Ẹ wo àwọn olùdíje tó wọlé àtàwọn tó lulẹ̀ nínú ìbò abẹ́nú APC sípò Gómìnà láwọn ìpínlẹ̀

Sharadeen Alli wọn agbada funfun, Obafemi Hamzat wọ agbada buluu pẹlu fila, Adebayo Adelabu ati Sẹnẹtọ Solomon Adeola Yayi naa wọ agbada buluu

Oríṣun àwòrán, Sharadeen Alli/Obafemi Hamzat/Adebayo Adelabu/Solomon Adeola Yayi/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn oludije ti yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo gomina lọdun 2027 ti foju han bayii, lẹyin eto idibo abẹnu to waye kaakiri awọn ipinlẹ ni Naijiria lanaa Ọjọbọ ọjọ kọkanlelogun oṣu Karun un yii.

Ṣaaju eto idibo abẹnu naa lawọn oludije kan ti yẹba fawọn oludije mii, eyi ti ko jẹ kawọn oludije naa ni alatako ninu eto ibo naa.

Ọpọ awọn gomina to ti ṣe saa kan tẹlẹ lo gba tikẹẹti lati ṣe saa keji, nigba tawọn to ti ṣe saa keji ri pe awọn eeyan ti wọn fẹ lọ wole idibo abẹnu to waye.

Eyi ni esi awọn idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu APC sipo gomina to waye kaakiri awọn ipinlẹ l'Ọjọbọ:

Ipinlẹ Oyo

Sẹnẹtọ Sarafadeen Alli lo bori ninu eto idibo abẹnu sipo gomina nipinlẹ Oyo, lẹyin ti o ri ibo 578,143.

Sẹnẹtọ Abdulfatai Buhari ṣe ipo keji ninu ibo ọhun pẹlu ibo 37,265, nigba ti minisita ina mọnamọna tẹlẹ, Adebayo Adelabu, ṣe ipo kẹta pẹlu ibo 19,193.

Mẹjọ ninu awọn oludije mọkanla to dije ninu eto idibo abẹnu naa lo wa lati ilu Ibadan, meji wa lati Oke Ogun, nigba ẹnikan wa lati Ogbomoso.

Awọn oludije mii ni Ọmọwe Adewale Kareem, Amofin Akeem Agbaje, Amoju ẹrọ Akeem Alao, Ọmowe Ayobami Lam-Adesina, Ọmọba Asanke Asatola ati Ololade Usman.

Awọn miran ni Dokita Muyiwa Gbadegesin, ati igbakeji gomina tẹlẹ, Rauf Olaniyan.

Ipinlẹ Ogun

Sẹnẹtọ Solomon Olamilekan Adeola tawọn eeyan mọ si Yayi lo wọle ibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu APC sipo gomina nipinlẹ Ogun.

Adeola lo n ṣoju ẹkun Iwọ Oorun ipinlẹ Ogun nile aṣofin agba niluu Abuja bayii.

Ipinlẹ Rivers

Aṣoju-ṣofin Kingsley Ogundu Chinda lo wọle ibo abẹnu APC fun ipo gomina nipinlẹ Rivers.

Ni olu ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC to wa niluu Port Harcourt ni igbimọ to ṣagbatẹru eto ibo naa ti kede Chinda gẹgẹ bi ẹni to bori ninu eto idibo naa.

Ibo 268,497 ni Chinda ri ninu eto ibo abẹnu naa.

Gomina ipinlẹ Rivers, Siminalayi Fubara, wa lara awọn oludije fun ipo gomina tẹlẹ ko to kede pe oun o dije mọ ṣaaju eto idibo naa.

Fubara ṣalaye ninu atẹjade to fi lede ṣaaju eto idibo naa pe oun ṣetan lati ṣatileyin fun ẹnikẹni to ba jawe olubori ninu eto idibo abẹnu APC fun ipo gomina nipinlẹ Rivers.

Gomina Fubara ni ẹnikeji to yọwọ ninu eto ibo abẹnu fun ipo gomina nipinlẹ Rivers, lẹyin ti Tonye Cole naa ṣe bẹẹ.

Awọn mii to tun jawe olubori

• Ẹgbẹ oṣelu APC ni Kano kede Yusuf gẹgẹ bi oludije ti ẹgbẹ fa kalẹ.

• Gomina Uba Sani ri ibo 459,393 ninu ibo abẹnu nipinlẹ Kaduna lati ṣoju APC ninu eto idibo gomina to n bọ.

• Sheriff Oborevwori ri ibo 345,375 lati wọle ibo abẹnu ni ipinlẹ Delta.

• Babagana Zulum ati Igbakaji Aarẹ Kashim Shettima ṣatilẹyin fun Mustapha Gubio lati wọle ibo abẹnu sipo gomina ni ipinlẹ Borno.

• Mbah ni ẹgbẹ oṣelu APC fẹnuko pe yoo dije fun ipo gomina nipinlẹ Enugu.

• Awọn gomina ipinlẹ Sokoto, Niger ati Katsina naa gba tikẹẹti lati dije fun saa keji.