Ọta ìbọn ba ọ̀dọ́bìnrin yìí lójú lọ́mọ ọdún 15: Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ti ṣòfò báwọn ọmogun ajìjàgbara ṣe ń kọjú ìjà síjọba

Oríṣun àwòrán, Michael Mvondo/BBC
- Author, Paul Njie
- Role, BBC Africa
- Reporting from, Ogoja
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ọmọ ọdún meedogun ni Median Bah wa nigba ti iṣẹlẹ manigbagbe ṣẹlẹ sí í.
O máa n ranti ọjọ keje oṣù Kẹrin ọdún 2018 bi ọjọ manigbagbe, ori ibusun lo wa lọjọ naa torí àìlera.
Ṣadeedee lawọn agbébọn yabo ile wọn ni ẹkun iwọ oorun guusu orilẹ ede Cameroon.
Median, ẹni ọdun mẹtalelogun bayii ṣàlàyé pé ẹgbọn òun ọkunrin lo ji oun pe awon jàndùkú ajijagbara tí dé.
Báyìí lo ni awon janduku naa bẹrẹ sí ní yinbon lakọ lakọ.
Oju ferese ni egbon Median gba salọ amọ ko rọrùn foun lati gbà oju ferese jade.
Idi niyi to fi gba ibi ilekun jade.
Báyìí ni meji lara awon janduku naa da ibọn bo o.
"Báyìí nì mo bẹrẹ sí bẹ wọn, itan ni won ti kọkọ yinbon fun mi.
Lẹyìn náà ni won yinbon lera lera si mi eyi to ba oju mi jẹ."
Median padà ṣubu lulẹ tí o si da bi ẹni pe o n lala ni.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan, Median ti ṣe iṣẹ abẹ merin ni Cameeroon, Ghana ati India lori ojú rẹ laarin odun mẹjọ seyin.
Median kò lanfaani lati mi pẹlu emi ati imu mọ.
Ọrun ni wọn gbé paipu sí fun un to fi ni mi.
Iya Median sa kuro nile, ọrọ ile ẹkọ rẹ daru.
Ìjà tó n lọ lọwọ fún bi ọdún mẹwàá bayii ti ba ayé ọpọ èèyàn jẹ.
Ni oṣu kẹwàá ọdún 2016 làwọn agbejoro atawon olukọ lekun ti wọn ti n sọ ede Gèésì da iṣẹ sílẹ lórí wi pé ìjọba n fi ẹtọ awọn dun awọn.
Bayii ni oniruuru iwode bẹrẹ ni ẹkun náà.
Nigba to ya lawọn ẹgbẹ ajijagbara jade ti won n pe fun iyapa orilẹ ede Abazonia lara Cameroon.
Lati igba naa ni awọn ọm'ogun ajijagbara tí n kojú ija si ọm'ogun ìjọba Cameroon.
Àjọ Human Rights Watch sọ pe ko dín ni eeyan 6000 to ti ku ni ẹkun naa lati igba ti ija naa ti bẹ sílẹ.
Ẹka UNHCR to n ri sọrọ awọn ogunlende ni àjọ UNO sọ pe awọn eeyan Cameroon to le ni 70,000 lọ ni ṣatipo ni orile-ede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Michael Mvondo/BBC
End of podcast promotion
Arabinrin Glory Akom to ni ipenija ara n gbe ni àgọ ogunlende to wa ni Ogoja ni Naijiria.
Ko din ni eeyan 15000 to wa ni agọ ogunlende ni Ogoja nipinle Cross River.
Àwọn èèyàn yìí kò mọ boya wọn maa lanfaani lọjọ kàn láti pada sile wọn ni Cameroon.
Glory ni igbe aye oun san ni Cameroon tori oun n ṣiṣẹ tóun fi n tọju ẹbi oun.
O ni awọn ọm'ogun ìjọba lo le awọn eeyan lọ sinu igbo nigba ti rogbodiyan naa lagbara si lọdun 2017.
Glory ni ninu igbo lawọn ti n sun torí wọn le yinbon pa ẹnikẹni to ba wa nile rẹ.
$67 ni àjọ UNHCR maa n fun enikookan ogunlende losu, owo yìí ni Glory n gba to fi n tọju awọn ọmọ rẹ eyi ti ọkan lara wọn nilo lati maa lọ sile iwosan tori o ni arun arunmoleegun.
Maurine Manga ni oun atawon ẹbi oun marun un sa kuro ni Akwaya lẹkun iwọ oorun guusu Cameroon nigba tawon ọmogun ajijagbara da ibọn bolẹ lásìkò tí wọn n dawọọ ominira wọn lọjọ kínní oṣù kẹwàá ọdún 2017.
O ni awọn ni lati sa kuro torí wọn yinbon fun ọpọ eeyan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Maurine ọmọ ọdun mọkanlelogun ti da ilé ẹkọ duro latari rogbodiyan to n ṣẹlẹ lẹkun naa.
Awọn ọmọde to le ni 200,000 ni ko sí nile ẹkọ mọ lẹkun naa bayii.
Bakan naa, Ile ẹkọ tó le ni 2,500 ni ko ṣiṣẹ mọ.
Amọ, Maurine ri eto ẹkọ ọfẹ gba eyi to fun un lanfaani lati maa kẹkọọ ni ile ẹkọ gbogbonṣe kan.
O ni inu oun maa n bajẹ toun ba ti ranti awọn ọrẹ oun ti wọn ko lanfaani sí eto ẹkọ mọ ni Cameroon.

Oríṣun àwòrán, Michael Mvondo/BBC
Lẹyìn ijajagbara bi ọdún mẹwàá, ìjọba Cameroon fẹ kí ẹgbẹ ọm'ogun ajijagbara fòpin si ija ti won n já.
Losu kẹsán an to koja ni ìjọba ṣe ijiroro ni ese kuuku lẹkun naa eyi to le mu alaafia jọba.
Olootu ijoba Joseph Dion Ngute sọ fawọn èèyàn ẹkun naa wi pe asiko ti to fun won lati sọ fawọn ajijagbara pe ki wọn maa lọ.
O kere tan awọn ọm'ogun ajijagbara bíi ogota ni wọn ti tuuba pe awọn o ja mọ.
Ọpọ nínú lo ti ku nígbà táwọn mii lawọn o beere fun òmìnira ẹkun awọn mọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọgbeni Clovis lo ọdún meji pẹlu ẹgbẹ ajijagbara White Tigers of Ribbons lẹkun iwọ oorun guusu Cameroon ko to fi wọn sílẹ lọdun 2019.
Oun lo wa n sọrọ tako ẹgbẹ ajijagbara bayii.
Bo tilẹ jẹ pé ìjọba n kepe awọn ajijagbara naa pe kí wọn jogun o mi, wọn si tẹsiwaju ikọlu ti wọn n ṣe lẹkun iwọ oorun guusu Cameroon.
Oníṣe ìwádìí kan Roland Fru sọ pe ijọba ko tii ṣiṣẹ lori nnkan táwon ajijagbara n béèrè fún.
BBC kàn sí oríṣìíríṣìí ẹka ijoba Cameroon, amọ ko s'ẹni to sọrọ lorukọ ijoba.
Fun Median, Glory àti Maurine, ìrètí wọn ni pé ija to n lọ yoo dopin lọjọ kan tawon yoo si lanfaani lati padà sí ibugbe awon ni Cameroon.
Median ni ko si nnkan to le ba oun leru mọ tori oun ti de bebe iku sugbon ti oun ko ju.



























