You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
"Ọlọ́pàá Kwara ti ọmọ mi obìnrin ọmọ ọdún 16 mọ́lé láìṣẹ̀, wọ́n ni ó gbọdọ̀ ṣẹ̀wọ̀n"
Obinrin kan niluu Arandun, nipinlẹ Kwara ti ke gbajare sawọn ọmọ Naijiria fun iranlọwọ lẹyin to fẹsun kan awọn ọlọpaa pe wọn ti ọmọ oun obinrin to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun mọle fun odidi ọjọ mẹta gbako.
Ninu fidio kan to n mi igboro titi loju opo X ni obinrin naa ti fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara pe wọn mu ọmọ naa dipo ẹgbọn rẹ ti wọn fẹsun ole jija kan lẹyin ti ẹgbọn rẹ to jẹ afurasi na papa bora.
Inu fidio ọhun ni a ti ri bi awọn mọlẹbi ọmọdebinrin naa ṣe n pariwo lagọ ọlọpaa pe ko tọ ki wọn ti ọmọ kekere mọle.
Iya ọmọ naa sọ pe "Ẹ kaarọ ọmọ Naijiria, ẹ ṣaanu mi, ọmọ ni kan lo ṣe aṣemaṣe. A si ti wa wa wa, a o ri.
"Awọn ọlọpaa wa gbe mi, wọn ti mi mọle, mo lo ọjọ mẹta nibẹ, wọn si gba owo beeloi lọwọ mi. Wọn da mi silẹ. Bi ọsẹ kan rẹ, wọn tun pada wa, wọn wa mu ọmọ ọdun mẹrindinlogun... ọmọ obinrin... lati ijẹta."
Iya ọmọ naa ṣalaye pe ọlọpaa dunkoko mọ oun pe wọn ko ni tu ọmọ naa silẹ ayafi to ba ṣẹwọn.
Irọ ni wọn pa mọ wa, a ko ti ọmọde mọle lọna aitọ - Ọlọpaa
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti fesi so ọrọ naa pẹlu alaye pe irọ ni ẹsun ti mọlẹbi naa fi kan oun.
Ninu atẹjade ti agbẹsnusọ rẹ, SP Adetoun Ejire-Adeyemi fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Aje, o fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ọlọpaa mu ọmọde ọhun.
O ni "Nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ni wọn fi ẹsun fifọ ile sun ni agọ ọlọpaa to wa ni Arandun.
"Afurasi lori ọrọ naa ti ọlọpaa ti n wa, Timothy Aransiola, na papa bora lẹyin ti ọrọ ọhun to wa leti.
"A gbọ pe aburo rẹ, Esther Aransiola, obinrin ọmọ ọdun mẹrindinlogun n daabo afurasi naa lọwọ ọlọpaa. A mu ọmọdebinrin naa si atimọle lọjọ kinni, oṣu Karun un, ọdun 2026 fun ẹsun pe o n daabo bo afurasi lọna ati mọọmọ di iṣẹ ọlọpaa lọwọ."
Ọlọpaa ni ṣe lawọn ba ọmọde naa wi, wọn gba ọrọ ẹnu rẹ silẹ ti wọn si fun ni beeli ko maa lọ sile.
O ni awọn ko tii mọle lọna ti ko ba ofin mu gẹgẹ bi fidio ori ayelujara ṣe ṣagbekalẹ.
Lẹyin naa lo ni ki awọn araalu maṣe naani fidio ti awọn obi ọmọ naa ṣe, eyii to n milẹ titi lori ayelujara.