"Ọlọrun ti gba ọkọ mi!" Niniola, gbajúmọ olórin tàkasúfèé kéde ikú ọkọ rẹ̀

Aworan Niniola ati ọkọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, officialniniola/ instagram

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Eekan akọrin takasufe obinrin ni, Niniọla Apata ti kede iku ọkọ rẹ.

Gbajumọ akọringbayi naa kede eyi ninu awọn ọrọ to fi lede loju opo ayelujara Instagram rẹ ni kutu ọjọru.

Aworan Niniola ati ọkọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, officialniniola/instgram

Niniọla kọ ọ si oju opo rẹ: "Ọlọrun ti gba ọkọ mi,".

"Ọkọ mi ti ku" lo fi kun un.

O ni ọdun mẹtala lawọn ti fi n fẹra.

Ninu ọkọọkan atẹjade to fi sita naa lo ti fi fọto oun ati ọkọ rẹ sii.

Aworan Niniola ati ọkọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, officialniniola/instgram

Ko tii si ẹni tii mọ ohun gan to ṣe okunfa iku ọkọ rẹ naa nitori pe gbajumọ olorin obinrin yii ko fi igba kankan gbe iroyin nipa ile rẹ sode gbangba tabi ayelujara ri.

Aworan Niniola ati ọkọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, officialniniola/instgram

Niniọla, ẹni ọdun mọkandinlogoji di ilu mọọka lẹyin to moke nibi idije orin kikọ Project Fame West Africa lọdun 2013, to si ti gba ibẹ di ọkan lara awọn olorin lati Naijiria to ti di ogo agbaye.

Tani ọkọ Niniọla to jade laye?

Aworan Niniola ati ọkọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, officialniniola/instgram

Orukọ ọkọ Niniọla to jade laye naa ni Michael Ndika.

Nigba aye rẹ oun ni oludari agba ileeṣẹ NaijaReview to jẹ ileeṣẹ nla kan to n ṣe agbodegba fun orin igbalode lati ilẹ Afrika.