You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Èmi ò sọ̀rọ̀ tàbùkù Olubadan o, ọmọ ni mo jẹ́ sí Ọba Rashidi Ladọja - Bayọ Adelabu sọ̀rọ̀ síta lẹ́yìn tí wọ́n ní ó sọ̀kò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ s'Olubadan nítorí òṣèlú
Lopin ọsẹ to kọja ni iroyin kan pe minisita fun ọrọ ina mọnamọna ati ohun amuṣagbara tẹlẹ, Adebayọ Adelabu ti bu ẹnu abuku lu olubadan ti ilu Ibadan.
Iroyin naa sọ pe nibi ipade ọrọ oṣelu kan bayii to waye lagbegbe ijọba ibilẹ ila oorun Gusu Ibadan ni wọn ni Adelabu ti sọ fun awọn to wa nibẹ pe Olubadan Ilu Ibadan Ọba Rashidi Ladọja, to figbakan ri jẹ gomina ipinlẹ Ọyọ lo wa nidi bi ẹgbẹ oṣelu APC ṣe kuna lati bori lasiko idibo gomina to waye lọdun 2019
Ọrọ yii ti fa ọpọlọpọ ifanfa eleyii to ti n mu ki ọpọlọpọ awọn eekan ilẹ Ibadan o maa fiohun ranṣẹ si minisita tẹlẹ naa pe ọrọ abuku si Olubadan ju ẹnu rẹ lọ.
Bawo lọrọ ti Adelabu sọ gan ṣe jẹ?
Ọrọ nipa ẹni ti yoo ṣoju fun ẹgbẹ oṣelu APC lasiko ibo gomina to n bọ lọdun 2027 ti n gbena soju diẹdiẹ bayii pẹlu bi gbogbo awọ̀n oludije ṣe n gbiyanjulati ṣẹ ki oun wa lọkan araalu gẹgẹbi ẹni to yẹ. Eyi si ti wa n fa ọpọlọpọ gbungbungbun ati ifanfa lagbo oṣelu ẹgbẹ oṣelu naa ati ipinlẹ Ọyọ lapapọ.
Iroyin to jade nibi ipade oṣelu ti Adelabu ti sọrọ naa ni wi pe o fi ẹna sọko ọrọ si Olubadan ti ilu Ibadan, Ọba Rashidi Ladọja pẹlu ọrọ to sọ naa. Ohun ti ọpọ n sọ ni pe Ọba Ladọja wa lara awọn igi lẹyin ọgba fun Sharafadeen Alli ti oun pẹlu n fẹ dije fun aṣia ẹgbẹ oṣelu APC lati ṣoju rẹ ninu ibo gomina ipinlẹ naa to n bọ.
"A o ni gba ki ẹnikẹni fi tipa yan oludije le wa lori."
Adelabu ni ilana tiwantiwa lẹgbẹ oṣelu naa nilo lati le kogoja ninu awọn eto idibo gbogbo to n bọ lọna.
Ki ni Adelabu sọ si ina to n jo latari ọrọ to sọ?
Lẹyin ti ọrọ naa ti wa di eyi ti awọn eeyan n gba bi ẹni gba igba ọti, paapaa awọn eekan ilu Ibadan ati ipinlẹ Ọyọ, Oloye Adebayọ Adelabu ti wa ṣalaye pe, oun o jẹ́ tabuku Olubadan, bi o ti wulẹ o mọ.
Adelabu ni irọ to jina si otitọ ni ohun tawọn eeyan nsọ lori rẹ. O ni ara ọna lati pagidina igbesẹ oṣelu oun ni.
"Bii baba ni Olubadan jẹ si mi, ko si si aidọgba kankan nipa oṣelu to le ba okun ajọṣepọ naa jẹ. Lootọ iha oṣelu ti a fi si le ṣe ọtọọtọ ṣugbọn eyi ko fi igba kọọkan da omi alaafia ajọṣepọ aarin wa ru rara."