Ìgbẹ́jọ́ ọmogun 36 tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n fẹ́ dìtẹ̀ gbàjọba Tinubu bẹ̀rẹ̀ nílé ẹjọ́ iléeṣẹ́ ológun Naijiria

Oríṣun àwòrán, Defence Headquarters/X
Igbẹjọ awọn ọmogun mẹrindinlogoji ti ijọba fẹsun kan pe wọn gbimọ pọ lati gbajọba Aare Bola Tinubu ti bẹrẹ nile ẹjọ ileeṣẹ ologun Naijiria.
Olu ileeṣẹ ologun Naijiria to ṣe ifilọlẹ igbẹjọ naa lonii ọjọ Ẹti ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹrin yii sọ pe ẹsun iditẹ eyi to lewu fun aabo orilẹede lẹsun ti wọn fi kan awọn ọmogun naa.
Igbẹjọ naa n waye ni Guards Brigade Scorpion Mess, Asokoro, niluu Abuja nibi tawọn ologun ti ruro wamu wamu.
Awọn akọroyin ko lanfaani lati wọ ibi ti igbẹjọ naa ti n waye.
Ileeṣẹ iroyin NAN ṣalaye pe ni deedee ago mẹsan an owurọ ọjọ Ẹti ni wọn gbe awọn afurasi naa lọ ibi igbẹjọ ọhun nibi tawọn agbẹjọro wọn ti wa bawọn.
Ninu atẹjade ti olu ileeṣẹ ọmogun fi sita, o ṣapejuwe igbẹjọ naa gẹgẹ bi igbesẹ pataki fun ibawi awọn ọmogun.
Olu ileeṣẹ ọmogun ni awọn ko ni figa kan bọ ọkan ninu lori igbẹjọ naa.
Loṣu Kẹwaa ọdun 2025 ni ileeṣẹ ọmogun Naijiria kede pe awọn ti mu awọn ọmogun mẹrinlogun lori ẹsun wi pe wọn tasẹ agẹrẹ.
Lẹyin naa ni iwadii tẹsiwaju ti wọn si mu awọn afurasi mii lori ẹsun igbimọpọ lati ditẹ gbajọba.
Iditẹgbajọba ologun ko tii waye lati igba ti orilẹede Naijiria ti pada si eto ijọba awarawa lọdun 1999.
Amọ, awọn ologun ṣejọba orilẹede Naijiria fun ọpọlọpọ ọdun lẹyin ominira lọdun 1960.
Eyi gan an lo jẹ ki ọrọ awọn afurasi to fẹ ditẹ gbajọba maa n kọ ọpọ eeyan lominu.
Gomina ipinlẹ Bayelsa tẹlẹ ri, Timipre Sylva, to wa lara awọn afurasi naa ti na papa bora
Ṣaaju laarin ọsẹ yii ni ijọba apapọ ti kọkọ gbe afurasi meje lọ sile ẹjọ giga apapọ niluu Abuja lori ẹsun iditẹgbajọba, igbesunmọmi atawọn ẹsun mii.
Mẹfa ninu awọn afurasi ọhun lo farahan nile ẹjọ ti wọn si sọ pe awọn o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.
Minisita fun epo rọbi tẹlẹ to tun jẹ gomina ipinlẹ Bayelsa tẹlẹ ri, Timipre Sylva, ni ẹnikeje amọ ko farahan nile ẹjọ.
Ohun ti a gbọ ni pe o tin a papa bora.
Adajọ paṣẹ pe ki wọn ko awọn afurasi naa si atimọle ajọ DSS titi ti igbẹjọ yoo fi tẹsiwaju lọjọ Aje to n bọ tii ṣe ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹrin yii.
Ohun to n ṣẹlẹ lori ọrọ naa ni pe awọn ileẹjọ ologun lo n ṣe igbẹjọ awọn ọmogun to si wa lẹnu iṣẹ, nigba tawọn ajagun fẹyinti atawọn eeyan mii ti wọn fẹsun iditẹgbajọba kan n ṣẹjọ tiwọn nile ẹjọ giga apapọ.

























