Saudi yóò ṣe ògbufọ̀ wáàsí ọjọ́ Arafa Hajj ọdún yìí sí Yorùbá, Hausa àti èdè mẹ́tàlélọ́gbọ̀n míì

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Bi awọn olujọsin ṣi ṣe n de si orilẹede Saudi Arabia fun iṣẹ Hajj tọdun 2026 yii, awọn alaṣẹ orilẹede naa ti sọ pe anfaani yoo wa lati ṣe ogbufọ waasi lọjọ tawọn olujọsin ba goke Arafa si ede Yoruba, Hausa ati ede mẹtalelọgbọn mii.
Adari ọrọ ẹsin ni mọṣalaaṣi Anabi ni Saudi, Sheikh Abdulrahman bin Abdulaziz Al-Sudais, ni o fidi ọrọ yii mulẹ.
Gẹgẹ bi Al-Sudais ṣe sọ, kii ṣe waasi ti Sheikh Ali bin Abdulrahman Al-Hudhaifi to jẹ Imaamu ni mọṣalaaṣi Anabi ni Madinah nikan ni wọn yoo ṣe ogbufọ rẹ, o ni waasi naa yoo tun wa lori oniruuru itakun ayelujara kaakiri.
O ni igbesẹ yii waye lati le jẹ ki ọpọ eeyan kaakiri agbaaye gbọ nipa ẹsin islam.
Al-Sudais ni igbesẹ yii jẹ ọkan lara ọna ti ijọba Saudi fi fẹ sin awọn musulumi ati ẹsin islam.
Sheikh naa ni ṣiṣe ogbufọ waasi ọjọ Arafa si oniruuru ede yoo jẹ kawọn ti wọn kii ṣe ọmọ ilẹ Larubawa jẹ anfaani waasi ọjọ tawọn olujọsin ba gun Arafa.
O ni awọn ede ti wọn yoo ṣe ogbufọ waasi ọjọ Arafa si ni ede Gẹẹsi, Faranse, Indonesia, Urdu, Turkey, Persia, Spanish, Chinese, Russian, Bengali, Hindi, Malay, Amharic, Hausa ati Swahili.
Lara awọn ede mi ni Somali; Pashto; Punjabi; Tamil; Filipino; Bosnian; German; Italian; Portuguese; Swedish; Uzbek; Tajik; Nepali; Sinhala; Malayalam; Oromo; Tigrinya; Yoruba, Ugandan ati Lithuanian.
Iṣẹ Hajj ti ọdun yii yoo bẹrẹ lọjọ Aje to n bọ nigba tawọn olujọsin yoo rinrin ajo lati Makkah lọ si Mina.
Lẹyin naa ni wọn yoo pejọ ni oke Arafa ti wọn maa n pe ni Jabbal Rahma (Oke aanu) lọjọ Iṣẹgun.
Ọjọ ti wọn yoo gun Arafa yii lọjọ lo ṣe pataki julọ ninu iṣẹ Hajj.
Ọjọ mẹta lawọn olujọsin yoo fi lẹ oko mọ Asitani ni Jamarat, eyi ti yoo pari lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Karun un yii.
Lẹyin eyi lawọn olujọsin yoo pada si Mecca nibi ti onikaluku yoo ti pada si ibi ti wọn ti wa.




























