imọlẹ si ọrọ naa.
Gẹgẹ bi Okunade ṣe sọ, ohun ti eyii n tumọ ni pe ileeṣẹ ifọpo Dangote ti di ajọni fun awọn ọmọ Naijiria.
O ni "Ko ni jẹ pe Dangote nikan ni a o maa sọ pe o ni i, o ti wa jẹ ti akojọpọ awọn to ti fi owo wọn sinu ileeṣẹ naa bayii.
"Anfani to wa nibẹ ni pe kii ṣe Danogte nikan lo ni i mọ bayii, funra rẹ Dangote le jẹ ẹni to ni ohun to pọju ninu rẹ, o ti di ohun ti ọpọlọpọ ni.
"Gbogbo wa ti di alajọni ileeṣẹ naa, to ba si di ipari ọdun, ti wọn ba ṣe ohun to yẹ, wọn maa jabo fun awọn to lowo ninu rẹ, wọn si maa fun wọn ninu ere wọn..

Ṣe Dangoe maa yi orukọ pada si PLC bayii ni?
Onimọ naa sọ pe tita ipin ninu ileeṣẹ naa lọwọ yii ko tumọ si pe Dangote maa yi orukọ rẹ pada.
O sọ siwaju si pe awọn eeyan to ba ra ipi naa yoo jere ti ileeṣẹ Dangote ba jere.
Amọ ko tumọ si pe wọn maa padanu owo wọn ti Dangote ba padanu owo bo tilẹ jẹ pe wọn le ma ri ida ere wọn 'dividends' gba fun ọdun naa.
Ṣe owo epo bentiro maa walẹ bayii?
Ni ti iye ti wọn n ta epo bẹntiro ni Naijiria bayii, Okunade sọ pe tita ipin Dangote ko tumọ si pe owo epo bẹntiro yoo ja walẹ ni Naijiiria.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni awọn ohun to n sọ nipa iye ti wọn n ta epo bẹntiro kaakiri agbaye, lara awọn nnkan naa ni igbesẹ ijọba, tabi ogun, bii eyii to n waye laarin Amẹrika ati Israel pẹlu Iran.
O fi kun pe lara ọna ti owo epo fi le ja walẹ ni ti ijọba ba gba awọn ọmọ Naijiria mii laaye lati ṣi ileeṣẹ ifọpo ti wọn.
O pari ọrọ rẹ pe ti ileeṣẹ to n fọ ep oba pọ ni Naijiria, ti awọn araalu i lanfani lati yan ileeṣẹ ti wọn yoo ra epo lọwọ rẹ, owo epo yoo walẹ ju igba ti ẹnikan ṣoṣo ba n jẹ gaba lori rẹ lọ.




























