Bí àṣekágbá ọdún Osun Osogbo ṣe ń lọ lọ́wọ́, ọlọ́pàá ṣèkìlọ̀ nlá fàwọn ọ̀daràn l'Osun

Awọn eeyan to wọ asọ funfun wa ni ojubọ Osun Osogbo, wọn n bu omi inu odo
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lojuna lati gba alaafia ati iṣọkan, to fi mọ aabo ẹmi ati dukia araalu laaye, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn to ba fẹẹ huwa ọdaran lati rin jinna sibi ayẹyẹ ọdun Osun-Osogbo to n lọwọ.

Atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Abiodun Ojelabi fi sita lo fidi rẹ mulẹ pe ọlọpaa ko nii fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ eto aabo lasiko ayẹyẹ naa.

Ọlọpaa sọ pe awọn to fẹẹ foju kan awọn ọdaran bii tọọgi, ole, ọmọ ẹgbẹ okunkun ati oniruuru iwa ọdaran miran nibi ayẹyẹ ọhun.

Awọn eleto aabo bii olopaa ree lasiko ayeye odun Osun-Osogbo to ti waye koja lo

"Ọmọ ẹgbẹ okunkun, tọọgi, ole, ati awọn oniwa ọdaran miran, ẹ mase lo anfaani ayẹyẹ ọdun Osun Osogbo lati huwa ọdaran"

Wọn ni ẹnikẹni tọwọ awọn ba tẹ, nibi to ti n gbiyanju lati dabaru alaafia ati iṣọkan nibi ayẹyẹ ọhun yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ ni ibamu pẹlu iwe ofin.

Ojelabi sọ pe ọga awọn, Ibrahim Gotan ti ṣẹlẹri pe oun ko nii faaye gba ẹnikẹni lati ko ibẹru sọkan araalu, paapaa awọn alejo ti wọn ba wa lati kopa nibi ayẹyẹ naa.

"Ọmọ ẹgbẹ okunkun, tọọgi, ole, ati awọn oniwa ọdaran miran la n ṣe ikilọ fun bayii lati ma ṣe pinnu pe awọn fẹẹ lo anfaani ayẹyẹ ọdun naa lati huwa ọdaran," atẹjade naa sọ bẹẹ.

"Ẹnikẹni tọwọ ba tẹ wi pe o n gbiyanju lati da omi alaafia ru lasiko ayẹyẹ naa yoo foju winna ofin," o fidi rẹ mulẹ.

Gotan wa fi ọkan awọn araalum alejo, arinrin-ajo-afẹ ati awọn ẹlẹsin ibilẹ balẹ wi pe awọn yoo pese aabo to pe ye fun gbogbo wọn, ṣaa, lasiko ati lẹyin ayẹyẹ ọdun Osun-Osogbo ti 2026.

Ọga ọlọpaa naa sọ pe ojuṣe awọn ni lati rii pe alaafia jọba, ti ohun gbogbo si lọ bo ti tọ ati bo ti yẹ, lati rii pe ko si wahala kankan.

"Ayẹyẹ to ti jẹ itẹwọ lagbaye naa, Osun-Osogbo lawọn eeyan kaakiri Naijiria ati orileede miran lagbaye maa n wa lati kopa nibẹ, leyi to maa n pọndandan fun agbekalẹ eto aabo ẹmi ati dukia."

O sọ siwaju pe gbogbo awọn ọga ọlọpaa lawọn ẹkun patapata, to fi mọ awọn tọrọ kan ni wọn ti ran lọ sibẹ lati rii pe eto aabo daju.