Mo fẹ́ di ológo nlá lágbo olórin lọ́dún méjì sí àsìkò yìí - Magixx

Oríṣun àwòrán, Magixx/Instagram
Gbajumọ ọdọmọde olorin, Adelabu Alexander, tawọn eeyan mọ si Magixx ti sọ pe
oun fẹ di ologo nla lọdin meji si asiko yii.
Magixx tun sọ fun BBC News Yoruba wi pe oun fẹran obinrin gan an ,amọ, o ni iwọntunwọnsi naa ni gbogbo nnkan.
Ṣugbọn Alexander ni kii ṣe tori obinrin loun fi n ṣiṣẹ akọrin.
Magixx ni ọkan ko di ọkan lọwọ tori oun mọ nnkan toun n ṣe.
O ni Adelabu Alexander ati Magixx o jinna sira wọn, ''mo maa n gbiyanjuu lati ma ya awọn mejeeji.
Mo maa n gbe igbe aye ti ara mi gan an gan an.
Inu mi dun nigba ti Don Jazzy pe mi lọdun 2020 tori anfaani nla ni mo ni tori kii ṣe gbogbo eeyan ni Don Jazzy maa n pe.''
Magixx ni o ni nnkan ti Don Jazzy maa ri lara olorin ki o to le pe e.
Ọdọmọde akọrin naa sọ pe bi oun ṣe darapọ mọ ileeṣẹ olorin Mavins jẹ nnkan to yi aye oun pada si rere.
Alexander ni ọdun 2021 ni Don Jazzy gbe orin oun sita lẹyin tawọn ti jọ ṣiṣẹ pọ lori oniruuru orin lọdun 2020.
O ni bayii ni orin toun kọ pẹlu akọle – ''Love don't cost a dime and All Over'' ṣe sọ oun di ilumọọka.
Magixx ni kii ṣe orin ifẹ nikan loun n kọ, ṣugbọn awọn orin ifẹ toun ti kọ lo jẹ ki ọpọ eeyan mọ oun.
Adelabu ni oniruuru orin bii hip-hop, raggae ati bẹẹ bẹẹ lọ loun maa n kọ.






