Mo ti fẹ́ obìnrin rí lágbo tíátà àmọ́ kò ní àṣeyọrí, owó, obìnrin àti agbára ló ń fa gbajúmọ̀ ọkùnrin ṣubú - Abayomi Alvin

Mo ti fẹ́ obìnrin rí lágbo tíátà àmọ́ kò ní àṣeyọrí, owó, obìnrin àti agbára ló ń fa gbajúmọ̀ ọkùnrin ṣubú - Abayomi Alvin
Published

Ọkan lara awọn odu, ti kii se aimọ fawọn oloko lagbo tiata ni Abayomi Alvin tii se gbajugbaja osere.

Osi ti kopa ninu ọpọ ere sinima eyi to jẹ ko di gbaujmọ laarin awọn osere tiata amọ inu ere sinima Jenifa Diary ti Funke Akinsele se, lo ti di ilumọọka.

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Abayomi Alvin ni oun kii gbe nilu Eko lasiko ti oun n se ere Jenifa Diary, Ibadan ni oun n gbe.

"Ọdọ ọrẹbinrin mi ni mo wa nigba yẹn fun bi ọjọ mẹta lẹyin ifọrọwanilẹnuwo, mo n duro pe wọn maa pe mi nigba yẹn.

Amọ fun odidi ọjọ mẹta, wọn ko pe mi, ọjọ kẹrin ni mo pinnu pe mo n pada lọ si Ibadan ti mo ti wa.

Sugbọn bi mo se dele ni bii aago mẹjọ alẹ nilu Ibadan, bi wọn se pe mi niyẹn."

"Imọran ti iya mi gba mi, nigba ti mo n dagba ni pe, ki n sọra fun obinrin tori bi eeyan ko ba sọra, wọn maa wa eeyan ri"

Nigba to n sọrọ lori awọn ohun to le fa isubu osere ọkunrin, Abayomi Alvin salaye owo, agbara ati obinrin lo le fa awọn ọkunrin silẹ lagbo amuludun.

"Ti a ba wo itan igbe aye awọn alagbara aye, awọn to gbajumọ, awọn to wa loke tẹlẹ amọ ti wọn ti ja walẹ.

Lara awọn nnkan to n fa isubu wọn ni boya owo tabi obinrin lo fa wọn walẹ.

Imọran ti iya mi si gba mi nigba ti mo n dagba ni pe ki n sọra fun obinrin tori bi eeyan ko ba sọra, wọn wa wa eeyan ri.

Paapaa ọkunrin to rẹwa, to ni okiki, to si tun ni owo diẹ lọwọ, obinrin maa wa kan.

Tori naa lo se yẹ ki ọkunrin sọra, mo si maa n mu imọran iya mi naa ni ọkunkundun."

"Mo ba ọkan lara awọn akẹẹgbẹ mi lagbo tiata jade ri, amọ igbẹyin rẹ ko dara, o si dun mi gan"

Bakan naa, a bi Abayomi Alvin ni ibeere pe se o le fẹ akẹẹgbẹ obinrin lagbo tiata ni iyawo amọ o dahun pe oun ti se bẹẹ ri.

"Mo ba ọkan lara awọn akẹẹgbẹ mi lagbo tiata jade ri, amọ igbẹyin rẹ ko dara, o si dun mi gan.

Mo maa wo nibi isẹ pẹlu obinrin naa nigba miran, a ko ni le sọrọ sira wa, titi di oni, a kii sọrọ sira wa.

Ti a ba wo awọn itan ti mo ti gbọ ati eyi to sẹlẹ si mi, kii saba wọpọ fun awọn osere meji, awọn to dijọ jẹ gbajumọ lati fẹra, ko si yọri si rere.

Osere le ba onkọtan tabi adari ere jade, iyẹn yatọ, amọ ki osere ọkunrin ati obinrin meji dijọ maa jade, ki wọn si pada fẹra sile, wọn ko pọ lọ titi.

A tiẹ ri awọn miran ni ayika wa ti igbeyawo wọn ti daru."

"Ori ayelujara ni emi ati Olo mi ti n kọkọ sọrọ, amọ a ri pe ero ati ise wa papọ, a si bẹrẹ si dan ibasepọ ọna jinjin wo"

Abayomi Alvin wa sọ fun BBC News Yoruba pe oke okun ni aya oun wa.

"Idi ti mo se yan lati maa ni ibasepọ loke rere, loke okun kii se ohun ti mo pinnu tabi ro ninu ọkan mi.

Ero ọpọ awọn obinrin ti mo n ba pade ni Naijiria ko papọ mọ ero temi, n ko ri ara mi ninu ero wọn.

Ori ayelujara ni emi ati Olo mi ti n kọkọ sọrọ, amọ a ri pe ero ati ise wa papọ, a si bẹrẹ si dan ibasepọ lọna jinjin wo."

Ta ni Abayomi Alvin?

Ogunjọ osu kẹfa ọdun 1993 ni Towase Abayomi Alvin dele aye, ilu Eko si ni wọn bi si.

Amọ o gbe ilu Ibadan si saa kan, ko to bẹrẹ isẹ tiata.

Abayomi ti se ọpọlọpọ ere to jẹ gbajugbaja, to si tun ti gba ọpọ ami ẹyẹ.

Lara awọn sinima to ti kopa ninu rẹ ni Kasala, Mummy ati war, Loud, A Naija Christmas, Collateral war ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Abayomei Alvin ti gba oniruuru ami ẹyẹ bii osere to dantọ lọdun 2017, ami ẹyẹ gbajumọ osere ati ami ẹyẹ fun osere to sẹsẹ n dide lẹ.