''Olorì lè kúrò ní àáfin àmọ́ ààfin kìí fi Olorì sílẹ̀,'' Olorì Silekunola sọ̀rọ̀ lórí i bó ṣe pàdé kábíyèsí àti bó ṣe kúrò láàfin Ooni

Oríṣun àwòrán, Queen Naomi Silekunola/Instagram
Olori Naomi Silekunola ti ṣalaye fun BBC News Yoruba wi pe ibaṣepọ to dan mọran lo wa laarin rẹ ati Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwunsi, Ojaja Kẹta,bo tilẹ jẹ pe o ti kuro laafin.
Olori Naomi sọ pe ''baba ni Ooni jẹ fun mi ati ọmọ mi Tadenikawo.
Eeyan maa n gbade Olori wa lati ọrun ni, irinajo bi mo ṣe pade Ooni ko ṣe e ṣalaye tori iṣẹ Oluwa ni mo n ṣe.
Olori le kuro laafin amọ aafin kii fi olori silẹ, bi eeyan ba jẹ olori, ko le yi pada.
Ẹmi ni olori, akaimoye ẹni ti ko fẹ ọba ri, ti a si n pe wọn ni iya.''
Olori Naomi fikun ọrọ rẹ wi pe ko si nnkan to yi pada ninu igbe aye oun lẹyin toun kuro ni aafin.
Wolii Naomi tun sọ nipa iṣẹ iranṣẹ ti o gba wi pe ajihinrere ati wolii loun, oun si jẹ eeyan ti ko moju ọkunrin.
O ni ''Ọba naa kii ṣe ẹni ti eeyan maa n he laarin titi, ọba tun wa jọba lọ.
Aditu ni ọrọ bi mo ṣe pade Ooni - Olori Naomi
Olori Naomi tun sọrọ nipa bi oun ati kabiyesi Onirisa ṣe pade.
Arabinrin Silekunola sọ pe ''aditu ni ọrọ bi mo ṣe pade Ooni, eeyan kii tu u, Oluwa lo dari Ooni si mi.
Ọlọrun naa lo si jẹ ki o ṣee ṣe, mo sọ pe iṣẹ iranṣẹ ni mo n ṣe ti mo fi pade kabiyesi.
Amọ, awọn eeyan ti ṣi mi gbọ, ọpọ lo n ro pe mo lọ ba Ooni wi pe Oluwa ran mi si yin.
Ṣugbọn eeyan kii paṣẹ fun alaṣẹ tori alaṣẹ ni Ooni jẹ.''
Ayanmọ ni bi mo ṣe kuro laafin – Olori Naomi
End of podcast promotion
Lori ọrọ ohun to ṣẹlẹ to fi kuro ni aafin, Olori Naomi ni ko si nnkan to ṣẹlẹ.
O ni ayanmọ ni ati pe bi Ọlọrun ba ṣe kọ pe eeyan maa rinrin ajo ni onitọun ṣe maa rin in.
O ni lati kekere lẹnu ti maa n kun oun tawọn eeyan maa n sọ nipa oun.
Olori Naomi ni ko si nnkan toun ba ṣe tawọn eeyan ko ni sọ nipa rẹ.
Ajihinrere Silekunola tun sọ idi to fi pada sile ẹkọ wi pe oun ni iṣẹ toun wa jẹ ninu aye.
Olori Naomi ni iwe kikọ wa lara ọna toun yoo gba jiṣẹ ti ori ran oun ninu aye.
Wolii Silekunola tun sọ pe ''ko si ẹni ti ko le pada lọ sile ẹkọ nigba kugba lai fi ti ọjọ ori ṣe.''
Olori tun sọ pe obinrin ti Ọlọrun ba pe ti di ọkunrin tori pe o ni lati jẹ akọni.
O ni iṣẹ iranṣẹ jẹ iṣẹ ẹmi eyi to nilo imulọkanle.
Nigba to n sọrọ lori bi eeyan ṣe maa mọ boya Ọlọrun pe e, Olori Naomi ni ko si nnkan ti eeyan le jẹ ti ko ni mọ.
''Ogbenu ọmọ eniyan fọhun ni Ọlọrun, ti o ba n gbe inu rẹ, waa mọ.
Oriṣiiriṣii eeyan lo wa lori ilẹ aye, awọn ẹda kan wa ninu omi, bẹẹ lawọn kan tun wa labẹ ilẹ.
Ko si ohun ti o maa jẹ ti o ko ni i mọ, emi mọ wi pe wolii ni mi.
Lati kekere bi ọmọ ọdun mẹfa ni mo ti mọ wi pe wolii ni mi, gbogbo nnkan ti mo ba sọ nigba yẹn lo maa n ṣẹ,'' Olori Naomi lo sọ bẹẹ.
Olori Ooni tẹlẹ tun sọ pe oun ko ni ọjọ kan to ba oun ninu jẹ ju laye, ṣugbọn o ni ọjọ ti oun bi Ọmọba Tadenikawo ni ọjọ ti inu oun dun julọ laye.

























