Kí ló dé tí orin K1 "Tó bá lóyún kóyún, sàárà ni" fi ń mi orí ayélujára tìtì? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, K1 deUltimate/Instagram
Orin kan ti agbaọjẹ olorin Fuji, King Wasiu Ayinde Marshal, KWAM1 De Ultimate, ṣẹṣẹ gbe jade eyi to pe akọle rẹ ni ''To ba loyun koyun, saara ni'' ti di nnkan ti ọpọ eeyan n sọ nipa rẹ bayii lori itakun ayelujara.
Amọ, ki lo ṣẹlẹ gan an ti orin naa fi di nnkan ti ọpọ eeyan n sọrọ le lori?
Ohun ti ọpọ eeyan n sọ ni pe obinrin kan to ti sọrọ ṣaaju lori ayelujara wi pe K1 loun bi ọmọdebinrin kan fun ni ilumọọka akọrin naa fi orin yii ba a wi.
Obinrin yii sọ ninu fọnran to ti lu ori ayelujara pa bayii wi pe ọdun meje loun ati Wasiu Ayinde fi fẹ ara awọn.
O ni lasiko ti ina ifẹ awọn n jo yii ni oun loyun ti oun si bi ọmọbinrin kan torukọ rẹ n jẹ Azizat fun K1.
Gẹgẹ bi obinrin naa ṣe ṣalaye, o ni gbajugbaja akọrin naa sọ fun oun wi pe ki oun ṣẹ oyun ọmọ naa tori oun ko ṣetan lati gba oyun rẹ.
''Nigba ti mo sọ fun un pe mo loyun, K1 ni oun o ṣetan lati gba oyun wi pe ki n lọ ṣẹ oyun ọhun.
O ni oun yoo fi owo ran ọkan lara awọn ọmọlẹyin oun si mi lati le ṣẹ oyun naa,'' obinrin naa lo sọ bẹẹ.
Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ pe ṣe ootọ ni pe K1 ni o loyun ọhun fun, o sọ pe bẹẹ ni.
Obinrin naa fikun ọrọ rẹ pe lẹnu iṣẹ oun ti oun ti n ṣe irun ti oun si tun n ṣe eekanna loge loun ti pade Alhaji Wasiu Ayinde.
O ni nigba to ya loun maa n lọ ṣiṣẹ fun K1 nile rẹ.
''Mo mu ọmọ ti mo bi fun K1 lọ sọdọ mama rẹ ki o to ku''
Arabinrin naa sọ pe oun gbe ọrọ yii lọ sọdọ Kabiyesi Agba Akin ti wọn ti waja bayii nigba ti ọmọ toun bi fun K1 pe ọmọ ọdun ọkan.
O ni kabiyesi naa pe agbaọjẹ olorin Fuji naa lori foonu nigba naa lori ọrọ ọhun.
Bakan naa ni o tun sọ pe oun tun lọ ba mama K1 lori ọrọ ọmọ oun Azizat, mama si ṣe bi abiamọ nigba ti wọn ri ọmọ naa.
Arabinrin naa ni mama sọ pe ''ah, mo si wa laye, mo wa bi ara mi'' eyi to ni o tumọ si pe Azizat jọ mama K1.
Ṣugbọn ṣa, K1 ti sọ ninu orin to ṣẹṣẹ gbe jade bayii wi pe saara ni oyun kohun ti ẹnikẹni ba ni, bo tilẹ jẹ ko darukọ obinrin naa.
Alhaji Wasiu Ayinde sọ ninu orin wi pe kawọn eeyan tan ẹrọ Bluetooth wọn silẹ ki wọn si gbe nnkan toun sọ lọ sori oniruuru itakun ayelujara bii Facebook, TikTok, Instagram ati lori X.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post





























