Èèyàn mẹ́fà kú, ọ̀pọ̀ farapa níbi ìpolongo ìbò Omo-Agege

Omo Agege ati moto ti won baje ati eni to farapa
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Delta ti kede isede kaakiri ijọba ibilẹ Ughelli, lẹyin ti rogbodiyan oṣelu mu ẹmi eeyan mẹfa lọ lọjọ Aje.

Aago mẹfa irọlẹ si mẹfa idaji ni isede naa yoo fi maa waye.

Nibi ipolongo ibo fun Sẹnetọ Ovie Omo-Agege n'ilu Uduere, ni ija oṣelu ti bẹ silẹ. Omo-Agege ni Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo aarin gbungbun ipinlẹ Delta.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe iwadii ti awọn kọkọ ṣe, fihan pe eeyan mẹfa lo ku, ti ọpọlọpọ si farapa.

Omo-Agege n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress (NDC) for di fun idibo ọdun 2027.

Kini Omo Agege sọ?

Ninu ọrọ to ba ileeṣẹ iroyin Channels sọ, Omo-Agege sọ pe ọpẹlọpẹ awọn oṣiṣẹ alaabo DSS to wa pẹlu oun, ni ori fi ko oun yọ ninu ikọlu naa.

"Orukọ mi la gbọ ti awọn janduku naa n pariwo bi wọn ṣe de, ti wọn si n sọ pe, Omo-Agege la fẹ ẹ pa. A gbọdọ pa Omo-Agege."

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii nipa iṣẹlẹ naa, ati lori bi ọwọ yoo ṣe tẹ àwọn to wa nidii rẹ.

Bo ti lẹ jẹ pe àwọn ọlọpaa ko ti i sọ nkankan nipa awọn to wa nidi ikọlu naa, ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress (NDC), fi ẹsun kan pe, ẹgbẹ alatako, APC, lo wa nidi ikọlu ọhun.

Akọwe ikede fun ẹgbẹ oṣelu NDC, Osa Director, sọ ninu atẹjade to fi sita lori iṣẹlẹ naa sọ pe, "ọna lati pa ẹgbẹ oṣelu alatako lẹnu mọ, ati lati dẹru ba awọn ọmọ ẹgbẹ naa ki wọn le jawọ ninu eto idibo, ni."