Ṣé lóòótọ́ ni bàlúù ọmogun Naijiria míì fi pàjáwìrì bà sínú oko kan, lẹ́yìn èyí tó pa èèyàn 25 ní Igbokoda? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Screenshot/Rufai Oseni/X
Ileeṣẹ ọmogun ofurufu Naijiria ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ si ẹlikopita kan ti fidio kan lori ayelujara ṣafihan bo ti ba sinu oko kan nipinlẹ Benue.
Adari eto iroyin fun ileeṣẹ ọmogun ofurufu, Air Commodore Ehimen Ejodame, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita pe baluu ẹlikopita naa n bọ lati ibi tawọn ọmogun ti lọ ṣekọlu sawọn ajinigbe ni nigba to ba sinu oko kan ti ọpọ eeyan ti ri i.
Oriṣiiriṣii fọto ti BBC ko le sọ ibi ti wọn ti wa lo wa lori itakun ayelujara to n ṣafihan baluu ologun ọhun ninu oko ka,
Eyi ṣẹlẹ lẹyin tawọn kan ti sọ ṣaaju wi pe pajawiri ni baluu ologun naa fi ba sinu oko yii ni Benue.
Ṣugbọn ileeṣẹ ọmogun ofurufu ti ṣalaye wi pe baalu naa ba sinu oko ti o to mẹẹli mẹwaa sibi to ti gbera fun aabo awọn to wa ninu rẹ lẹyin ti wọn ti ṣekọlu sawọn ajinigbe tan.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ologun ofurufu fikun ọrọ rẹ pe ẹlikopita yii lọ ṣeranwọ fawọn ọmogun oriilẹ to kọju ija sawọn ajinigbe ni agbegbe Ogbadigbo to wa ni ẹgbẹ ibode ipinlẹ Benue ati Enugu.
Ọgagun Ejodame sọ pe baluu yii da isẹ ibi awọn ajinigbe naa ru, lẹyin ti wọn ṣeranwọ fawọn ọmogun oriilẹ tan.
Ileeṣẹ ọmogun ofurufu ni awakọ baluu ọhun tẹle awọn ilana to yẹ ko tẹle nipa eto aabo ki baluu naa ba sinu oko to ba si i.
Ejodame ṣalaye pe ''ẹlikopita yii ti pada si ibi to ti gbera lọ ṣiṣẹ ni alaafia pẹlu awọn ọmogun oriilẹ.''
Ileeṣẹ ọmogun ofurufu ko sọ boya ẹnikankan farapa ninu baluu naa tabi boya nnkankan bajẹ lara baluu ọhun.
Iṣẹlẹ ijinigbe jẹ ọkan lara iṣoro eto aabo to n koju Naijiria papaa julọ lẹkun ariwa ati lẹkun aaringbungbun orilẹede Naijiria.
Eeyan ti ko din ni 7,825 ni iroyin fidi rẹ mulẹ pe wọn ji gbe laarin oṣu Keje ọdun 2025 si oṣu Kẹfa ọdun 2026.
Oriṣiiriṣi iṣẹlẹ ijingbe ati ija laarin awọn darandaran atawọn agbẹ lo ti n ṣẹlẹ nipinlẹ Benue.
Eeyan bii 1,338 lo ku ninu oriṣiiriṣii rogbodiyan to waye nipinlẹ Benue laarin oṣu Kinni ọdun 2024 si ọsu Kẹjọ 2025 gẹgẹ bi iroyin ṣe fidi rẹ mulẹ.
Ọpọ eeyan ni rogbodiyan to n ṣẹlẹ ti le kuro ni ibugbe wọn nipinlẹ Benue.



























