Sunday Igboho ṣe àfihàn ẹ̀ṣọ́ ààbò "Ija Ekun" tó fẹ́ fi kojú àwọn agbébọn nílẹ̀ Yorùbá bí ìjọba bá fún-un láṣẹ

Sunday Igboho atawọn eeyan ti wọn bana Ija Ekun dani

Oríṣun àwòrán, @DejiAdesogan/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti ṣafihan awọn ọmọ ogun ẹṣọ aabo rẹ to pe ni Ija Ekun.

Igboho ni awọn ọmọ ogun ẹṣọ aabo Ija Ekun ni wọn to aadọta egbẹrun ti wọn si ti ṣetan lati koju awọn agbebọn, awọn ajinigbe ati gbogbo ikọlu tawọn Fulani agbeṣumọmi n ṣe sawọn eeyan nilẹ Yoruba ati ni ipinlẹ Kwara.

O ni awọn eeyan naa ti ṣetan lati da aabo bo gbogbo awọn afurasi ọdaran to n fi inu igbo ṣe ibugbe, to si jẹ pe ibuwọlu ijọba apapọ lo ku ti oun n reti ke awọn eeyan fi bẹrẹ iṣẹ.

Ṣaaju ni Igboho ti parọwa si ijọba apapọ lati tete buwọlu agbedide awọn ẹṣọ aabo naa lojuna ati le mu alekun bae to aabo ni ilẹ Yoruba ati agbegbe rẹ.

O ni gbogbo igbesẹ ati ilana to yẹ ni oun ti tẹle, ti oun kan n reti ibuwọlu ijọba apapọ lati jẹ ki iṣẹ bẹrẹ ni pẹrẹu.

O fi kun pe oun ko fẹ bẹrẹ pẹlu gbogbo igbesẹ ati igbaradi ti awọn ti la kalẹ lati koju awọn afurasi ọdaran to n da ilẹ Yoruba laamu lai ṣe pe awọn gba aṣẹ lati ọwọ ijọba apapọ, awọn ijọba ipinlẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ Ologun.

Bakan naa lo rọ awọn ọba alaye nilẹ Yoruba lati da si ọrọ naa, pe ki wọn ba awọn ijọba sọrọ lati fun awọn laṣẹ lati da Ija Ekun silẹ ni kiakia.

Mo ṣetán láti kojú àwon agbébọn tó wà nínú igbó nílẹ̀ Yorùbá, àṣẹ ìjọba àpapọ̀ ni mò ń dúró dè- Sunday Igboho

Sunday Adeyemo (Igboho oosa)

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Bi ògun ẹni ba da ni loju, a maa n fi gbari ni.

Ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Sunday Adeyemo, (Igboho ooṣa) ti ni oun ṣetan lati koju awon agbebọn to n kọlu ilẹ Yoruba lati awọn inu igbo kiri.

Ọjọ Iṣẹgun ni Igboho sọrọ yii, pẹlu alaye pe aṣẹ ijọba apapọ ati ibuwọlu awọn gomina nikan loun n duro de lati bẹrẹ iṣẹ naa, to ba ti ya, o ya ni.

"Aṣẹ ijọba nikan ni mo n duro de lati koju aisi aabo to n gbilẹ si I nilẹẹ Yoruba yii patapata."

Ninu atẹjade ibanikẹdun si ẹbi awọn eeyan ti ajinigbe gbe lọ nile ẹkọ, ni Ahoro Esinele, niluu Ogbomoso, ipinlẹ Oyo lọjọ Ẹti to kọja ni Igboho ti darukọ ikọ ọmọ ogun to pe ni Iru Ẹkun.

Awọn wo ni ikọ ologun Iru Ẹkun ti Igboho n sọ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Sunday Igboho sọ pe oun ti pari iṣẹ lori ikọ ọmọ ogun ti I ṣe Iru Ẹkun.

O ni iṣẹ ikọ naa ni lati gba awọn igbo to wa ni Guusu-Iwọ-Oorun ilẹ yii lọwọ awọn agbebọn, awọn ọdaran darandaran ati ajinigbe ti wọn ti gba gbogbo igbo to wa ni ilẹ yii.

Gẹgẹ bi Sunday Igboho ṣe wi:

"Mi o fẹ bẹrẹ eto ti a la kalẹ lati le awọn ọdaran yii jade lai gba aṣẹ ijọba apapọ, tawọn gomina Guusu Iwọ-Oorun, tawọn ọlọpaa, DSS, ologun atawọn alẹnulọrọ yoku.

"Ohun to ṣẹlẹ ni Ahoro-Esinele atawọn eyi to ti ṣẹlẹ ṣaaju bani lọkan jẹ, o si ko idaamu bani pẹlu ohun ti awon alaiṣẹ ti wọn ji gbe n koju, paapaa julọ, awon akẹkọọ ti ko da nnkan kan mọ.

"O ṣe pataki nibi ti a de yii, lati tete gbe igbesẹ akin ti yoo da aaafia pada sawọn agbegbe igberiko wa.

"Awon ni won n koju ipaniyan ati ikọlu yii ju ni Guusu-Iwọ-Oorun ilẹ yii, ati lawọn apa ibi kan nipinlẹ Kwara.

"A ti ṣetan ogun lati wọ awọn igbo yii, ka si le awọn oniṣẹ ibi to n fi okunkun ṣiṣẹ jade, ka le awọn to n fi aye ni awon eeyan wa lara jade.

"A ko le maa ba a lọ bayii ka si kawọ gbera, ka maa wo, kawọn agbebọn, darandaran ati ajinigbe maa pa awọn eeyan wa nipakupa."

Bakan naa ni Igboho ke si awọn ọba alaye lati tete da si ọrọ yii, nipa sisọ fun ijọba lati tete gba ikọ Iru Ẹkun wọle, ki opin le tete de ba ai si aabo to n daamu ilẹ Yoruba.

Tẹ o ba gbagbe, eyi kọ ni igba akọkọ ti Sunday Igboho yoo beere fun aṣẹ ijọba lati koju ai si aabo to n daamu ilẹ yii, ṣugbọn ibeere naa ko jẹ itẹwọgba.