Shina Peller, ọmọ ilẹ àṣofin márùn ún míì kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Wahala to de ba ẹgbẹ oṣelu PDP ko tii dopin pẹlu bi awọn eekan ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa nipinlẹ Oyo ṣe n kọwe fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ bayii.

‎Ohun ti ọpọ awọn to ti kọwe fipo silẹ sọ ni wi pe ija to wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP yoo ṣe idiwo fun awọn ninu eyo idibo to n bọ.

‎Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP mẹta lati ipinlẹ Oyo ti wọn tun jẹ ọmọ ile igbimo aṣojuṣofin ẹgbẹ oṣelu naa loti kọwe lati fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ bayii.

‎Awọn mẹtẹẹta ni Najimdeen Oyedeji, to n ṣoju fun agbegbe Iseyin/Itesiwaju/Kajola/Iwajowa; Adedeji Olajide ati Abass Adigun to ti fi ẹgbẹ na silẹ patapata.

‎Iroyin tun sọ pe Anthony Adepoju to n ṣoju agbegbe Ibarapa ati Ojo Makanjuola to n ṣoju agbegbe Ogo-Oluwa/Surulere ti wọn ni ija to wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lọ fa a ti awọn fi yẹba fun ẹgbẹ ọhun bayii.

‎ ‎Ki ni ohun ti a ri gbọ ṣaaju?

‎Lọjọru ni gomina Seyi Makinde ṣe ipade idakọnkọ nile rẹ pẹlu awọn aṣaaju ati awọn to ṣe pataki ninu ẹgbẹ oṣelu Allied Peoples Movement (APM), ti wọn wa lati ilu Abuja.

Awọn oloṣelu ipinlẹ Oyo si n sọ wi pe igbesẹ lati fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ ni wọn wa n yanju nibi ipade naa.

Ipade ọhun to waye ni Ibadan, jẹ apakan lara awọn atunto to n lọ lọwọ laarin awọn oloselu ṣaaju eto idibo apapọ ti ọdun 2027.

‎Ti ẹ ko ba gbagbe, gomina ipinlẹ Bauchi Bala Muhammad ti ṣaaju fi ẹgbẹ oṣelu PDP naa sile to si ku gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ nikan ṣoṣo ninu ẹgbẹ oṣelu naa.

‎Amọ ṣa, ọpọ ninu awọn to fẹ dije dupo ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lo ti kọwe fi ẹgbẹ naa silẹ ti wọn si ti lọ sinu ẹgbẹ oṣelu APM, ninu wọn ni, Shina Peller, Olufemi Ajadi, Akeem Olatunji, aṣoju ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọ julọ nile igbimo aṣofin ipinlẹ Oyo, Sanjo Ọnaolapo naa wa lara wọn.

‎Ọjọ kẹwaa, oṣu Karun un, ọdun 2026 yii ni fifi orukọ awọn oludije fun eto idibo ọdun 2027 gẹgẹ bii ajọ INEC ti fi lelẹ yoo dopin.

‎Kinni ohun to ṣẹṣẹ ko sẹlẹ nipinlẹ Oyo?

‎Pẹlu bi awọn kọọkan ninu ile aṣofin ipinlẹ Oyo ṣe n kọwe fipo silẹ, o ṣeeṣe ki awọn to ku to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP naa lọ sinu ẹgbẹ oṣelu APM, iyẹn gẹgẹ bii awọn onimọ nipa eto oṣelu ipinlẹ Oyo ṣe sọ.