Oògùn ni àwọn darandaran kọ́kọ́ fi na ọkọ mi kí wọ́n tó ṣa wẹ́lẹwẹ̀lẹ - Ìyàwó Oloye tí darandaran pa n'Ibadan
Àwọn mọlẹbi Oloye Mutairu Oladosu, to jẹ Otun Balogun Okelade Okin, lagbegbe Omi Adio nipinlẹ Oyo ti awọn afurasi Fulani darandaran ṣa pa sinu oko rẹ ti ba BBC Yoruba sọrọ.
Wọn sọ fun BBC pe asiko ti awọn darandaran naa n fi ẹran jẹko ninu olo oloogbe lo sọ fun wọn pe ki wọn kuro ninu oko oun, amọ iku ojijiji ni wọn fi fesi fun.
Latifat Oladosu, to jẹ iyawo oloogbe sọ pe oun ati ọmọ oun sa asala fun ẹmi wọn ni awọn afurasi naa ko gbẹmi awọn naa.
O ṣalaye oogun ni wọn kọkọ fi na Oloye naa ki wọn to bẹrẹ si n di ada ṣa.
Ẹgbọn oloogbe, Alimi Osuolade sọ fun wa ẹgẹ ti oloogbe naa ti wu to si fẹ ta ti awọn maluu naa jẹ lo m k wọn gbẹmi rẹ.
O ni gbogbo igbiyanju oloogbe naa lati le awọn darfandaran naa kuro lori ilẹ rẹ lo ja si pabo ki wọn to pa a.
Ẹwẹ, iya oloogbe naa ti sọ pe ọkan awọn ko balẹ mọ bayii latari pe awọn afurasi naa ti ṣeleri pati pada wa fun ikọlu mii.
Wayi o, a gbọ pe ọwọ tẹ ọkan lara awọn afurasi to gbẹmi oloogbe naa, o si ti wa lakata awọn agbofrinro fun iwadii.



