Àgbà òṣère;Kola Oyewo wọ káà ilẹ̀ sùn l'Osun
Wọn ti sin oku gbajumọ agba oṣere nni, Oloogbe Gabriel Adekola Benedict Oyewo.
Ọjọ Ẹti, ọjọ keje oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni wọn sin oku naa siluu rẹ niluu Oba Ile, ipinlẹ Osun.
Tẹ o ba gbagbe, Oloye Oyewo jade laye lọjọ kejila, oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii lẹni ọgọrin ọdun.
Ile ijọsin St. Joseph Catholic Church, niluu Oba Ile ni won ti bẹrẹ eto isinku naa, nibi ti awọn ọmọ oloogbe, ẹbi ati awọn alabaaṣe peju si, ki wọn too gbe e pada lọ sile ikẹyin ti wọn sin in si.

Oríṣun àwòrán, Nollywire/BBC
"Ẹni mimọ rẹ ki yoo dibajẹ"

Ninu ọrọ Biṣọbu John Akin Oyejola to ṣe iwaasu nibi eto isinku naa, o mu ẹnu ba Orin Dafidi, ori kẹrindinlogun ẹsẹ kẹwaa.
Ọrọ iwaasu naa ko ṣai ka pe:
"Nitori iwọ ki yoo fi ọkan mi silẹ ni ipò-okú; bẹẹ ni iwọ ki yoo jé ki ẹni mimọ rẹ ki o ri idibajẹ.
Eyi ni koko ọrọ iyanju ti Bisọọbu Oyejola sọ fawọn ọmọ oku lakooko to n gba wọn nimọran.
Oniwaasu naa tẹsiwaju pe Oloogbe Kola Oyewo jẹ olufọkan sin ninu ijọ Ọlọrun,ati nibi gbogbo to ba de.
O rọ awọn ọmọ ati ẹbi patapata lati mu ninu iwa rere ti Oloogbe Kola Oyewo wu nigba aye rẹ.
Awọn oṣere tiata ko wa sibi isinku naa

Ohun kan ti BBC News Yoruba ri òye rẹ nibi eto isinku naa ni pe awọn oṣere tiata ti wọn jẹ akẹgbẹ Oloogbe Kola Oyewo ko si nibẹ.
Oṣere kan ṣoṣo ti a ri nibi ayẹyẹ naa ni Abilekọ Toyin Adegbola (Ajoke Asewo to re Meka.)
Nigba to n sọrọ nipa Oloogbe Kola Oyewo, Ajoke sọ pe oun ti mọ Oloogbe naa bayii o ti pe ogoji ọdun, ati pe baba naa ṣe pupọ ninu aye oun.
"Nipasẹ Kola Oyewo ni mo fi di gbajumọ oṣere loni, imọran ati itọsọna wọn ran mi lọwọ pupọ ninu irin ajo aye mi."
O fi kun un pe Oloogbe Kola Oyewo jẹ Baba rere ati ololufẹ gbogbo eeyan patapata, ti ko si yọ ẹnikẹni silẹ rara.
Baba mi jẹ ọrẹ mi, abiyamọ rere ni-Adetoyese Oyewo

Ọkan lara awọn ọmọ Oloogbe Kola Oyewo, Adetoyese Oyewo, ninu ọrọ rẹ ṣapejuwe iru ẹni ti baba rẹ jẹ nigba aye rẹ.
Adetoyese ni:
"Baba mi jẹ ọrẹ mi, ololufẹ ati adari rere fun mi ati fun gbogbo awa ọmọ rẹ patapata.
"Baba mi ki i ṣe bi baba si awa ọmọ rẹ, o rẹ ara rẹ nilẹ o si ṣe wa bii ọrẹ rẹ ni.
"Baba mi ko le jẹun ko ma ṣẹku fawa ọmọ rẹ, wọn si ni aṣa kan, fifi oju ba ọmọ sọrọ ni, ko le ye alejo, awa ọmọ rẹ nikan lo ye."
Adetoyese Oyewo tẹsiwaju pe Baba oun jẹ ẹni to ko ẹbi ati gbogbo ilu Oba-ile mọra, adari rere si ni pẹlu.
O ni iku baba naa dun oun pupọ, amọ ko si ohun toun le ṣe si i.
Ta a ni Oloogbe Kola Oyewo?

Oríṣun àwòrán, Kunle Aford/Instagram
Agba oṣere tiata Yoruba to tun jẹ olukọ fasiti ni Oloogbe Kola Oyewo.
Ọjọ́ kẹtadinlọgbọn, oṣù kẹta ọdún 1946 ni olóògbé Kola Oyewo dele aye.
Ìlú Oba Ile, nipinlẹ Osun ni wọn bi i si, to si bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ère tíátà pẹlu ẹgbẹ́ òṣèré Oyin Adejobi.
Kola Oyewo ṣe ere tíátà fún bíi ọgọ́ta ọdún, lára ere to tí kopa ni Sango, Koseegbe àti Super Story.
Bákan náà, olùkọ́ àgbà ní olóògbé Oyewo, to si gbà oye Ọmọwe nìdí ere sise ni Fásitì Ibadan.
Fásítì Obafemi Awolowo ni olóògbé náà tí ṣiṣẹ olùkọ́ni, ó si tún ṣiṣẹ ni Fásítì Redeemer áti Elizade.
Gẹgẹ bi awọn ọmọ rẹ ṣe ṣalaye, ọdun meje sẹyin ni aarẹ ti mu Oloogbe, ko too jade laye lọjọ kejila, oṣu Kẹfa ọdun 2026 lẹni ọgọrin ọdun( 80 years).



























