Kókó méje nípa ìgbé ayé Pete Edochie, àgbà òṣèré tíátà tó dágbére fáyé

Oríṣun àwòrán, peteedochie/Instagram
Agba ọjẹ oṣere tiata, to tun jẹ ilumọka, Pete Edochie ti jade laye ni ọdun mọkandinlọgọrin, 79.
Iroyin yii lo tẹ wa lẹti ninu atẹjade kan ti ọmọ rẹ, Leo Edochie, fi sita ni owurọ Ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2026 pe oloogbe naa jade laye nipinlẹ Enugu.
Bakan naa ni atẹjade naa tun fidi rẹ mulẹ pe aisan jẹjẹrẹ ti n ba oloogbe naa finra ko to di pe o jẹ ipe Olọrun.
Awọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìgbé ayé Pete Edochie, àgbà òṣèré tíátà tó jáde láyé
Yoruba ni awaye ku ko si, tori bo pẹ titi, gbogbo ẹda ni yoo tọ iku wo.
Wọn bi Pete Edochie ni ọjọ keje oṣu kẹta ọdun 1947 nipinlẹ Enugu
Baba rẹ jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ Reluwe Naijiria, to si jẹ iṣẹ baba rẹ lo gbe lọ si ipinlẹ Kaduna, ibi to ti dagba.
Pete Edochie lọ si ile ẹkọ Saint Patrick's and Saint James Primary Schools ni Zaria, ko to tun morile Saint John Secondary School, Kaduna, ni 1960.
Lẹyin ọdun mẹrin, o dara mọ baba rẹ nidi iṣẹ Reluwa ṣugbọn mọlẹbi naa kuro nipinlẹ Kaduna saaju ki ogun abẹle to bẹrẹ
Ni ẹni ogun ọdun, Pete Edochie bẹrẹ iṣẹ ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ Eastern Nigerian Broadcasting Corporation.
Ni ọdun 1980, Pete Edochie lọ si ile ẹkọ British Broadcasting Corporation fun imọ si, to si pada di ọga agba akọkọ fun ileeṣẹ ijọba Anambra Broadcasting Service 3FM Stereo ni ọdun 1987.

Oríṣun àwòrán, Pete Edochie/Instagram
Irinajo Pete Edochie sagbo osere tiata
Lẹyin eyi ni Pete darapọ mawọn osere tiata, to si kopa ninu ọpọ sinima.
Amọ ere to mu ko di ilumọọka ni ere Things Fall Apart nibi to ti kopa bii Okonkwo.
Ileesẹ mohunmaworan ilẹ wa, Nigerian Television Authority, NTA si lo se ẹda iwe naa bii ere tiata loju iworan rẹ.
Ipa ti Pete Edochie ko gẹgẹ bii jagunjagun fun ẹya Igbo ninu ere tiata naa lo mu ko di gbajumọ ati ọkan lara awọn osere tiata to n lewaju nilẹ Naijiria.
Ere yii lo jẹ ohun ti gbogbo agbaye tẹwọgba, koda, ileesẹ agbohunsafẹfẹ BBC gan fi ọrọ wa lẹnu wo nipa ipa to ko ninu ere naa.
Lara awọn ere sinima ti Pete ti kopa ni Igodo, Rituals, Billionaire's Club ati Lionheart, ninu eyi to ti kopa bii Oloye Ernest Obiagu.
Pete Edochie fẹ́ agbẹjọ̀ro ni aya, ọmọ rẹ meji ninu mẹfa jẹ osere tiata
Bakan naa ni Edochie ti gba ọpọ ami ẹyẹ nidi isẹ tiata, ti aarẹ ana, Oloye Olusegun Obasanjo si da lọla pẹlu oye Member of the Order of the Niger (MON).
Oloogbe naa tun gba ami ẹyẹ Africa Magic fawọn osere tiata, ti Afica Film Academy naa si tun fun ni ami ẹyẹ osere tiata to pegede.
Amofin Josephine Edochie ni aya Pete, ti Ọlọrun si fi ọmọ mẹfa ta wọn lọrẹ.
Lara wọn ni Yul ati Linc Edochie ti awọn mejeeji naa jẹ gbajumọ osere tiata bii baba to bi wọn.
Ọpọ igba ni awuyewuye ti waye nipa ẹbi Pete Edochie, ti ọpọ eeyan ko si le gbagbe awọn ohun to suyọ nipa igbeyawo Yul, ẹni to fẹ Judy bii iyawo keji.

























