Inú mi kò dùn nígbà tí Taiwo mi ṣe ìgbéyàwó torí ó dà bí ẹni pé wọ́n gba ìyàwó mi ni - Kehinde Afolabi

Awọn ibeji kan, Tayelolu ọmọ Afolabi ati Kehinde Gabriel Afolabi, ree ti ina ifẹ to wa laarin si n jo lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti onikaluku wọn ti ni idile tireẹ.
Arabinrin Taiwo sọ fun BBC News Yoruba wi pe ''ilakọja wa kii ṣe kekere nitori ọdun 1970 ni baba wa ku.
Iku yajo yajo ni baba wa ku tori o ba wa lojiji.
Iku baba wa lo jẹ ki emi ati ekeji mi di ẹni ti ko le lọ ile iwe mọ.
Bayii ni awa mejeeji ṣe lọ kọ iṣẹ, koda,ọjọ kan naa ni a gba iyọnda lẹnu iṣẹ.
Iṣẹ aranṣọ ni emi kọ nigba ti Kehinde mi kọ iṣẹ fọto yiya.''
Ọgbẹni Kehinde Afolabi sọ pe oun loun buru ju nigba tawọn n dagba, amọ, baba naa ni oun ti yi pada bayii.
O ni ti eeyan ba ti n dagba, eeyan maa n yọ ogun ja ni.
''Emi ati ekeji mi kii ja nigba ti a wa ni kekere, koda, kilaasi kan naa ni a jọ wa.
Ọdun 1978 ni Taye mi ṣe igbeyawo, o si bimọ lọdun 1979.
Inu mi ko dun si igbeyawo rẹ tori o da bi ẹni pe wọn gba iyawo mi ni.
Mo maa n beere lọwọ awọn ti wọn maa n sọ pe Tayelolu lagba pe ṣe ọjọ kan naa kọ ni wọn bi awa mejeeji ni?'' Ọgbẹni Afolabi lo sọ bẹẹ.
Arabinrin Taiwo ni nigba kugba ti Taye oun ba sọ pe oun lagba loun maa n sọ fun un wi pe oun loun kọkọ de ile aye.
Arabinrin Taiwo ni oun ati ekeji oun jọ maa n dawọ lu ẹnikẹni to ba doju ija ko Kehinde oun nigba tawọn wa ni kekere.
























