Ohun márùn ún ọ̀tọ̀tọ̀ tí Adeleke ní òun yóò ṣe fún ìpínlẹ̀ Osun ní sáà kejì rẹ̀ lórí oyè

Ademola Adeleke wọ aṣọ funfun ati fila pupa
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

‎Gomina Ademola Adeleke ni oun ti ṣetan lati tun fi ara oun jin fun gbogbo olugbe ipinlẹ Osun nipa mimu aye dẹrun fun wọn.

‎O ni gbogbo awọn iṣẹ akanṣe ti o lọ kaakiri ipinlẹ ọhun ni oun yoo kọkọ pari ki oun to bẹrẹ iṣẹ akanṣe miran lọtun.

‎Gomina Adeleke tun ṣeleri pe oun yoo pese iṣẹ fun awọn ọdọ to ni iwe ẹri ṣugbọn ti ko si iṣẹ lọwọ wọn. Bakan naa lo ni gbogbo ile ẹkọ to nilo atunṣe ni oun yoo tun ṣe.

Adeleke lo sọrọ yii lasiko ti wọn burawọle fun fun saa keji niluu Osogbo.

Gomina ọhun ni oun yoo gba awọn olukọ si gbogbo ile ẹkọ alakobere ati ti girama jakejado ipinlẹ Osun.

‎O tun fi kun ọrọ rẹ pe oun ti ba aarẹ Bola Tinubu ṣe ipade lori ọrọ owo ijọba ibilẹ n to da wahala ṣilẹ ni ipinlẹ naa.

‎Gẹgẹ bo ṣe sọ, abajade ipade naa ni pe, laarin ọsẹ meji si asiko yii ni gbogbo ọrọ owo ijọba ibilẹ nipinlẹ Osun yoo yanju, yoo si di oun igbagbe, alaafia yoo si jọba ni ijọba ibilẹ kọọkan nipinlẹ naa.

‎Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ aarẹ Bola Tinubu fun ipa to ti ko lori owo ijọba ibilẹ naa ati lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Osun fun atilẹyin wọn fun ijọba oun.

Wo gbogbo ǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ níbi ayẹyẹ ètò ìbúra sípò gomina Ademola Adeleke nipinlẹ Osun

Gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Osun, o wọ agbada alawọ aro pẹlu fila alawọ kan naa. O n rẹrin-in bẹẹ lo fi ika ọwọ rẹ meji sibi oju rẹ osi, o fi ilẹkẹ meji si ọrun ọwọ rẹ osi.

Ètò ìbúra wọlé fún Gómìnà Ademola Adeleke fún sáà kejì yóò wáyé lónìí, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, osù Kọkànlá ọdún 2026

Lẹyin to jawe olubori ninu idibo sipo gomina ipinlẹ Osun ninu eto idibo to waye lọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii, oni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla ọdun 2026 ni wọn yoo ṣeto ibura wọle fun saa keji fun Gomina Ademola Adeleke, niluu Osogbo, ipinlẹ Osun.

Ori papa iṣere to wa ni agbegbe Ọmọ West, niluu Osogbo ni eto iburawọle naa yoo ti waye.

Koda, ‎Igbakeji Aarẹ orilẹede Naijiria, Kashim Shetima, ti de si ipinlẹ Osun bayii fun ayẹyẹ ibura wọle naa.

‎Diẹ ninu irin-ajo Gomina Ademola Adeleke sinu oṣelu

Gomina Ademola Adeleke n sọrọ lọwọ ninu aworan yii, o mu ẹrọ gbohun-gbohun dani. Aṣọ alawọ aro lo wọ, o si de fila ẹgbẹ Accord ti wọn kọ imọlẹ si, awọ ofeefe ni fila naa.
Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‎Ọdun 2017 ni Ọmọọba Ademola Adeleke kọkọ gbegba ibo ninu oṣelu, iyẹn nigba to dije fun ipo Sẹnetọ loṣu Keje ọdun 2017, labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, o si yege.

‎Eleyi ko ṣẹyin iku ti Isiaka Adetunji Adeleke to jẹ ẹgbọn fun Gomina Ademola Adeleke ku nigba naa. Bo tilẹ jẹ pe inu ẹgbẹ oṣelu APC ni Isiaka Adetunji Adeleke ti du ipo Sẹnetọ lakoko igba naa ki ọlọjọ too de.

‎Gomina Adeleke lo osu diẹ ni ile ìgbìmọ̀ asofin agba ni ilu Abuja gẹgẹ bi Sẹnetọ to n ṣoju Iwọ-Oorun Osun ( Osun West), ko too wa dije du ipo gomina ni ipinlẹ Osun ni 2018.

‎‎Eto idibo si ipo gomina ni 2018 naa kun fun orisirisi ipenija, eyi to mu ki Adeleke tawọn eeyan mọ si Sẹnetọ Onijo, fidi rẹmi ninu ibo naa.

‎Ẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori lọdun naa lọhun-un, ibo naa lo gbe gomina ana; Gboyega Oyetola wọle nipinlẹ naa bii gomina kẹsan-an nipinlẹ Osun.

‎‎Ṣugbọn Adeleke ko jẹ ki aarẹ mu oun lati ma dije mọ, o tun du ipo gomina ni 2022, o si pada yege ninu ẹgbẹ oṣelu PDP to ti dije.

Wọn bura wọle fun un gẹgẹ bii gomina Osun ni saa akọkọ lọjọ kẹtadinlọgbọn, osu Kọkanla ọdun 2022, oun si ni Gomina Kẹwaa nipinlẹ Osun.

Gomina Ademola Adeleke n ba ijọba rẹ lọ l'Osun ni saa naa, amọ rogbodiyan wa ninu ẹgbẹ PDP to gbe e depo.

Nigba to ya lo kuro ninu PDP latari wahala ẹgbẹ, o darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Accord.

Rogbodiyan tun bẹrẹ si i ṣẹlẹ l'Osun latari ibo to n bọ ati ẹgbẹ Accord ti gomina wọ. Ipaniyan pọ kaakiri Osun,ipaya ati ibẹrubojo si gba gbogbo ilu naa ṣaaju idibo.

‎Amọ pẹlu gbogbo ẹ naa, Ademola Adeleke tun jawe olubori ninu ibo gomina to waye lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii.

‎Abajade ijawe olubori naa ni wọn yoo fi bura fun Ademola Nurudeen Jackson Adeleke lonii, fun saa ọdun mẹrin miran titi di 2031.