Amẹ́ríkà wọ́gilé ìjíròrò pẹ̀lú Iran, bí Iran ṣe ní àbẹ̀wò sí Pakistan kìí ṣe nítorí ogun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ààrẹ Amẹ́ríkà , Dinald Trump ti ni àwọn aṣoju Amẹ́ríkà kanjan kò ní lọ sí Islamad fun ijiroro pẹlu Iran.
Trump sọ eyi ninu atẹjade kan to fi sori ikanni ayelujara rẹ, Truth Social lọjọ Abamẹta.
Trump sọ loju opo naa pe oun wọgile irinajo awọn to fẹ lọ ṣoju Amẹrika nibi ijiroro pẹlu Iran ni Pakistan nitori o jẹ fifi ọpọlọpọ akoko ṣofo ni.
O ni gbogbo nnkan ni awọn ni lati fi bori ogun pẹlu Iran ṣugbọn ti Iran ko ni ohunkohun.
O sọ pe ohun ti Iran ni lati ṣe ti wọn ba fẹ ijiroro ko ju ki wọn pe awọn lori foonu lọ.
"Mo ti sọ fun awọn eeyan mi nigba ti wọn mura lati maa lọ si Pakistan pe ki wọn jokoo sile, ẹ o ni lọ si irinajo fun wakati mejilelogun loju ofurufu lati lọ jokoo jiroro lori ohun ti ko ni so eso rere."
Ṣaaju ni ireti wa pe Jared Kushner ati Steve Witkoff maa kopa nibi ijiroro laaarin Amerika ati Iran to n waye ni Pakistan lojuna ati fopin si ogun ti Amerika ati Israel n gbe ti Iran.
Ni ọjọ Ẹti ni Amẹrika sọ pe Iran ti n gbe awọn igbesẹ kan, ti wọn si n gbe awọn aba kan siwaju eyi ti awọn maa gbe yẹwo daadaa, ti wọn si maa jiroro le lori.
Ni owurọ ọjọ Abamẹta ni Minisita fọrọ ilẹ okeere Iran, Abbas Araghchi ti kọkọ ṣe ipade pẹlu olori ologun Pakistan, Asim Munir.
Awọn alaṣẹ Iran sọ pe awọn ko ni ifọkantan ninu ijiroro ti Amẹrika fẹ ṣe pẹlu awọn amọ awọn ọmọ ogun awọn ti gbaradi lati koju ikọlu ti Amẹrika ba fi le gbe yọju lasiko yii.
Lẹyin naa ni Araghchi ni oun ti ṣepade pẹlu olootu ijọba Pakistan, Shehbaz Sharif ti oun si ti sọ nipa awọn nnkan ti orilẹ ede oun n fẹ nipa didawọ ogun duro.
O ni oun ni igbagbọ pe ijiroro ṣi maa tẹsiwaju amọ to ti kuro ni Pakistan lati tẹsiwaju irinajo rẹ lọ si Oman ati Russia.
Olootu ijọba Pakistan, Shehbaz Sharif ninu atẹjade to fu soju opo X rẹ sọ pe ijiroro ti awọn ni pẹlu Iran lọ deedee ati pe awọn jiroro lori awọn ohun to ṣe pataki to fi mọ ijiroro lori ibaṣepọ laaarin Pakistan ati Iran.
Olootu ijọba tẹmpẹlẹmọ pataki ijiroro ki alaafia ati iduro ire bi ẹkun naa.

























