Ṣé lóòótọ́ ni pé àwọn ajínigbé tó ṣọṣẹ́ l'Ogbomoso ti ń bá ìjọba Oyo sọ̀rọ̀? Ohun tí a mọ̀ rèé

Ajinigbe agbebọn lapa osi, Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo lapa ọtun

Oríṣun àwòrán, AFP

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oni ọjọ Satide, ọjọ kẹtalelogun oṣu Karun-un ọdun 2026 yii lo pe ọjọ mẹsan-an ti awọn olukọ atawọn ọmọde akẹkọọ ti awon ajinigbe gbe lọ nile ẹkọ mẹta niluu Ogbomoso ti wa ni igbekun awọn agbebọn naa.

Ireti ọpọ ọmọ Naijiria ni pe awon ajinigbe naa yoo tete ba ijọba sọrọ, ki awon to wa nigbekun le gba ominira.

Ṣugbọn titi di asiko ti a n kọ iroyin yii, ko ti I si òye kankan to foju han pe ajọsọ ti n waye laarin awon ajinigbe naa pẹlu ijọba.

Iroyin kan sọ pe ajọsọ ti n waye

Gẹgẹ bi ẹka iroyin Punch ṣe ro o laarọ ọjọ kẹsan-an ti awon eeyan naa ti wa nigbekun, wọn ni awọn ajinigbe naa ti ṣi oju opo ibanisọrọ kan pẹlu ijọba ipinlẹ Oyo.

Ẹka iroyin naa ṣalaye pe ibi meji to ṣee gbagbọ lo fidi ẹ mulẹ fawọn akọroyin awọn, pe awọn agbebọn naa sọ pe awon ko ni I ba ẹbi awọn ti won ji gbe sọrọ, bi ko ṣe ijọba nikan.

Gẹgẹ bi ẹka iroyin Punch ṣe fi lede:

"Wọn ni gomina nikan ni awọn fẹ ba sọrọ, awọn ko ni ohunkohun lati ba ẹlomiran sọ.

" Ohun ti won sọ pe awon fẹ niyẹn kawọn too le sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ gan-an. Fun idi eyi, ko sẹni to mọ kókó ati ohun ti wọn n beere lati gba."

Ohun kan ti won ko le fidi rẹ mulẹ bi wọn ṣe wi ni pe boya gomina funra rẹ lo n ba wọn sọrọ ni tabi o ni aṣoju kan to n ba awọn ajinigbe naa dunaa-dura.

Wọn fi kun un pe anfaani ibanisọrọ yii tura ṣaa.

"Ki I ṣe pe awọn eleto aabo ko mọ ohun to yẹ ki wọn ṣe, amọ ewu to rọ mọ ọn lo pọ. Ohun itura lo jẹ pe wọn ti ẹ n sọrọ bayii."

Bẹẹ ni ẹka iroyin Punch ṣalaye pe awọn gbọ latọdọ ẹni to fidi ọrọ naa mulẹ fawọn.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Ẹti to kọja ni awon agbebọn yawọ ile ẹkọ mẹta ti I ṣe Community High School, Ahoro Esinele, niluu Ogbomosọ.

Wọn ṣọṣẹ ni nile ẹkọ alakọọbẹrẹ LA, wọn si gbe olukọ ati awọn akẹkọọ lọ nilẹ ẹkọ alakọọbẹrẹ Baptist, Yawota.

Won pa tiṣa kan, Joel Adesiyan, ninu ikọlu naa, fidio si ṣafihan ibi ti wọn ti dumbu olukọ miran, Michael Oyedokun ninu igbo.

Ṣaaju ni fidio kan ti ṣafihan ibi ti ọga ile ẹkọ naa, Abilekọ Folawe Alamu ati olukọ kan, Mary, ti n rawọ ẹbẹ pe ki ijọba Naijiria ati tipinlẹ Oyo waa gba awọn kuro ninu igbekun ajinigbe ninu igbo.

Iléeṣẹ́ ológun kéde àwọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ gbé ní ìpínlẹ̀ Oyo, ọlọ́pàá ní àwọn tí wọ́n jí gbé ṣì wà ní àhámọ́

Aworan awọn ologun ati abule kan ti awọn agbesunmọmi ti dana sun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ileeṣẹ ọmọogun alaabo orilẹede Naijiria ti ṣalaye wipe awọn agbebọn ti awọn ọmọogun fi ina ija le kuro lawọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria ni wọn wa nidi ijinigbe to waye laipẹ yii ni ipinlẹ Ọyọ.

Ileeṣẹ ọmọogun alaabo lorilẹede Naijiria ṣalaye yii lasiko ti wọn fi n fesi si wọn atẹjade kan to n lọ kaakiri pe ileeṣẹ ọmọogun alaabo sọ ọrọ kan ninu eyi to ti n ṣe iyasọtọ awọn agbesunmọmi atawọn ọdaran to n ṣọṣẹ lẹkun iwọ oorun gusu Naijiria.

Ninu atẹjade kan to fi sita, alukoro ileeṣẹ ọmọ ogun alaabo, Ọgagun Michael Onoja ṣalaye pe awọn awọn ọmọ ẹgbẹ agbebọn Jama'atu Ahlis Sunna Lidda'awati wal-Jihad tawọn ọmọogun Naijiria fi ina ibọn le kaakiri awọn agbegbe ti ina ibọn awọn ologun ti n ro lakọlakọ lorilẹede Naijiria.

"O han kedere pe awọn agbesunmọmi ẹgbẹagbesunmọmi JAS ti awọn ologun ti fi ina fin kuro lawọn agbegbe kan lorilẹede yii ni wọn wa nidi ikọlu ijinigbe to waye ni ipinlẹ Ọyọ."

Ileeṣẹ ọmọogun alaabo ni Naijiria sọ pe irọ ni iroyin to n wi pe awọn ileeṣẹ ologun n sọ pe awọn ọdaran lasan lawọn to n ṣọṣẹ ni ẹkun iwọ oorun gusu Naijiria.

O ni ko si igba kankan ti ileeṣẹ ologun pe awọn agbebọn to n ṣọṣẹ ni ipinlẹ Ọyọ.

Iroyin ofege lo n lọ kaakiri pe awọn ọmọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe ti gba itusilẹ - Ọlọpaa

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ ti kede pe irọ ni iroyin kan to n kaakiri pe awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn jigbe ni ijọba ibilẹ Oriire ti gba itusilẹ. O ni awọn ọlọpaa atawọn agbofinro yooku gbogbo ti n gbe igbesẹ gbogbo to yẹ lati gba itusilẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni irọ lasan lawọn to n gbe iroyin naa n gbe kiri ati pe iroyin ofege ni.