Iléeṣẹ́ ológun Naijiria kéde àwọn agbéṣùmọ̀mí méjì tó juwọ́ sílẹ̀ fún ìjọba

Abu Umar ati Ismail Mohammed n wo ọọkan

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN ARMY/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ Ologun Naijiria ni awọn ogbontarigi ni ikọ agbeṣumọmi Islamic State West Africa Province, ISWAP, ti jọwọ silẹ fun ileeṣẹ Ologun ti wọn si ni awọn ko ni kopa ninu igbeṣumọmi mọ.

Ileeṣẹ Ologun to fi iroyin naa lede lori ayelujara kede orukọ awọn agbeṣumọmi ti wọn juwọ lẹ naa bii Ismail Mohammed ati Abu Umar.

Atẹjade naa ni awọn eeyan naa wa pẹlu ileeṣẹ Ologun, ti wọn si n gba idanilẹkọọ lati ko gbogbo awọn nnkan to wa lori wọn tẹlẹ kuro.

Ileeṣẹ Ologun ninu atẹjade naa ni pe awọn tun ti ṣe aṣeyọri nidii igbogunti iwa igbeṣumọmi pẹlu awọn eeyan ti wọn ju ida wọn silẹ naa.

Agbẹnusọ ikọ HADIN KAI ni ẹka ileeṣẹ Ologun, Haruna Sani lo fi iroyin lede.

Eyi lo n waye lasiko ti iwa ijinigbe ati ipenija aabo n peleke si ni orilẹ ede Naijiria.

Bakan naa lo n waye lẹyin ti ijọba Naijiria pẹlu atilẹyin orilẹ ede Amẹrika ṣekupa ọkan lara awọn ọga agba ikọ agbeṣumọmi IS, Abu-Bilal al-Minuki.

Ta ni awọn eeyan naa?

Gẹgẹ bi atẹjade ti ileeṣẹ Ologun Naijiria fi lede, awọn eeyan mejeeji naa lo di ipo to ṣe pataki mu laaarin awọn agbeṣumọmi egbe wọn, ti wọn si maa n ṣọṣẹ ni agbegbe Mangari ni ẹkun lake Chad.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkan lara awọn eeyan naa, Ismail Mohammed lo sunmọ ọga awọn Iswap, Baa Shuwa, to si ni ọpọ imọ nipa bi ikọ agbeṣumọmi naa ṣe n ṣiṣẹ daadaa.

Ẹnikeji, Abu Umar ni oun gbajumọ laaarin awọn akẹgbẹ wọn imọ rẹ lori ṣiṣe awọn ado oloro.

Iṣẹ tirẹ ni lati maa pese awọn ọkọ ti wọn ado oloro pẹlu awọn ohun ija oloro mii tawọn agbeṣumọmi naa maa n lo lati fi ṣọṣẹ.

Ileeṣẹ Ologun ko sọ ohunkohun nipa ọjọ ori wọn, ibi ti wọn ti wa tabi ohun to ṣẹlẹ lẹyin ti wọn ti jọwọ silẹ fun ijọba bayii.

Bakan naa ni ileeṣẹ Ologun tun fidi rẹ mulẹ pe agbeṣumọmi kan, Mohammed Khalifa, to jẹ ọmọ ẹgbẹ ikọ agbeṣumọmi Iswap Shurah ti padanu ẹmi rẹ nigba ti ikọ Ologun HADIN KAI ṣe ikọlu si ibuba wọn.

Ileeṣe Ologun woye pe bi Ismail ati Abu ṣe juwọ silẹ fun ijọba yii jẹ ifasẹyin fawọn agbeṣumọmi akẹgbẹ wọn paapaa nitori imọ ati ipa wọn ninu ikọ naa ki wọn to kuro.

Wọn fi kun pe igbagbọ wa pe ọwọ lile ti ikọ HADIN KAI n gbe lẹnu ọjọ mẹta yii lodi si awọn agbeṣumọmi naa n so eso rere lo jẹ ki awọn eeyan naa jọwọ silẹ fun ijọba.

Ẹ o ranti pe ni oṣu Karun-un ni Ijọba apapọ ti fidi rẹ mulẹ pe ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ ologun ilẹ Amẹrika ti ṣekupa Abu-Bilal al-Minuki, to jẹ olori ẹgbẹ agbesunmọmi ISIS.

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lo fidi eyii mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede laarọ ọjọ Abamẹta.

Ọrọ yii lo n jẹyọ lẹyin ti Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump ti kọkọ kede igbesẹ naa.

Nigba ti Aarẹ Trump n juwe Abu-Bilal al-Minuki, o ni oun ni igbakeji ẹgbẹ ISIS kaaliri agbaye.

Trump sọ pe Abu-Bilal al-Minuki ko ni le maa ṣeruba awọn eeyan Afrika mọ bayii lẹyin to ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.

Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ ijọba Naijiria fun ibaṣẹpọ rẹ lati rẹyin Abu-Bilal al-Minuki.