Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀tọ̀ ni mo rí Satani, mo tún rí ẹnu ọ̀nà ọ̀run àpáàdì – Pope Francis

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olori ijọ Aguda lagbaye nigba kan, Pope Francis ti sọ pe igba mẹta ọtọtọ loun ri satani nigba aye oun, bẹẹ loun tun ri ri ẹnu ọna ọrun apaadi.
Ọrọ naa lo jẹyọ ninu akọsilẹ rẹ ti wọn ṣẹṣẹ ko jade.
Ninu iwe naa ti orukọ rẹ n jẹ 'The Private Diary of Pope Francis' ti wọn ko jade lọjọ Iṣẹgun, o sọ nibẹ pe lọdun 2021, oun ri iran mẹta ọtọtọ nibi ti oun ti ri satani.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ri satani lati inu ọkọ ayọkẹlẹ, ekeji nibi ti awọn ẹgbẹ akọrin maa n wa lasiko adura, nigba ti ẹẹkẹta jẹ lasiko ipade kan pẹlu awọn oṣiṣẹ Vatican.
O sọ ninu iwe naa pe "Mi o le gbagbe bi ohun rẹ ṣe lagbara to."
Ninu akọsilẹ naa to kọ sinu iwe apamọ diary rẹ lati ọdun 1992 si ọdun 2024, o tun kabamọ nipa abẹwo rẹ si orilẹede Chile, nibi ti awọn kan ti bu ẹnu atẹ lu u fun bo ṣe ṣegbe lẹyin biṣọọbu kan ti wọn ni o bo aṣiri ẹsun ibalopo ti wọn fi kan alufaa kan nibẹ.
Francis, to ti tukọ ijọ Aguda fun ọdun mejila gbako titi di ọdun 2025 to dagbere faye pada tuba, o si ke si awọn biṣọọbu orilẹede naa siluu Rome, nibi ti gbogbo ti wọn ti kọwe fi ipo wọn silẹ.
O kọ sinu akọsilẹ naa lọdun 2021 pe "Ohun to ṣẹlẹ ni Chile ba inu mi jẹ gidi.
"O ṣoro fun mi lati gba ohun to ṣẹlẹ ni Chile; mi o ro pe ohun to lagbara to bẹẹ ni. Lasiko naa"
Nipa awọn iran to ri ninu eyii to ti ri satani, Francis sọ pe oun ko le gbagbe bi ohun rẹ ṣe ri.
Francis ṣalaye "O wo mi pẹlu ina loju rẹ… ina ọhun naa pọ ju eyii ti mo ri ṣaaju. Niṣe ni wọn da bii ina to n ṣẹyọ."
O ni oun ri lojukoju, bẹẹ ni oun si gbọ ohun rẹ.
Olori ijọ Aguda tẹlẹ naa tun sọ pe oun ri ẹnu ọna ọrun apaadi nigba to n mura lati sun ninu oṣu Kẹfa, ọdun 2018.
O kọ ninu akọsilẹ naa pe "Mo wo o fun igba diẹ, ẹru si ba mi. O lewu lati sunmọ ẹnu ọna ọrun apaadi nitori ina inu rẹ le ru jade ko si jo eeyan."
Akọsilẹ yii, ti Cardinal Victor Fernandez to jẹ olori awọn to n kọ nnkan silẹ Vatican ṣe ayẹwo rẹ ni akọkọ iru rẹ lẹyin ọdun 1960.



























