You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo kókó ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour tí wọn fi ní kí Olóòtú Ìjọba UK kọ̀wé fipò sílẹ̀
Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Sir Keir Starmer, si duro lori ẹsẹ rẹ wi pe oun ko ni kọwe fipo silẹ lẹyin tawọn alatako rẹ ti pe fun ikọwefiposilẹ rẹ.
Awọn oṣiṣẹ ijọba rẹ mẹrin to fi mọ minisita to n ri si ọrọ abẹle, Jess Phillips lo ti kọwe fipo silẹ.
Ọpọ aṣofin to wa ninu ẹgbẹ Labour kan naa pẹlu Starmer lo ti n pe fun ikọwefiposilẹ Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi lẹyin ti ẹgbẹ naa fidirẹmi ninu eto idibo ẹsẹ kuuku to waye lọsẹ to kọja.
Wọnyii ni koko nnkan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ Labour:
Akọwe ijọba to n ri si ọrọ abẹnu, Shabana Mahmood, wa lara awọn minisita to ti kepe Olootu ijọba lati mu ọjọ ti yoo fipo silẹ.
Amọ, Sir Keir sọ ninu ipade to ṣe pẹlu igbimọ alaṣẹ ijọba lanaa ọjọ Iṣẹgun wi pe oun ko ni kọwe fipo silẹ.
Ko tii si aṣofin to ti tẹle ilana ile lati kepe Sir Keir wi pe ko kọwe fipo silẹ, igbesẹ yii nilo ki aṣofin mọkanlelọgọrin gba a wọle tabi ki ida 20% awọn aṣofin ẹgbẹ Labour gba a wọle.
Lẹyin ipade ọjọ Iṣẹgun ni Akọwe ilegbee, Steve Reed ati akọwe ijọba fun ọrọ iṣẹ ati owo ifẹyinti, Pat McFadden, sọ pe awọn si wa lẹyin Olootu Ijọba.
Amọ, akọwe ijọba to n ri si eto ilera, Wes Streeting, ti awọn eeyan n wo gẹgẹ bi alatko Keir ko sọ nnkankan fawọn akọroyin.
Streeting yoo ṣepade pọ pẹlu Starmer lonii Ọjọru ọjọ kẹtala oṣu Karun un yii.
Awọn alatilẹyin Starmer ni igbagbọ pe Streeting ko le ri aṣofin mọkanlelọgọrin lati ti i lẹyin lori ati yọ Olootu Ijọba nipo.
Minisita to n ri sọrọ ilẹ okeere, Jenny Chapman, toun naa wa lara awọn alatilẹyin Starmer sọ pe ijirpro si n lọ lọwọ lori eto iṣejọba Starmar, ṣugbọn o fidi rẹ mulẹ pe ko si minisita to tii sọ pe oun fẹ gba ipo rẹ.
Ẹwẹ, lonii ni Ọba Charles Kẹta yoo kede eto ijọba fun ọdun tuntun.
Ki lo n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ Labour lọwọ yii?
O le ni ọgọrin awọn aṣofin ti wọn ti kepe Starmer ni gbangba lati kọwe fipo silẹ tabi ko ṣeto asiko ti yoo kuro nipo Olootu ijọba.
Minisita mẹrin ọtọọtọ, Jess Phillips, Zubir Ahmed, Alex Davies-Jones ati Miatta Fahnbulleh – lo ti kọwe fipo silẹ.
Awọn amugbalẹgbẹ minisita mẹfa ti wọn fipo wọn silẹ lọjọ Aje ni ijọba ti rọpa wọn bayii.
BBC gbọ pe awọn mii naa yoo tun kọwe fipo silẹ.
A gbọ pe o le ni ọgọrun un aṣofin ẹgbẹ Labour to fenu ko pe ko tii to akoko lati paarọ adari.
Streeting ati igbakeji Olootu Ijọba tẹlẹ, Angela Rayner, ni ọpọ gbagbọ pe wọn le fẹ gba ipo Starmer.
Ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin
Olootu Ijọba sọrọ apilẹkọ lọjọ Aje lati kede pe mimi kan ko le mi oun
Amọ, lẹyin wakati diẹ lawọn aṣofin kan bẹrẹ sii kepe e wi pe ko kọwe fipo silẹ.
Igbesẹ yii ko ṣẹyin bi awọn kansilọ ẹgbẹ Labour ti ko din 1,500 ṣe fidirẹmi ninu eto ijọba ibilẹ to waye lọsẹ to kọja.
Bakan naa tun ni Labour tun fidirẹmi ni Wales ati ninu eto idibo ile aṣofin Scotland pẹlu.
Eto idibo yii ni ọpọ n wo gẹgẹ bi nnkan ti yoo sọ bo ya Starmer yoo tẹsiwaju lati maa dipo rẹ mu.
Bakan naa tun ni ọpọ aṣofin ti koro oju si bi Starmer ṣe yan Peter Mandelson gẹgẹ bi aṣoju ijọba UK si orilẹede Amẹrika.
Starmer yoo ṣepade pẹlu Streeting, alatako rẹ ninu ẹgbẹ Labour
Olootu ijọba Sir Keir Starmer yoo ṣepade pẹlu akọwe ijọba fun eto ilera, Wes Streeting, lonii lori awuyewuye to n lọ ninu ẹgbẹ Labour eyi to mu kawọn ọmọ ẹgbẹ kan pe fun ikọwefiposilẹ Starmer.
Ipade yii n waye lẹyin ti minisita mẹrin to fi mó Jess Phillips ti kówe fipo silẹ.
Ko din ni ọgọrin aṣofin lati inu ẹgbẹ Labour to ti kepe Starmer pe ko kọwe fipo silẹ.
Sir Keir sọ lanaa wi pe oun ko ni kọwe fipo silẹ, awọn aṣofin to le lógọru un si ti fi atilẹyin wọn han fun Olootu Ijọba.
Amọ, agbara Olooto Ijọba ti dinku lẹyin ti ẹgbẹ Labour fidirẹmi ninu eto idibo ijọba ibilẹ ọsẹ to kọja.
Ikọwefiposilẹ yii waye ṣaaju asiko ti Ọba Charlsea Kẹta yoo kede eto ijọba fun araalu.
Streeting yoo ṣepade pọ pẹlu Starmer ṣaaju ọrọ ti Ọba Charles yoo sọ eyi ti yoo ṣami ibẹrẹ ijokoo ile fun saa tuntun.
Eto idibo adari le waye ti Olootu Ijọba ba kọwe fipo silẹ, tabi tawọn aṣofin ẹgbẹ Labour ba panupọ pe ki adari ẹgbẹ kuro nipo fun ẹlomiran.