You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ohun tó yẹ kí o mọ̀ bí Trump ṣe ń ṣàbẹ̀wò sí Ààrẹ Xi ní China
Aarẹ ilẹ America, Donald Trump, ti balẹ si ilu Beijing, lorilẹede China.
Ọdun 2017, nigba to n ṣe saa rẹ akọkọ gẹgẹ bi aarẹ America ni Trump ti ṣe abẹwo bayii gbẹyin si China.
Ọjọ meji ni yoo fi ṣepade pẹlu Aarẹ Xi Jinping ti ilẹ China. Oṣu Kẹta ọdun yii ni wọn fi ipade yii si tẹlẹ, amọ ogun Iran ti America ati Israel n ja ko jẹ ko ṣee ṣe nigba naa.
Ki ni idi ti Trump fi lọ si China?
Koko irinajo naa gẹgẹ bii afojusun ọpọ eeyan, ni ọrọ nipa okoowo laaarin awọn alagbara aye meji naa.
Trump ti sọ pe oun yoo ni ki Xi ṣi ọrọ aje China silẹ fawọn ileeṣẹ ẹlẹrọ nla nla.
O si tun ni oun lero pe awọn yoo sọrọ to pọ nipa Iran, bo tilẹ jẹ pe o loun ko nilo iranlọwọ China lati pari ogun naa.
Trump sọ pe Aarẹ Xi ti huwa ọmọluabi debi kan lori ogun Iran yii.
O fi kun un pe irinajo China yii yoo wuyi pupọ, bẹẹ ni ọpọ nnkan daadaa ni yoo ti ara rẹ jade.
Ni ti aarẹ Xi, ireti wa pe yoo ṣipẹ pe ki America yee ta nnkan ogun silẹẹ Taiwan.
Yoo si tun pe fun afikun igba lori adehun okoowo onigbedeke ti wọn ṣe loṣu Kẹwaa, eyi to da owo ori ọja gọbọi sisan duro laaarin America ati China.
Bakan naa ni ohun to kari ẹka iroyin ni China bayii pe Beijing n wa ọjọ iwaju to daa ju tasiko yii lọ lọdọ America.
Wọn si n fẹ ajọṣe ti yoo mu ẹsẹ wọn duro lai bẹru, bi gbogbo aye tilẹ n mi logbo-logbo.
Ki ni yoo ṣẹlẹ lasiko irinajo yii?
Irọlẹ Ọjọruu ni Trump balẹ si Beijing, ki ojulowo irinajo rẹ gan-an too bẹrẹ l'Ọjọbọ.
Ireti wa pe Aarẹ America yoo wa nibi eto ikini kaabọ ti Aarẹ Xi yoo ti gba a lalejo, ni gbọngan nla, ki wọn too jọ bẹrẹ ajọsọ .
Awẹjẹ-wẹmu yoo si waye lọwọ alẹ ọjọ naa.
Ọjọ Ẹti ni Trump yoo ṣabẹwo si Zhongnanhai, ibudo agbara ti awọn olori China n gbe ti wọn si ti n ṣiṣẹ.
Yoo ya fọto ọlọrẹsọrẹẹ pẹlu Xi, yoo si bọ ọ lọwọ pẹlu.
Lẹyin eyi ni ipade ajọsọ mi-in yoo tun waye pẹlu Xi, wọn yoo jẹun ọsan bi wọn ṣe n ṣepade.
Lẹyin naa ni Trump yoo pada si papakọ ofurufu fun ayẹyẹ ipada si America rẹ.
Nibo lọrọ de duro lori owo ori ọja sisan?
Ija agba meji nipa okoowo wa laarin awọn alagbara aye mejeeji yii.
Ṣugbọn awọn mejeeji ni afojusun wa pe wọn yoo tun jọ tun ọrọ naa sọ bayii, bi ko tiẹ ni I yanju tan raurau.
Ireti wa pe Trump yoo sọ fun wọn ni China pe ki wọn maa ra ọja lọdọ awon ileeṣẹ nla nla l'America, titi kan ẹwa soya ati awon nnkan elo ara ọkọ ofurufu.
Beijing funra rẹ to tan, o ni akọsilẹ olokoowo to n fi ọja ranṣẹ sawọn orilẹede mi-in, amọ o ṣi nilo ọja America fawọn nnkan elo ti araalu n ra.
Bakan naa ni oye foju han, pe Aarẹ China naa yoo ni ki America fagile ikede rẹ to ṣe laipẹ, pe oun yoo wadii awọn ilana okoowo ti ko tọ ni China.
Ohun miran ti wọn a tun gbe yẹwo
Lọsẹ to kọja ni Akọwe ijọba America; Marco Rubio, ṣo pe ọrọ nipa Taiwan yoo wa lara ohun ti wọn yoo sọ nibi ipade yii.
O ni o yẹ bẹẹ, ki ọrọ naa ma lọ di ohun ti yoo fa wahala laaarin America ati China.
Bakan naa ni China pẹlu ti fi han pe dandan ni ọrọ Taiwan yii ninu ipade.
Laaarọ Ọjọru, awọn alaṣẹ China sọ ọ di mimọ pe awọn ko faramọ ajọṣepọ ologun America to n ta nnkan ija fun Taiwan.
Bi Trump ṣe n sọ pe oun ko nilo iranlọwọ China lati fopin si ogun Iran to, ireti wa pe yoo rọ Beijing lati ba Tehran sọrọ, ki wọn le jọ fẹnuko sibi kan.
China ṣetan lati fopin si ogun ni tirẹ, o si n gbiyanju labẹnu lati jẹ ki alaafia wa, gẹgẹ bi akọroyin BBC ni China, Laura Bicker, ṣe jabọ.
O ni eyi ri bẹẹ nitori ija yii n ko ba ọrọ aje China.