Igbákejì ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Naijiria ṣáájú àwọn agbófinró ní Imo láti wá àgùnbánirọ̀ 20 àtàwọn èrò mí-ìn tí ajínigbé gbé lọ

Oríṣun àwòrán, The Nigerian Police Force.
Lojuna ati ri awọn agunbanirọ ti iye wọn to ogun (20), atawọn ero ọkọ mi-in tawọn ajinigbe gbe lọ nipinlẹ Imo l'Ọjọbọ ọsẹ yii, Ọga agba ọlọpaa pata lorilẹede Naijiria, Olatunji Disu, ti paṣẹ fun Igbakeji rẹ to wa fun iru iṣẹ bayii, Shehu Nadada, lati lewaju nipa bi wọn yoo ṣe ri awọn ti wọn ji gbe naa gba pada.
Ọga agba ọlọpaa pata paṣẹ naa ninu atẹjade ti Alukoro ọlọpaa Naijiria, CSP Anietie Iniedu, fi sita lọjọ keji oṣu Kẹwaa ọdun 2026.
Aṣẹ IGP Olatunji naa lo gbe DIG Shehu Nadada pẹlu awọn kọmiṣanna ọlọpaa meji mi-in de Imo, lati dari ọna ti wọn yoo fi ri awọn to wa ni ahamọ ajinigbe naa gba pada.
"Iṣẹ ti bẹrẹ pẹrẹwu lati gba awọn to wa nigbekun kalẹ"

Oríṣun àwòrán, The Nigerian Police Force.
Gẹgẹ bi atẹjade ọlọpaa naa ṣe ṣalaye, ẹsẹkẹsẹ ti DIG Nadada ti balẹ sipinlẹ Imo lo ti de ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Alukoro ọlọpaa Naijiria sọ pe bẹẹ naa ni iṣẹ ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lati gba awọn to wa nigbekun ajinigbe naa kalẹ.
O ni DIG Nadada ti ṣagbeyẹwo ilana ti wọn fẹ fi wa awọn eeyan naa ri, ati bi wọn yoo ṣe pin awọn ti yoo ṣiṣẹ naa sibi to yẹ.
O ni eto ti n lọ lori awọn irinṣẹ ti wọn yoo lo pẹlu, ki idari too tun waye lori iṣẹ iwadii naa.
Awọn ti wọn jọ ṣe agbeyẹwo iṣẹlẹ yii bi atẹjade naa ṣe wi ni: Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Imo; Audu Garba Bosso ati Kọmiṣanna ọlọpaa ijọba apapọ to wa fun iṣẹ bawọnyi; Akpan Anifiok.
Bakan naa ni iṣẹ naa kan Kọmiṣanna ọlọpaa to n ri si iwọde atawọn ọga agbofinro miran, titi kan ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo.
Gẹgẹ bi Iniedu ṣe wi, awọn ọlọpaa ti fi kun bi wọn ṣe n wa awọn to wa ni igbekun naa.
O ni wọn ti n lo awọn ikọ ọlọgbọn inu lati fi mọ ibi ti wọn wa gan-an.
O fi kun un pe awọn ileeṣẹ eleto aabo mi-in yatọ si ọlọpaa naa ti da si i.
Ninu ọrọ DIG Nadada ninu atẹjade naa, o fi da araalu loju pe ọlọpaa ko ni i dekun igbiyanju, titi wọn yoo fi ri awọn to wa nigbekun gba pẹlu alaafia.
Bakan naa lo rọ awọn eeyan ilu pẹlu awọn akọroyin, lati ṣe suuru, ki wọn si maa fura.
Bi ẹnikẹni ba ni olobo to fẹ ta ọlọpaa lori ọna to le mu iṣẹ itusilẹ yii ya kiakia, ki iru ẹni bẹẹ tete fi to ileeṣẹ ọlọpaa to ba wa nitosi leti ni wọn wi.
"Gbogbo ohun ti ẹ ba fi to wa leti ni aabo wa fun, ko ni I lu sibi ti ko yẹ."
Bẹẹ ni DIG Shehu Nadada wi ninu atẹjade naa.
O lawọn yoo maa fi to araalu leti bo ba ṣe n lọ nipa agunbanirọ ogun atawọn ero ọkọ mi-in ti ajinigbe gbe lọ .
Wo orúkọ àwọn èrò tó wà nínú ọkọ̀ àwọn àgùnbánirọ̀ tí wọ́n jí gbé lọ́nà ibí tí wọ́n ti ń lọ sìnrúùlú

Oríṣun àwòrán, NYSC/X
BBC News Yoruba ti ṣawari orukọ awọn ero to wa ninu ọkọ awọn àgùnbánirọ̀ tí wọn ji gbe lopopona Onitsha sí Owerri lasiko ti won n rìnrìn ajo lọ sí ipinlẹ Abia níbí ti wọn ti fẹ sìnrúùlú.
Iwadii BBC News Yoruba fidi rẹ múlẹ pe eeyan mẹẹdogun lo wa ninu ọkọ naa to gbera ni agbegbe Samonda niluu Ibadan.
Iwe t'awọn ero ọkọ maa n kọ orúkọ si ni ibudokọ ti a foju gan an ni fi han pe Akande Kehinde, Olaleye Mary, Oladosu Greatness wa ninu ọkọ naa.
Awọn ero mii to wa ninu ọkọ ọhun ni Banuso Rhoda, Abdulraheem Anifat, Esther Oyede, Hassan Usman, Ayomide Isaac ati Mary Makinde.
Azeez Adejoke, Abdulrazaq Anifat, Sarah Temilolu, Adeoye Elizabeth, Eniola Samuel ati Usman Temitope naa wa lara awon to wa ninu ọkọ ọhun.

Oríṣun àwòrán, NYSC/X
Àádọ́ta mílíọ̀nù náírà ni wọ́n sọ pé kí n mú wá láti gba ìtúsílẹ̀ ọmọ mi - Bàbá àgùnbánirọ̀ tí wọ́n jí gbé
Awọn obi ti wọn ji awọn ọmọ wọn gbe nibi ijinigbe to waye ni ipinlẹ Imo ti sọ pe awọn ajinigbe naa ti kan si awọn, ti wọn si ti n beere fun owo itusilẹ lati fi gba itusilẹ awọn eeyan naa.
Ọkan lara awọn obi agbubanirọ naa sọ fun BBC News Yoruba pe awọn ajinigbe naa ti kan si awọn ni owurọ ọjọ Ẹti pe ki awọn lọ wa aadọta miliọnu naira wa fun ọmọ kọọkan ti wọn ba ni ẹmi ọmọ wọn lọ.
Omotosho Adewale, ọkan lara awọn obi ọmọ naa sọ pe funra oun ni oun mu ọmọ oun lọ si ibudokọ to wa ni Samọda ni agbegbe UI niluu Ibadan lati w'ọkọ to n lọ si ipinlẹ Abia ti ọkọ naa si gbera loju oun ni irọlẹ ọjọru.
O ṣalaye pe ọmọ oun ati iya rẹ n sọrọ titi di alẹ ti wọn fi de ilu Onitsha ni ipinlẹ Abia nibi ti wọn sun si mọjumọ ki wọn to tẹsiwaju ninu irinajo wọn ni aago mẹrin owurọ ọjọ keji, ki iroyin to tẹ awọn lọwọ pe awọn ajinigbe ti ji wọn gbe.
O ni lati igba naa ni awọn ti npe ẹro ibaniṣọrọ ọmọ naa titi di owurọ ọjọ Eti kawọn ajinigbe naa to kan si awọn pe ki awọn lọ maa wa aadọta miliọnu naira gẹgẹ bi owo itusilẹ.
Omotosho wa rọ ijoba ipinle Oyo ati ijọba apapọ lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo to wa l'orile ede Naijiria lati gba awọn ọmọ wọn silẹ lọwọ awọn ajinigbe layọ ati alaafia nitori awọn ko ni owo ti wọn n beere fun naa.
Nigba ti a kan si ile-iṣẹ Awọn agunbaniro to wa ni agbegbe Agodi gate niluu Ibadan ṣugbọn awọn ti a ba ni bẹ sọpe awọn ọga ti wọn le bawa sọrọ wani ilu isẹyin ni ibi ti awọn agunbaniro ti wọn ṣẹṣẹ fi ranṣẹ si ipinlẹ Ọyọ wa.
Ibudokọ ti awọn eeyan naa ti wọ ọkọ ti gbe orukọ awọn eeyan tawọn ajinigbe ji gbe naa siita, ti aworan naa si fi han pe eeyan mẹẹdogun ni wọn ji gbe, ti ileeṣẹ ọlọpaa si ni awọn ti gba itusilẹ eeyan mẹwaa ninu wọn
A ti ń ṣiṣẹ́ láti gba ìtúsílẹ̀ àwọn àgùnbánirọ̀ tí wọ́n jí gbé ní ìpínlẹ̀ Imo - Ìjọba Oyo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Oyo ti kọminu lori awọn agunbanirọ to jẹ ọmọ ipinlẹ naa ti wọn ji gbe ni ipinlẹ Imo lasiko ti wọn n lọ lati lọ silẹ baba wọn.
Atẹjade ti Kọmiṣanna ipinlẹ Oyo, Dotun Oyelade fi lede sọ pe iroyin ijinigbe awọn agunbanirọ naa ba oun lọkan jẹ paapaa lasiko yii ti Naijiria n koju awọn ipenija nla kọja.
Ijọba ipinlẹ Oyo sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ ohun to buru gidi, ti awọn si n ṣiṣẹ pẹlu awọn ẹṣọ aabo, ijọba ipinlẹ Imo, awọn alaṣẹ ajọ agunbanirọ lati le gba itusilẹ awọn agunbnirọ naa ni kiakia.
Oyelade ninu atẹjade naa fi kun pe awọn ni ifarajin si gbigba itusilẹ awọn eeyan naa ni ayọ ati alaafia, ti awọn ko si ni ko aarẹ ọkan lati ti pe awọn eeyan naa pada sile wọn layọ.
O fi kun pe Gomina Seyi Makinde ti dari gbogbo awọn ohun to yẹ lati ṣawari awọn eeyan naa, to si tẹmpẹlẹmọ pe aabo ẹmi ati dukia awọn eeyan ipinlẹ Oyo lo jẹ ijọba logun yala ninu ipinlẹ naa tabi lẹyin odi.
Ijọba wa rọ ẹbi awọn agunbanirọ naa lati ṣe suuru pẹlu ijọba, ti ijọba si ṣọ aridaju rẹ lati tẹsiwaju pẹlu iwadii wọn lati gba awọn naa silẹ.
Bakan naa ni wọn rọ awọn ẹṣọ aabo lati pọn kun akitiyan wọn, ki wọn si foju awọn ọdaran to ṣiṣẹ ibi naa wina ofin.
Wọn ni gbogbo awọn alẹnulọrọ to wa lori iṣẹlẹ naa ni awọn n ba ṣiṣẹ lati dena irufẹ ijinigbe bẹẹ lọjọ iwaju.
Ọlọpaa gba itusilẹ mẹwaa ninu awọn ti wọn ji gbe
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo sọ pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati gba itusilẹ awọn agunbanirọ atawọn eeyan mii tawọn ajinigbe ji gbe nigba ti wọn n ṣe irinajo lọ si ibi ti wọn fẹ lọ sin ilẹ baba wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni eeyan mẹwaa ni awọn ti gba itusilẹ wọn ninu awọn eeyan ọhun.
Agbẹnusọ ọlọpaa Imo, Okoye Henry sọ pe opopona Owerri si Onitsha ni wọn ti ji awọn eeyan naa gbe ati pe akitiyan pẹlu awọn ẹṣọ aabo mii ni wọn fi gba itusilẹ awọn eeyan naa silẹ.
O ni nnkan bii aago mẹfa abọ owurọ ni iṣẹlẹ naa waye nigba ti awọn ajinigbe ji awọn agunbanirọ atawọn ero ọkọ mii ti wọn n ṣe irinajo lati ilu Ibadan lọ si ipinlẹ Akwa Ibom ati Abia gbe.
Okoye ni awọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ aabo tete ji giri si ojuṣe wọn eyi to mu ki wọn gba itusilẹ mẹwaa ninu awọn eeyan naa.
O fi kun pe awọn eeyan ti wọn gba itusilẹ wọn ni wọn wa ni alaafia, ti wọn si n gba itọju.
Ohun tí a mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe jí àwọn èèyàn gbé nínú bọ́ọ̀sì tó ń kó àwọn àgùnbánirọ̀ láti Ibadan lọ sí àgọ́ NYSC ní Imo àti Akwa Ibom

Oríṣun àwòrán, KOLA SULAIMON/AFP via Getty Images
Awọn agbebọn kan ti ji awọn eeyan mọkandinlogun, pupọ ninu wọn jẹ agunbanirọ to n lọ bẹrẹ eto isinruulu wọn.
Ọkọ bọọsi meji to ko awọn eeyan arinrinajo naa lawọn agbebọn naa dẹbu rẹ ni ipinlẹ Imo ti wọn si ko awọn eeyan inu rẹ lọ.
Awọn ibudo ifinimọle awọn agunbanirọ to wa ni ipinlẹ Imo ati Akwa Ibom ni awọn bọọsi naa n ko awọn eeyan naa lọ ki wọn to ji wọn gbe ni Ọjọbọ.
Ọgbẹni Isaiah Akpan to ṣalaye ọrọ naa fun BBC sọ pe, '"meji ninu awọn ọkọ mi gbe awọn eeyan lati ilu Ibadan lalẹ ana, ọkan ninu rẹ n lọ si agọ ifinimọle NYSC ni Akwa Ibom, ikeji si n lọ si ti Ipinlẹ Imo".
O ni wọn ji gbogbo awọn arinrinajo inu bọọsi akọkọ gbe, wọn si ji mẹrin gbe ninu ikeji.
"Eyi sọ iye awọn ti wọn ji gbe di mọkandinlogun."
Ki ni ọlọpaa sọ?
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Imo, Henry Okoye sọ fun BBC pe ọrọ naa ti kan awọn ọlọpaa leti.



























