Igun ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ wo ló bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì oníkìlọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́ta? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ kan labẹ asia Joint National Public Service Negotiating Council (JNPSNC) ti bẹrẹ iyanṣelodi ọlọjọ mẹta lati bere fun awọn ẹtọ wọn lọwọ ijọba Naijiria.
Iyanṣelodi naa bẹrẹ lati ọjọ keji, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 yii ti yoo si pari ni ọjọ kẹrin, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi lede lọjọ kinni, ọjọ Kẹwaa, ọdun 2026 to jẹ ayajọ ọjọ ominira Naijiria, wọn ke si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa nileeṣẹ ijọba apapọ, ileeṣẹ ijọba ipinlẹ ati ileeṣẹ ijọba ibilẹ ki wọn darapọ mọ iyanṣelodi ọhun.
Ẹgbẹ naa kilọ pe iyanṣelodi naa ko ṣẹyin ikuna ijọba apapọ lati ṣe ohun ti wọn bere fun ninu lẹta ti wọn kọ si Aarẹ Bola Tinubu lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan an, ọdun 2026 yii.
Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, NLC, ti kin iyanṣẹlodi naa lẹyin gẹgẹ bii Aarẹ ẹgbẹ naa, Joe Ajaero ṣe n lọgun ninu ọrọ to sọ lọjọ kinni oṣu Kẹwaa to jẹ ayajọ ọjọ ominira.
Awọn ẹgbẹ wo lo wa labẹ asia ajọ JNPSNC?
Awọn ẹgbẹ to wa labẹ ajọ to kede iyanṣelodi yii ni Amalgamated Union of Public Corporations, Civil Service Technical and Recreational Services Employees, (AUPCTRE); Nigeria Civil Service Union (NCSU); Nigeria Union of Public Service Reportorial, Secretarial, Data Processors and Allied Workers (NUPSRAW).
Awọn to ku ni National Association of Nigeria Nurses and Midwives (NANNM); National Union of Printing, Publishing and Paper Products Workers (NUPPPROW); Association of Senior Civil Servants of Nigeria (ASCSN) ati The Medical, Nigeria Union of Agriculture and Allied Employees (NUAAE), and Health Workers' Union of Nigeria (MHWUN).
Wayi o,ọpọ araalu lo n woye eredi ti wọn ṣe gunlẹ iyanṣẹlodi lopin ọsẹ dipo aarin ọsẹ ti ijọba yoo ni imọlara rẹ.
Àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ kéde ìyanṣẹ́lódì oníkìlọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́ta

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Apapọ awọn oṣiṣẹ ijọba labẹ igbimọ to n dunaadura pẹlu ijọba lori owo oṣu to kere julọ iyẹn Joint National Public Service Negotiating Council (JNPSNC) ti kede iyanṣẹlodi onikilọ ọlọjọ mẹta bẹrẹ lati ọjọ Keji si ọjọ Kẹrin oṣu Kẹwaa, ọdun 2026.
Wọn ni iyanṣẹlodi naa n waye latatri eto ọrọ aje to ti dẹnu kọlẹ ati iṣoro ati ilakaka tawọn oṣiṣẹ atawọn to n gbarale wọn n koju.
JNPSNC lo jẹ apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC, TUC atawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ mii, ti wọn si maa n panupọ lati fi beere ẹtọ wọn lọwọ ijọba apapọ.
Igbimọ naa, ni ayajọ ominira dari awọn olori wọn kaakiri gbogbo ipinlẹ lati darapọ mọ iyanṣẹlodi naa, ki wọn ma ṣiṣẹ lati ọjọ Ẹti titi di ọjọ Aiku.
Igbesẹ yii lo n waye lẹyin tawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ti n beere lọwọ ijọba apapọ lati ṣe awọn eto to maa adinku ba iṣoro tawọn oṣiṣẹ latari awọn ọwọngogo owo epo, ti wọn si ni ki ijọba apapọ bẹrẹ igbesẹ lati ṣe atungbeyẹwo oṣu to kere julọ fawọn oṣiṣẹ.
Atẹjade kan ti akọwe igbimọ JNPSNC, Olowoyo Gbenga fi lede lọjọ Kiini, oṣu Kẹwaa sọ pe awọn n gbe igbesẹ yii nitori ijọba apapọ kọ lati fesi si awọn kọ ranṣẹ si Aarẹ Bola Tinubu ni ọjọ Kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2026.
Gbenga ninu atẹjade naa rọ awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ, ijọba ipinlẹ ati ijọba ibilẹ lati lati kopa ninu iyanṣẹlodi naa, to si ni awọn fẹ fi iyanṣẹlodi ọhun pe akiyesi ijọba si ilakaka awọn oṣiṣẹ kaakiri Naijiria.
"A rọ gbogbo awọn oṣiṣẹ lẹka ijọba apapọ, ijọba ipinlẹ ati ijọba ibilẹ lati darapọ mọ iyanṣẹlodi yii nitori aarun to n ṣe Abọyade, gbogbo Ọlọya lo n ṣe.
"Gbogbo awọn ọmọ Naijiria lo n kọminu lori ipo ti eto ọrọ aje wa bayii labẹ iṣejọba to wa lode."
Igbimọ naa ni ilakaka ati iṣoro awọn oṣiṣẹ tun pọ si to si ni asiko ti to fawọn oṣiṣẹ lati gbe igbesẹ, ki wọn gba ara wọn lọwọ iṣẹ ati oṣi to n ba awọn oṣiṣẹ finra.
Bakan naa ni wọn tun beere pe ki ijọba apapọ mu adinku ba owo epo bẹntiroolu di ẹẹdẹgbẹta naira (N500), ki wọn si gbe igbimọ to maa dunaasura lori owo oṣu to kere julọ tuntun ti ko ni din ni ẹgbẹrun ẹẹdẹgbẹta naira (N500,000) dide ṣaaju ọdun 2027.
Ibeere yii lo n waye latari bi ọwọngogo ṣe ti n waye ni Naijiria, ti owo ko si to ra ọpọ nnkan mọ latari bi alekun ṣe ti n ba owo ọkọ, owo ounjẹ atawọn ohun elo ile mii.
Wọn ni awọn nigbagbọ pe iyanṣẹlodi naa maa so eso rere, ti awọn si maa tẹsiwaju pẹlu iyanṣẹlodi naa.




























