Èmi ò mọ̀ bóyá wọ́n sanwó ìtúsílẹ̀ kankan lórí àwọn àgùnbánirọ̀ tí wọ́n jí gbé n'Imo- Kọmíṣánnà ọlọ́pàá Imo

Oríṣun àwòrán, Audu Bosso/Facebook/Nigerian Police/ X
Lẹyin ti awọn agunbanirọ ogun (20) lati ipinlẹ Oyo ti wọn ji gbe nipinlẹ Imo l'Ọjọbọ to kọja ti gba itusilẹ, ti awọn obi si sọ pe awọn sanwo itusilẹ gba awọn ọmọ naa pada ni, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Imo, Audu Bosso, ti ni oun ko mọ nipa owo itusilẹ kankan ki wọn too tu wọn silẹ l'Ọjọru ana.
Audo Bosso sọrọ yii l'Ọjọbọ, lori eto amohunmaworan kan niluu Eko.
Bosso sọ pe niṣe ni awọn ajinigbe naa pada juwọ silẹ fawọn ẹṣọ alaabo to fọ gbogbo igbo ti wọn tọju awọn agunbanirọ naa si.
O ni ohun ti oun mọ ni pe awọn agbofinro ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bii akọṣẹmọṣẹ, wọn si ṣe ohun to yẹ lati gba awọn agunbanirọ naa silẹ.
O ni wọn wa lọdọ awọn DSS lasiko kan, wọn si tun de ileewosan fun itọju, bo tilẹ jẹ pe wọn ko fi gbogbo ara pa bẹẹ naa.
Igbesẹ to kan ti n lọ bo ṣe wi, lati ṣe ohun to kan lori awọn ti wọn ṣẹṣẹ gba itusilẹ naa.
Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa Imo ti kede pe awọn ti ri eeyan mẹwa gba kalẹ ninu awọn ti wọn ji gbe naa, ati pe iṣẹ ṣi n lọ lati ri awọn yoku.
Lẹyin eyi ni wọn kede pe awọn ti mọ apa ibi ti awọn agunbanirọ naa wa, pẹlu awọn to ji wọn gbe, wọn ni ẹru ado oloro ti wọn fi yi ibẹ po lo n ba awọn lati ku gidi debẹ.
Nigba to di irọlẹ Ọjọru, ọjọ keje oṣu Kẹwaa ni iroyin gbode, pe wọn ti fi awọn agunbanirọ naa silẹ pẹlu awọn ero mi-in ti wọn jọ ji wọn gbe.
Inu igbo Amakohia-Ubi, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Owerri ni wọn ni awọn to wa nigbekun naa ti de.
Gomina ipinlẹ Imo, Hope Uzodimma, si ki awọn agbofinro fun bi wọn ṣe tete da si ọrọ naa.
Amọ ko pẹ ti awọn obi awọn agunbanirọ fi n ṣalaye, pe miliọnu-miliọnu ni awọn da fawọn ajinigbe naa ki wọn too yọnda awọn ọmọ awọn.
Tẹ o ba gbagbe, aadọta miliọnu naira ni awọn ajinigbe naa kọkọ sọ pe awọn fẹẹ gbe lori ẹnikọọkan awọn ti wọn ji gbe ọhun, ki wọn too pada din in ku si miliọnu marun-un naira ẹnikọọkan.
Owo naa ni awọn obi sọ pe awọn san kawọn ọmọ too gba itusilẹ yii, amọ ti Kọmiṣanna ọlọpaa Imo ni oun ko mọ nipa rẹ ni toun.
"Àwa òbí ni a dá owó dọ́là fáwọn ajínigbé kí wọ́n tó tú àwọn àgùnbánirọ̀ ọmọ wa sílẹ̀, ọmọ mi kò sìnrúùlú mọ́ ní Imo"

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force/X
Ọkan lara awọn obi awọn agunbanirọ ogun ti wọn gba itusilẹ lọwọ ajinigbe nipinlẹ Imo ti ṣalaye fun BBC News Yoruba wi pe awọn ajinigbe naa gba owo dọla lọwọ awọn obi ki wọn to fi wọn silẹ.
Obi naa ti ko fẹ ki a darukọ rẹ fidi rẹ mulẹ pe ''ẹnikankan kọ lo ṣokunfa bi wọn ṣe gba awọn ọmọ wa silẹ.
Awọn obi atawọn eeyan lori ayelujara to fi mọ awọn ọrẹ lo dawo jọ fun obi kọọkan lati sanwo tawọn ajinigbe beere fun.
Ijọba o sanwo kankan fun itusilẹ awọn ọmọ wa, ko si nnkan to jọ mọ pe ijọba tabi awọn ẹṣọ eleto aabo doola awọn ọmọ wa.
Amọ, ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS gbiyanju tori awọn ni wọn ranṣẹ pe awọn obi wi pe ki wọn wa lati le ran iṣẹ iwadii wọn lọwọ.
Awọn DSS gan an mọ nipa bi awọn obi ti ṣẹ owo si dọla lọwọ Aboki ki wọn to kowo naa lọ fawọn ajnigbe.
Owo naa si pọ gan an kii ṣe owo kekere.''
Obi to ba BBC News Yoruba sọrọ naa fikun ọrọ rẹ pe oun ko tii fẹẹ sọ nipa iye owo dọla tawọn obi san fun itusilẹ awọn agunbanirọ naa.
Arabinrin naa sọ pe ọmọ oun ko ni ṣe isinruulu mọ ni Imo, o ni oun fẹ ki ajọ NYSC fun un laye lati pada si ipinlẹ Oyo tabi ipinlẹ Ogun lati wa sinruulu rẹ.
Obi naa sọ pe ọmọ oun ko ni sinruulu mọ ti NYSC ko ba gba a laye lati pada wa sinruulu rẹ nipinlẹ Oyo tabi Ogun.
Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria sọ pe awọn ọlọpaa pẹlu iranlọwọ awọn ẹṣọ eleto aabo mii ni wọn doola awọn agunbanirọ ogun naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa tun sọ pe iṣẹ n lọ lati fọwọ ṣinkun mawọn ajinigbe naa.
"Àwọn àgùnbánirọ̀ 20 Oyo tí wọ́n jí gbé ní Imo ti gba ìtúsílẹ̀"- Olubadan Ladoja

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii ni pe awọn agunbanirọ ogun ti awọn ajinigbe da lọna ti wọn si gbe lọ nipinlẹ Imo lọjọ kin-in-ni oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii ti gba itusilẹ.
Gomina ipinlẹ Imo, Hope Uzodinma, fidi ọrọ naa mulẹ ninu ọrọ to ba Olubadan ilẹ Ibadan,Ọba Rashidi Ladoja sọ lori ẹrọ ibanisọrọ.
Oni Ọjọru, ọjọ keje oṣu Kẹwaa ni iroyin itusilẹ naa gbode lọwọ irọlẹ, nnkan bii aago marun-un irọlẹ si ni Uzodinma ba Olubadan sọrọ bi a ṣe gbọ.
Atẹjade lati aafin Olubadan tun fidi itusilẹ awọn agunbanirọ naa mulẹ
Yatọ si ọrọ ori aago ti Gomina ipinlẹ Imo ati Olubadan Rashidi Ladoja sọ, Aafin Olubadan paapaa tun fi atẹjade sita lori itusilẹ awọn agunbanirọ naa.
Akọwe iroyin Olubadan; Adeola Oloko lo fi atẹjade to kede itusilẹ naa lede nirọlẹ Ọjọru.
Bakan naa ni BBC News Yoruba sare ba ọkan lara awọn obi ti ọrọ naa kan sọrọ bi iroyin yii ṣe gbode, wọn si fidi rẹ mulẹ pe òdodo ni, awọn ọmọ naa ti gba itusilẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ayajọ Ominira Naijiria ti ọdun 2026 yii lo n lọ lọwọ, ti iroyin fi jade pe awọn ajinigbe ti ji awọn agunbanirọ to n lọ sinru ilu lati ipinlẹ Oyo gbe ni ipinlẹ Imo.
Ominira ti wọn gba yii lo n waye lẹyin ọjọ keje ti wọn ti wa nigbekun, ti awọn ajinigbe naa si ti kọkọ ni awọn yoo gba biliọnu kan owo itusilẹ, ki wọn too tun din I ku si miliọnu marun-un fun ẹnikọọkan wọn.
























