Wo àwọn olóṣèlú tí wọ́n ṣèlérí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù ìbò fún Tinubu lọ́dún 2027

Bello Matawalle, Atiku Bagudu, Tunji Alausa, ati Monday Okpebholo
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Bi eto idibo apapọ ọdun 2027 ṣe n sunmọ etile, awọn agba oloṣelu kan ati awọn oniruuru ẹgbẹ to n ṣatilẹyin fawọn oloṣelu kaakiri Naijiria ti bẹrẹ sii fi atilẹyin wọn han si Aarẹ Bola Ahmed Tinubu.

Pupọ ninu awọn ẹgbẹ ati oloṣelu wọnyi ni wọn si ti n ṣeleri ẹgbẹẹgbẹrun ibo fun Aarẹ Tinubu lawọn ilu, ipinlẹ ati agbegbe ti wọn ti lẹnulọrọ jakejado Naijiria.

Lati Ariwa titi de Guusu, oniruuru ileri ifọkanbalẹ ni awọn oloṣelu ati alẹnulọrọ ti n ṣeleri wi pe wọn yoo ṣiṣẹ takuntakun lati rii daju pe ipo naa ja mọ Aarẹ Tinubu lọwọ fun igba keji.

Ṣugbọn ṣa, pẹlu awọn ileri to jọju wọnyi, oriṣiriṣi ibeere lo ti n jẹyọ lori awọn ipa to n ṣe ileri wọnyi, ati boya wọn yoo mu awọn ileri naa ṣẹ nigba ti asiko eto idibo ba de.

Eyi la fi n ṣagbeyẹwo awọn ileri ti awọn eeyan ṣe fun Tinubu, ati boya awọn ileri naa yoo wa si imuṣẹ.

Bello Matawalle – Ibo miliọnu lọna ogun

Bello Matawalle mu ẹrọ gbohungbohun dani lasiko to n sọrọ

Ọkan lara awọn onka ibo to pọ julọ ni ti ileri ti minisita feto aabo, Bello Matawalle ṣe lati pese ibo ti ko din ni miliọnu lọna ogun fun Tinubu.

Matawalle lo ṣeleri yii lasiko to n sọrọ nibi ifilọlẹ ẹgbẹ oṣelu kan ti wọn pe ni "Tinubu Agai", eyi to waye niluu Abuja.

Gomina ipinlẹ Zamfara tẹlẹ naa sọ fawọn eeyan pe gbogbo igberiko ati agbegbe to sunmọ araalu ni wọn yoo ṣatilẹyin fun aarẹ ni

"A ni lati lọ ba awọn eeyan sọrọ, ka si da wọn lẹkọọ, ka si fi to wọn leti nipa awọn ohun ti ijọba yii n ṣe, awọn ohun ti Bola Ahmed Tinubu n ṣe fawọn eeyan, ipinnu rẹ, agbekalẹ rẹ, afojusun rẹ, ati awọn nnkan to ni lati ṣe fawọn ọmọ Naijiria," Matawalle sọ bẹẹ.

Bagudu Network for Tinubu - ibo miliọnu mọkandinlogun

Atiku Bagudu lo n rẹrin yii

Yatọ si Matawalle to ṣeleri, ẹgbẹ alatilẹyin fun oṣelu kan ti wọn pe ni 'Atiku Bagudu Grassroots Network for Tinubu 2027' naa tun ti ṣeleri lati pese ibo ti ko din ni miliọnu mọkandinlogun kaakiri ẹkun ipinlẹ Ariwa mọkandinlogun fun Aarẹ.

Minisita feto iṣunu ati agbekalẹ, Atiku Bagudu ni baba isalẹ ẹgbẹ yii.

Ṣugbọn olori ẹgbẹ naa, Ọnarebu Ali Oriri sọ pe ẹgbẹ naa yoo tan kaakiri gbogbo ẹkun Ariwa mọkandinlogun to wa ni Naijiria lati rii pe awọn eeyan jade dibo fn Tinubu.

Lọsẹ yii, ẹgbẹ naa ṣepade niluu Abuja lati ṣagbekalẹ eto ironilagbara lori ọna ti wọn yoo gba lati mu ileri wọn ṣẹ.

Tunji Alausa – ibo miliọnu mẹwaa

Tunji Alausa wọ aṣọ alawọ aro pẹlu fila alawọ dudu, bẹẹ ni ẹrọ gbohungbohun wa niwaju rẹ

Oloṣelu miran to tun ṣeleri ibo fun Aarẹ Tinubu ni minisita feto ẹkọ ni Naijiria, Tunji Alausa, ẹni to ṣeleri ibo miliọnu mẹwaa fun aarẹ.

Ọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii ni minisita naa ṣeleri pẹlu ifọwọsọya nibi ipade akọkọ ti igbimọ ẹgbẹ olupolongo APC ti wọn pe ni APC Presidential Campaign Committee, ẹka eto ẹkọ ṣagbekalẹ rẹ.

Nibẹ ni wọn ti ṣe ifilọlẹ eto ipolongo idibo fun Tinubu lati ọdọ awọn akẹkọọ, olukọ, ati awọn alẹnulọrọ lẹka eto ẹkọ.

Minisita naa sọ pe ẹka eto ẹkọ, pẹlu ọpọlọpọ ile ẹkọ to wa labẹ rẹ kaakiri Naijiria ni agbara lati ri awọn oludibo rẹpẹtẹ fun Aarẹ Bola Ahmed Tinubu.

"Bi a ba ṣiṣẹ takuntakun, o yẹ ka le ni ibo miliọnu mẹwaa lati ẹka eto ẹkọ nikan fun aarẹ," o sọ bẹẹ.

Gomina ipinlẹ Edo – Ibo miliọnu meji aabọ

Monday Okpebholo de fila, o lo igo soju, bẹẹ lo n rẹrin lori ijokoo to wa

Bakan naa ni Gomina Monday Okpebholo tun ṣeleri ibo miliọnu meji aabọ kaakiri ipinlẹ naa fun Tinubu ninu eto idibo apapọ ọdun 2027.

Okpebholo sọ eyi lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii nibi iwọde APC ti wọn ṣe nijọba ibilẹ Ikpoba-Okha, ipinlẹ naa.

Nibẹ lo ti foju gbogbo awọn to n dije fun ipo oṣelu nipinlẹ naa lọdun 2027 han fun gbogbo araalu.

"Ẹgbẹ oṣelu APC ti ṣagbekalẹ ipilẹ to duro ṣinṣin kaakiri ipinlẹ yii, bẹẹ lo si wa nibi to yẹ ṣaaju eto idibo to n bọ lọna."

Okpebholo fi kun ọrọ rẹ pe ẹgbẹ naa ni igboya wi pe awọn yoo jawe olubori nipasẹ ipilẹ rere ti wọn ti fi lelẹ kaakiri ijọba ibilẹ ati Naijiria.

Senetọ Olamilekan Adeola – ibo miliọnu meji

Bakan naa ni oludije sipo gomina nipinlẹ Ogun, Sẹnẹtọ Solomon Olamilekan Adeola tọpọ mọ si Yayi ti ṣeleri lati gbe ibo miliọnu meji dide fun aarẹ lọdun 2027.

Yayi ṣeleri yii nibi ifilọlẹ ẹgbẹ alatilẹyin oṣelu ti wọn ṣe ni City Boy Movement laipẹ yii, to si ni kaakiri ipinlẹ naa lawọn eeyan yoo ti jade.

"Ipinlẹ Ogun ni awọn oludibo to le ni miliọnu mẹta, pẹlu iye yii, mo lero wi pe Aarẹ Tinubu yoo ri ibo miliọnu meji to kere julọ ninu eto idibo ọdun 2027," Adeola sọ bẹẹ.

Njẹ wọn le mu awọn ileri yii ṣẹ bi?

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn akọṣẹmọṣẹ nipa ọrọ oṣelu ti sọ pe pupọ ninu awọn ileri wọnyi lo ṣoro lati muṣẹ, nitori pe awọn kan ko tiẹ ṣoju-ṣaara ninu wọn.

Ninu eto idibo ọdun 2023, ibọ miliọnu mẹjọ ni Tinubu fi bori ninu apapọ ibo to din diẹ ni miliọnu marundinlọgbọn.

Idi ree ti awọn onimọ nipa ọrọ oṣelu fi jẹ ko di mimọ pe ko si aridaju nibẹ, bi ko ṣe pe ọrọ oṣelu lasan ni.

Ọmọwe Kabiru Sa'id Sufi, olukọ kan ni fasiti ipinlẹ Kano, sọ pe ọrọ oṣelu lo n ti wọn, ti wọn fi n ṣeleri naa.

"Awọn oludahun si ọrọ oṣelu ni, ẹnikọọkan wọn n fẹ lati tẹ ọga rẹ lọrun ni, lati le bori ijakadi," o sọ bẹẹ.

O fi kun ọrọ rẹ pe ninu awọn oloṣelu yii ni wọn n ṣe awọn ileri wọn lai wo iye awọn oludibo to wa nipinlẹ wọn.

"Bi ẹ wo iye awọn to forukọsilẹ fun eto idibo, eyi ti INEC gbe jade laipẹ yii, ẹ maa rii pe iye awọn oludibo to wa nibẹ kere si iye ibo ti awọn oloṣelu yii n ṣeleri rẹ," onimọ nipa oṣelu naa sọ bẹẹ.

O tẹsiwaju pe ọrọ igbaniniyanju lasan ni awọn ileri naa, ti kii sii ṣe nnkan ti wọn le fidi rẹ mulẹ.

Ki lo maa n fa awọn ileri wọnyi?

Ọmọwe Kabiru Sufi sọ pe idi mẹta si mẹrin pataki lo maa n fa ileri awọn oloṣelu wọnyii.

Wọn n wa ojurere lọdọ aarẹ

Gbigba awọn ololufẹ wọn niyanju

Fifikun ọrọ ipo oṣelu wọn

Bi iru esi bẹẹ ba jade, ko ma le ya awọn eeyan lẹnu.

O wa fi kun ọrọ rẹ pe pupọ awọn oloṣelu wọnyi lo maa n ṣe awọn ileri bayii, lati le daabo bo ọjọ iwaju wọn.

"Iyẹn ni pe, bi wọn ba bori awon eto idibo naa, ki ijọba ṣiṣẹ pẹlu wọn," o kadi ọrọ rẹ nilẹ.