'Scholarship 20 ni mo kọ̀wé fún, ṣùgbọ́n mẹ́rin péré ni mo rí gbà' - Akẹ́kọ̀ọ́ First Class

Oríṣun àwòrán, Bilesanmi Tobiloba
Laipẹ yii ni fasiti ilu Ilọrin nipinlẹ Kwara ṣeto ayẹyẹ ikẹkọọgboye, ti wọn si ṣafihan awọn akẹkọọgboye ti wọn peregede julọ lẹnu ẹkọ wọn.
Bilesanmi Tobiloba naa wa lara awọn akẹkọọgboye tuntunt o ṣe daadaa ni fasiti naa.
Nigba to n ba BBC sọrọ, ọmọbinrin naa ṣalaye irin ajo rẹ, ati bo ṣe tiraka lati de ipo naa, pẹlu afojusun rẹ lẹyin ọdun marun-un si asiko yii.
Bilesanmi sọ pe oun ko wa lati inu idile olowo, ṣugbọn to sọ pe awọn obi oun tiraka lati ran oun atawọn yooku oun nile ẹkọ, lati ṣe aṣeyọri.
"Mo wa lati inu idile ti kii ṣe olowo, awọn obi mi si tiraka lati rii pe wọn fun emi ati awọn yooku mi ni ẹkọ to yege," o sọ bẹẹ fun BBC.
Ọmọbinrin naa ṣalaye pe ko rọrun lati kekọọgboye ipo akọkọ, ṣugbọn to jẹ ko di mimọ pe ipinnu toun ṣe lati ibẹrẹ pẹpẹ lo jẹ ko rọrun foun diẹ.
Tobiloba sọ pe koun too wọle ẹkọ fasiti naa loun ti nii lọkan wi pe oun fẹẹ kọkọọgboye ipo akọkọ, to si loun ṣiṣẹ tọ ọ nipa kika iwe ni gbogbo igba.
"Jijade ile-ẹkọ pẹlu ipele akọkọ ko rọrun rara, ṣugbọn o dabi wi pe o rọrun nitori pe o jẹ ipinnu ọkan mi latigba ti mo ti wọ ileewe ni ipele akọkọ," Tobiloba sọ bẹẹ.
O ni ko jẹ tuntun wi pe oun kẹkọọ yege, nitori pe lati ile-ẹkọ alakọbẹrẹ loun ti n gba ipo kinni, titi de girama, to fi wa de fasiti.
"Nile-ẹkọ alakọbẹre, mo ṣetan gẹgẹ bi akẹkọọ to yanranti, ni ile-ẹkọ girama, bẹẹ naa ni mo ṣetan gẹgẹ bi akekọọ to yanranti.
"Igba ti mo wọ ileewe fasiti, mo ni lọkan pe mo fẹẹ ṣe daadaa funra mi, mo si fẹẹ jade pẹlu ipele akọkọ, iyen lo jẹ ko rọrun diẹ, ṣugbọn jijade pẹlu ipele akọkọ funra re ko rọrun, nitori pe o gba orisirisi ifarajin," o fidi rẹ mulẹ.
"Mo ni oye ara mi"
Tobiloba jẹ ko di mimọ pe oun ko fẹran lati maa kawe laaarin oru, gẹgẹ bi awọn kan ṣe fẹran rẹ, to si ni gbogbo ọsan loun fi maa n ka iwe, koda, toun yoo tun lọ si yara ikawe lati kẹkọọ siwaju sii.
"Mo ni oye ara mi, mo jẹ akẹkọọ to jẹ pe igba oojọ ni mo maa n kawe, mi o kii fibẹẹ kawe loru," Tobiloba sọ bẹẹ fun BBC.
O ni, "To ba ti di pe mi o ni kilaasi, mi o si ni ibikankan lati lọ, maa lọ si yara ikawe, maa lọ kawe fun wakati diẹ, ki n too tun pada lọ si ile lati lọ sinmi diẹ."
"Anfaani eto ẹkọ ọfẹ ti mo jẹ"
End of podcast promotion
Tobiloba, nigba to n sọrọ nipa bo ṣe ri anfaani eto ekọ ọfẹ gba, eyi to jẹ ki ẹkọ rọrun fun un, o ni gbara toun ti wọ fasiti naa loun ti gbọ nipa anfaani eto ẹkọ ọfẹ, to si loun rii pe akẹkọọ gbọdọ ni awọn ohun amuyẹ kan, ko too bọ si.
O ni kete toun ti ri awọn ohun amuyẹ ti wọn n beere, loun ti mọ daju pe oun le yege fun anfaani naa, to si loun tẹpa mọ eto ẹkọ oun lati rii pe oun je anfaanim naa.
"Igba ti mo wọ ileewe, mo rii wi pe awọn eeyan maa fi orukọ silẹ fun ẹkọ ọfẹ, to dẹ dabi owo ọƒẹ, teeyan ba ti fun wọn ni awọn nnkan ti wọn n beere, bii koo ni esi idanwo to dara, ko ni afojusun ibi ti o n lọ lọjọ iwaju.
"Igba ti mo rii pe awọn nnkan ti wọn n beere yii je awọn nnkan ti mo le ṣe, ohun ni mo ṣe ṣiṣẹ fun ipele akọkọ mi. Igba ti mo ti gba ipele akọkọ naa ni ipele akọkọ, mo wa bẹrẹ sii forukọ silẹ fun awọn eto ẹkọ ọfẹ naa," Bilesanmi sọ bẹẹ.
O ni ọna to to ogun loun ti forukọsile, ṣugbọn to jẹ pe mẹrin pere lo bọ sii foun, to si lo ṣe iranlọwọ to pọ foun ninu eto ekọ oun ni fasiti Ilorin.
"Mo forukọsilẹ nibi to to ogun, ti mo si fi ri bii mẹrin yii. Riri eto ẹkọ ọfẹ yii jẹ ki ileewe rọrun fun mi diẹ si, kii ṣe gbogbo igba ni mo maa n pe ile fun owo."
Ọjọ ti inu mi bajẹ ju
Nigba to n sọ fun BBC nipa adojukọ ati ọjọ ti inu rẹ bajẹ julọ, Tobiloba jẹ ko di mimọ pe boun ṣe padanu idanwo kan ninu marun-un to ṣe.
O sọ pe idanwo kan ṣoṣo naa ni ko jẹ koun gboye gẹgẹ bii akọṣẹmọṣẹ onimọ iṣiro.
"Ọjọ ti inu mi bajẹ ju nileewe ni ọjọ ti kuna ninu idanwo ICAN mi, iṣẹ kan ni mo kuna ninu iṣẹ marun-un ti mo kọ idanwo rẹ.
"Inu mi bajẹ nitori pe leyin idanwo naa lo ye ki n di akọṣẹmọṣẹ onimọ iṣiro, ṣugbọn iyẹn sun siwaju diẹ nitori iṣẹ ti mo tun nilo lati tunkọ."
"Afojusun mi"
"Awọn to wa ni ijọba n gbiyanju, ṣugbọn mo lero wi pe ti mo ba ni anfaani lati wa lara awọn to n gbe ilana kalẹ, maa ri iyatọ mu wa si bi eto ọrọ aje orileede wa ṣe ri, ati agbaye.
"Awokọse mi ni Ngozi Okonjo Iweala, ẹni to jẹ alakoso agba fun ileeṣẹ eto okoowo agbaye bi a ṣe n sọrọ lọwọlọwọ yii, o dẹ ri wi pe ibi nnkna pataki ti wọn ti bere igbe aye wọn ni banki agbaye. Fun idi eyi, ọdun marun-un si asiko yii, mo lero wi pe maa ti pari 'Masters' mi, maa si ribi wọle si banki agbaye pẹlu eto awọn akọṣẹmọ ti ọdọ ti wọn maa n ṣe.
"Imọran mi fun awọn to ba fẹẹ yege nidi ẹkọ wọn, o se koko ki wọn ni ipinnu yẹn lati ibẹrẹ pẹpẹ wi pe wọn fẹẹ se daadaa nidi ẹkọ wọn, ki wọn si ṣiṣẹ tọ ọ."




























