Ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina dá Emir Daura dúró lórí ẹ̀sùn fífi ọwọ́ kan obìnrin arìnrìnàjò lọ́nà àìtọ́

Emir ilu Daura,Alhaji Umar Faruk Umar
Àkọlé àwòrán, Emir ilu Daura,Alhaji Umar Faruk Umar
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lẹyin fidio kan to jade, eyi to ṣafihan Emir ilu Daura, nipinlẹ Katsina, Alhaji Umar Faruk Umar, ti wọn lo n fọwọ kan obinrin arinrinajo kan lọna aitọ, ijọba ipinlẹ naa ti paṣẹ pe ki Emir ọhun lọọ rọ ọ kun nile na.

Aṣẹ to da Emir naa duro sọ pe ko gbọdọ kopa ninu gbogbo ohun to ba jẹ mọ iṣakoso, bẹẹ ni ko gbọdọ rin awọn irinajo kan mọ.

Eyi wa ninu atẹjade ti Kọmiṣanna fun eto Iroyina ti Aṣa ni Katsina, Bala Salisu Zango, fi sita lọjọ kẹrinlelogun oṣu Kọkanla ọdun 2026 yii.

Atẹjade naa ṣalaye pe ijọba ti gbe igbimọ oluwadii kan dide lati wadii ẹsun ti wọn fi kan Emir Umar Faruk Umar.

Ijọba ipinlẹ Katsina wa rọ awọn eeyan lati ni suuru lori ọrọ yii, ki wọn tẹle ofin bi wọn ṣe n ba iṣẹ oojọ wọn lọ.

Wahala yii bẹrẹ nigba ti fidio ṣafihan ọkan lara awọn Emir ti ọpọ eeyan n bọwọ fun lapa Ariwa, to di ẹni ti wọn n fẹsun kan pe o fi ọwọ kan obinrin ajeji lọna aitọ.

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Ninu fidio to da wahala silẹ fun Emir ilu Daura yii, o ṣafihan obinrin kan ati ọkunrin ti igbagbọ wa pe Emir Daura, Alhaji Faruk Umar Faruk ni.

Obinrin to pe ara rẹ ni Bequinqa lori Instagram lo n sọrọ ninu fidio naa to si ni:

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Lara awọn nnkan to wu mi lori ni gbigbọ itan nipa Daura,nitori tẹlẹ, obinrin lo n dari Daura."

Obinrin naa sọ pe oun ka fidio yii silẹ pẹlu igo oju oun, to ni kamẹra ninu, eyi ti a mọ si "Meta glasses."

Ninu fidio naa ni obinrin yii ti n kọkọ rẹrin-in pẹlu ọkunrin agbalagba ti wọn jọ wa ninu aafin nla to rẹwa kan. Ọkunrin naa ni iroyin si sọ pe Emir Umar ti Daura ni.

Ṣugbọn ko pẹ ti obinrin oyinbo to wa fun irinajo afẹ naa fi bẹrẹ si i sọ pe "Rara, rara, rara" Eyi to fi n da baba agba ti wọn jọ wa naa lẹkun lati yee fi ọwọ kan oun.

Iroyin to jade lẹyin eyi ni pe Emir Umar, ẹni ti wọn pe ni ẹni ọdun mejilelaadọrun (92) n fọwọ tẹ obinrin ajeji naa lọyan lasiko ọhun ni, lo jẹ ki oyinbo maa sọ "No, no, no" ninu fidio naa.

Obinrin naa tun pada sọ pe ki baba ma fi ọwọ kan ibẹ yẹn rara.

Bequinqa ṣalaye pe oṣu Kọkanla yii ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, nigba toun wa ni Naijiria, amọ oun ko fi fidio naa sita nigba toun wa ni Naijriia nitori aabo oun.

Latigba ti fidio ọhun ti gun ori ayelujara ni ọpọ eeyan ti n sọrọ lorii rẹ, to si fa a ti Emir naa fi gba iwe lọ rọ ọ kun nile bayii latọwọ ijọba Katsina.

Awọn ajọ ajafẹtọọ ọmọniyan bii Amnesty International ti da si ọrọ yii, wọn si n beere fun iwadii to rinlẹ lati mọ boya Emir Daura lẹbọ lẹru loootọ tabi bẹẹ kọ.

Ta a ni obinrin Bequinqa yii?

Oyinbo arinrinajo naa, Mirka ti orukọ rẹ n jẹ Bequinqa loju opo Instagram.

Ohun ti oyinbo obinrin arinriajo yii fi si oju opo Instagram rẹ fi han pe ọmọ orilẹede Poland ni, o si ni ipinnu lati rin irinajo de orilẹede 197 lagbaaye.

O ṣapejuwe ara rẹ bii ẹni to fẹran lati maa ran awujọ lọwọ, oun si fẹran lati maa rin irinajo kaakiri agbaye.

Ninu awon fọto to fi soju opo rẹ, o fi han pe o ti rin irinajo lati Europe de Ariwa ati Guusu America, Australia, Africa atawọn orilẹeede mi-in lagbaaye.

Awọn fọto naa tun fi han pe o ti de aafin awọn ọba kan ninu irinajo rẹ yii.

Bequinqa tun ṣafihan awọn fọto ibi to ti lọ si awọn ayẹyẹ ibilẹ ni Kano, ati ibi to ti ba Emir Bauchi ya fọto, ko too de Daura to pada di iroyin yii.

Awọn ilu mi-in to ni oun tun ti de ni Naijiria ni Oron, Calabar, Ibadan, Uyo, Benin City, Eko, Abeokuta, Ibadan, Osogbo, Ilorin, Abuja, Jos, Bauchi, Dutse, ati Kano.

Ṣaa, ijọba ipinlẹ Katsina ti ni oun yoo tu iṣu iṣẹlẹ yii de isalẹ ikoko, lati fidi otitọ ohun to ṣẹlẹ mulẹ gan-an.