You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìdí rèé tí mo fi pinnu láti má lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́ - Funke Akindele
Gbajugbaja oṣere ori itage, Funke Akindele, ti ṣalaye idi to fi pinnu lati ma lọ si ile ijọsin mọ.
Akindele sọrọ yii ninu fidio kan eyi to fi lede lori Snapchat lasiko to n se ounjẹ fawọn ọmọ rẹ.
Gbajumọ oṣere naa sọ pe oun pinnu lati ma lọ si ṣọọṣi mọ nitori oun ni ọpọ olujọsin maa n wo.
O ni eyi kii sii jẹ koun le fọkan ba isin lọ nigba kugba toun ba ti wa ni ṣọọṣi.
Akindele wa fidi rẹ mulẹ pe oun fẹ lati maa ṣe ijọsin bayii lori itakun ayelujara.
''Sise ounjẹ fawọn ọmọ ati gbigbe wọn lọ si ile ijọsin ko rọrun rara.
Ma tiẹ bi mi leere bo ya mo maa lọ ṣọọṣi, mi o lọ si ṣọọṣi.
Gbogbo igba ti mo ba ti wa nile ijọsin, emi nikan ni wọn maa n ya fọto mi.
Fun idi eyi, mo maa jọsin lori itakun ayelujara bayii
Ẹgbọn mi ni Pasuma jẹ, ẹ ye gbe iroyin ofege kiri - Funke Akindele
Ti ẹ o ba gbagbe, laipẹ yii lawọn eeyan kan fẹsun kan an wi pe o foju pa gbajumọ akọrin Fuji, Alhaji Wasiu Alabi Pasuma, rẹ lode ti wọn ti pade.
Fidio kan lo ṣafihan bi Pasuma ṣe fẹ ki Akindele nigba to n ba ẹnikan sọrọ lode.
Fọnran naa tun ṣafihan bi Funke Akindele ṣe tẹsiwaju pẹlu ẹni to n ba sọrọ ti Pasuma si pada sori ijokoo.
Eyi gan an lo jẹ ki ọpọ maa sọ pe o foju pa gbajugbaja akọrin Fuji naa rẹ.
Amọ, Akindele ti sọ pe ahesọ ọrọ lasan an lawọn eeyan kan n gbe kiri, o ni ọrọ ko ri bẹẹ rara.
Akindele sọ pe oun ki Pasuma lode ti awọn ti pade, koda, oun tun jo loju agbo pẹlu olorin naa.
''Foju pa Alhaji Pasuma rẹ kẹ? Rara o! Ẹ ye gbe iroyin buruku kiri.
Mo ri Pasuma, mo si ki i, a tun jọ jo papọ.
Ẹgbọn mi ni Pasuma jẹ, ẹ ye gbe iroyin ofege kiri,'' Akindele ṣalaye