You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn ajínigbé tún jí òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ iná mọ̀nàmọ́ná IBEDC gbé, àwọn aláṣẹ ké gbàjarè síta
Awọn agbebọn ti ji awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ mọnamọna Ibadan Electricity Distribution Company, IBEDCmeji gbe ti ko si ti si ẹni mọ ibi ti awọn oṣiṣẹ meji naa wa bayii.
Atẹjade kan ti ileeṣẹ ina mọnamọna naa fi sita lọjọ Aje ṣalaye pe Ọjọru ọsẹ to kọja tii ṣe ọjọ kọkandinlọgbọ̀n oṣu kẹrin ni wọn ji awọn oṣiṣẹ rẹ meji ọhun gbe.
"Iṣẹlẹ yii mu ọkan wa gbọgbẹ pupọ, ọkan wa si wa pẹlu awọn akẹgbẹ wa naa atawọn mọlẹbi wọn lasiko ipenija nla yii."
Iroyin sọ pe ẹkun ileeṣẹ mọnamọna IBEDC ni ipinlẹ Ogun lawọn oṣiṣẹ mejeeji yii ti n ṣiṣẹ ki wọn to ko sọwọ awọn afurasi ajinigbe naa.
Bakan naa la tun gbọ pe agbegbe ilu Ṣagamu ni wọn ti ji awọn mejeeji yii gbe ti iroyin si tun fihan pe awọn ajinigbe naa ti n beere fun owo itusilẹ to gọbi bayii.
Awọn alaṣẹ ileeṣẹ Mọnamọna IBEDC ṣalaye ninu atẹjade naa pe awọn ti n ba awọn agbofinro atawọn ajọ alaabo gbogbo lati le gba awn meji ti wọn ji gbe naa pada.
Amọṣa wọn ni awọn ko ni le sọ ọrọ pupọ lori iṣẹlẹ naa nitori ẹlẹgẹ to jẹ nitori abo awọn eeyan naa.
Ọgbọn miliọnu lawọn ajinigbe naa n beere, araalu kan sọrọ loju opo ayelujara
Atẹjade kan ti arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Awolesi Oluwadamilare Adedayo fi sita loju opo Facebook rẹ ṣalaye pe ọgbọ̀n miliọnu Naira lawọn ajinigbe naa n beere lori ọkọọkan awọn oṣiṣẹ IBEDC ti wọ̀n ji gbe naa.
"Ohun ti a n panupọ beere fun bayii ni:
Itusilẹ awọn oṣiṣẹ IBEDC mejeeji yii
Didena atunṣẹ iṣẹlẹ yii lọjọ iwaju nipasẹ ajọṣepọ awọn ileeṣẹ alaabo gbogbo."