Sẹ́nétọ̀ Buba sọ̀rọ̀ lórí fídíò tó gba orí ayélujára pé ó ṣàtìlẹyìn fáwọn agbébọn

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ni opin ọsẹ ni fidio kan ti gba ori ayelujara nibi ti ọkunrin kan ti pe orukọ ara rẹ ni Hassan fẹsun kan Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun guusu ipinlẹ Bauchi ni ile aṣofin agba ilu Abuja, Shehu Buba, wi pe o ṣe atilẹyin fawọn agbebọn.
Ninu fidio naa ni Hassan ti fẹsun kan pe niṣe ni Sẹnetọ naa n idanilẹkọọ fawọn agbebọn to pe orukọ wọn ni Babangida ati Lema.
O ni lasiko ti Sẹnetọ ko awon eeyan naa si ile rẹ to wa ni ilu Abuja ni oun ri bi wọn ṣe n ṣe idanilẹkọọ fawọn eeyan naa, ti oun si ya aworan wọn lati inu ile igbọnsẹ ti oun fara pamọ si.
Amọ Sẹnetọ Shehu Buba ti jiyan awọn ẹsun ti ọkunrin naa fi kan an.
Hassan tun fẹsun kan pe Sẹnetọ Buba tun n ṣe atilẹyin fun ogbontarigi agbebọn nni, Bello Turji ati pe o maa n fun ni awọn nnkan ija ogun ti wọn n lo.
O sọ pe ninu ile Sẹnetọ ni wọn ti ṣe idanilẹkọọ fun awọn agbebọn naa ti oun si pe ọkan lara awọn ẹṣọ aabo ọtẹlẹmuyẹ pe wọn n ṣe idanilẹkọọ fawọn agbebọn ninu ile rẹ.
O ni oṣiṣẹ aabo ti oun pe nigba naa sọ pe awọn ko le ṣe ohunkohun nitori alagbara ni oloṣelu ni o n ṣe atilẹyin fun wọn.
O fi kun pe idi ti oun fi n jade sọrọ, ni pe oun awọn ẹri to daju tako Sẹnetọ naa lori awọn ẹsun yii.
O tun sọ pe baba ogbontarigi agbebọn, Dogo Gide wa lara awọn to maa n lọ si ile Sẹnetọ Buba ati pe niṣe ni wọn gbe lọ si Abuja lati ṣe idanilẹkọọ Pataki kan fun-un latọwọ senetọ naa.
Hassan tun ni oun maa tọrọ aforiji lọwọ Sẹnetọ naa to ba mu ẹri jade pe ijọba Naijiria lo fun laṣẹ lati maa ṣe idanilẹkọọ fun awọn agbebọn naa ni ilu Abuja.
O ni gbogbo awọn fidio ti oun gbe jade naa lo jẹ eyi ti oun ṣe nigba ti oun wa ninu ile Sẹnetọ naa.
Shehu Buba fesi
Ṣugbọn Sẹnetọ Shehu Buba ti wa jiyan gbogbo awọn ẹsun ti Hassan fi kan an to si ni gbogbo awọn fidio ti wọn gbe jade naa lati fi ba oun lorukọ jẹ ni.
Buba, to ti figba kan ri jẹ alaga igbimọ to n ri si ọrọ aabo nile igbimọ aṣofin agba Naijiria, lo ti n koju ẹsun ṣiṣe atilẹyin fawọn agbebọn lati ọdun 2024 amọ to maa n jiyan awọn ẹsun naa.
Atẹjade kan ti Buba fi lede lọjọ Aiku sọ pe oun gbiyanju lati ma sọ ohunkohun lori awọn ẹsun ti wọn fi kan oun nitori ọrọ aabo to jẹ amọ kii ṣe pe didakẹ oun tumọ si pe oun ko le fesi sawọn ẹsun naa.
Sẹnetọ naa sọ pe ni oṣu Kẹsan-an ọdun 2024 ni awuyewuye ti n jẹyọ lori oun nigba ti oun ṣe abẹwo sawọn ẹbi eleedu meji kan nigba ti ikọlu ti Umar Shayi ṣaaju ikọ kan ti wọn pe ara wọn ni ọdẹ to n ṣiṣẹ pẹlu ikọ fijilante ipinlẹ Bauchi.
O ni nigba ti oun ṣabẹwo sawọn ẹbi naa ni oun rọ ijọba lati ṣewadii iṣẹlẹ ki wọn si fi oju awọn ti wọn lọwọ ninu ikọlu naa wina ofin, ti oun si jẹjẹẹ lati ri daju pe tuṣu de isalẹ ikoko iṣlẹ naa titi ti awọn to lọwọ ninu rẹ fi maa foju wina ofin.
Buba ni lẹyin naa ni Kọmiṣanna fọrọ abẹnu ipinlẹ Bauchi kede orukọ oun bi ẹni to n ṣe atilẹyin ati agbodegba fawọn agbebọn, ti wọn si tun fẹsun kan oun pe oun ran awọn agbebọn lọ si Hajj lọdun 2024.
O ni lati igba naa ni oun ti jiyan ẹsun naa, ti oun si ke si awọn ẹṣọ aabo lati ṣewadii oun to ba jẹ pe oun jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi n kan oun.
O fi kun pe lẹyin naa ni Gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed tun kọ iwe ẹsun ranṣẹ si Aarẹ Bola Tinubu pe oun n ṣatilẹyin fawọn agbebọn ati pe oun tun ran ọkan lara wọn lọ si Hajj 2024.
O ni gbogbo iranwọ ti oun n ṣe fawọn eeyan yala lori eto ẹkọ, ilera ati ironilagbara lo jẹ eyi ti oun maa n ṣe fun awọn eeyan tawọn ara ilu atawọn olori ẹsin ba sọ fun oun pe awọn lo tọ si.
"Awọn fidio ti ko jọ ara wọn ni wọn to papọ lati fẹ fi bami lorukọ jẹ"
Nigba to n sọrọ lori awọn fidio ati aworan ti Hassan fi sori ayelujara lenu ọjọ mẹta yii, Buba sọ pe ni ọdun 2024 ni wọn mu Hassan wa ba oun pe ọmọ orukan to nilo iranlọwọ lori eto ẹkọ rẹ ni.
O ni eyi lo mu oun fi sile ẹkọ kan ni ipinlẹ Kaduna ti oun si ra kẹkẹ fun-un amọ to pa ile ẹkọ naa ti to si beere owo lọwọ oun lati fi bẹẹrẹ okoowo mọto tita eyi ti oun kọ lati ṣe fun, ti oun si ni ko pada sẹnu ẹkọ rẹ.
O ni ko pẹ ni oun ri pe o ti n wa aworan atawọn fidio awọn alejo to n wa oun wa sile to fi mọ awọn to ba ti Hajj de ti wọn wa ki oun.
O sọ pe awọn fidio ati aworan yii lo n gbe sori ayelujara lẹnu ọjọ mẹta yii lati maa fi ẹsun ṣiṣe atilẹyin fawọn agbebọn kan oun.
Sẹnetọ naa tun fẹsun kan pe awọn to gbe fidio naa sori ayelujara wa beere owo lọwọ oun ti oun si gbe ọrọ naa lọ sọdọ awọn ọlọpaa, ti wọn si panpẹ ofin gbe awọn afurasi marun-un.
Lori awọn fidio to ṣẹṣẹ gba ori ayelujara bayii, Buba ni ọpọ awọn fidio naa ni kii ṣe ootọ nitori wọn kan ko awọn fidio ti ko jọ ara wọn pọ ni, to fi mọ awọn fidio awọn to ṣẹṣẹ de lati Hajj ti wọn ṣe abẹwo sile oun lọdun 2023.
O fi kun pe oun ti kọwe ranṣe si ijọba Niger Republic lati fẹsun ibanilorukọ jẹ kan Hassan Hussein.
O sọ siwaju pe loootọ ni oun tig be aba kalẹ siwaju ile aṣofin pe bi fifi ọwọ lile mu awọn agbebọn ṣẹ ṣe Pataki naa ni o pọn dandan lati lo ilana ijiroro pẹlu awọn agbebọn nitori Naijiria ko le koju ipenija aabo lai lo ilana mejeeji.
O ni oun ko le sọ gbogbo igbesẹ ti awọn n gbe lati wa ojutuu si iṣoro aabo Naijiria nita gbangba nitori aabo.
Bakan naa lo fi kun pe fifi ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC silẹ lọsinu egbẹ oṣelu Peoples Redemption Party, PRP wa lara ohun ti wọn fi n tabuku ati biba oun lorukọ jẹ.
Awọn oloṣelu ti wọn fẹsun kan pe wọn n ṣatileyin fawọn agbeṣumọmi ati agbebọn
Igba akọkọ kọ niyi ti wọn yoo maa fi ẹsun kan awọn oloṣelu lori ayelujara pe wọn ṣe n atileyin fawọn agbeṣumọmi ati agbebọn.
Ṣaaju Shehu Buba yii ni ẹnu ti maa n kun awọn eekan oloṣelu paapaa lẹkun ariwa Naijiria pe awọn lo n kun awọn agbebọn lọwọ lati maa da omi alaafia ilu ru
Lara awọn ti ẹnu tik un ri ni
Gomina ipinlẹ Borno tẹlẹ ri, Ali Modu Sheriff
Gomina ipinlẹ Sokoto tẹlẹ ri, Attahiru Bafarawa
Sẹnetọ Ali Ndume
Yatọ si awọn oloṣelu yii, agba onimọ Islam, Sheikh Gumi ni awọn eeyan tun maa n fẹsun kan pe o n ṣe atilẹyin fawọn agbebọn nitori awọn nnkan to maa n sọ pe ki ijọba dunaadura pẹlu awọn agbebọn lo le tan iṣoro aabo ni Naijiria.



























