You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀pọ̀ èrò n‘Ibadan fẹ̀sùn ajínigbé kan Dókítà kan, wọ́n fẹ́ lú ú pa, dáná sun ọkọ̀ rẹ̀, ọ̀pẹ́ ọlọ́pàá tó dé sásìkò
Ori ko dokita oniṣegun oyinbo kan yọ lọwọ iku ojiji lẹyin tawọn ọlọpaa doola rẹ lọwọ ọpọ ero ti wọn fẹ lu u pa lagbegbe Ologuneru n'Ibadan lori ẹsun pe o ji ọdọbinrin meji gbe.
Dokita naa, ti a gbọ gbe o wale lati Amẹrika, lawọn eeyan kan sọ fun ileeṣẹ ọlọpaa to wa lagbegbe Eleyele wi pe, awọn eeyan kan ti fẹ dana sun un lagbegbe Ologuneru.
Bayii lawọn ọlọpaa sare lọ si agbegbe naac, ti wọn si doola ọkunrin ọhun lọwọ awọn to fẹ lu u pa.
Amọ, kawọn ọlọpaa to de, awọn eeyan ti dana sun ọkọ Lexus 330 SUV to jẹ ti ọkunrin naa.
Ailesọ ede Yoruba ati ede Oyinbo daadaa awọn ọmọbinrin mejeeji tun jẹ ki ọpọ maa fura si ọkunrin naa wi pe o ṣee ko jẹ ajinigbe
Ileeṣẹ ọlọpaa tun ko ọdọbinrin Deborah ọmọ ọdun mẹẹdogun ati Rebecca ẹni ọdun mejila to wa ninu ọkọ naa lọ si agọ ọlọpaa pẹlu ọkunrin naa fun iwadii kikun.
Iwadii ti fi han pe ọkunrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Dokita Afolabi jẹ dokita oniṣegun oyinbo lorilẹede Amẹrika.
Iwadii naa fi han pe, kii se ajinigbe gẹgẹ bi awọn kan ṣe n sọ kaakiri ori itakun ayelujara.
Bakan naa ni iwadii tun fidi rẹ mulẹ pe lati ọwọ Arabinrin kan to n jẹ Idowu Abimbola, to n gbe lagbegbe Eleyele lawọn ọdọbinrin meji naa ti tẹle ọkunrin yii lati ṣeranwọ fun un pẹlu iṣẹ ile.
Arabinrin Abimbola ni a gbọ pe, o fidi ọrọ naa mulẹ fawọn ọlọpaa ninu iṣẹ iwadii wọn.
Awọn ọdọbinrin meji naa jẹẹri si ọrọ ti Arabinrin Abimbola sọ fawọn ọlọpaa.
Ohun ti a gbọ ni pe ede-ai-yede bẹ silẹ nigba ti ọkunrin naa fẹ wọ inu ile ẹkọ giga Poly Ibadan nibi tawọn ẹṣọ eleto aabo da a duro fun ayẹwo.
Amọ, bi awọn ọdọbinrin meji to wa ninu ọkọ naa ṣe wa, eyi ti wọn ni ṣe lo dabi ẹni pe ihoho ni wọn wa pẹlu iru aṣọ ti wọn wọ lo jẹ kawọn eeyan fura si ọkunrin naa.
Bi ọkunrin naa ko ṣe le dahun awọn ibeere ti wọn bi i daadaa ati bi o ṣe lọri ọkọ pada lo jẹ ki ọpọ eeyan tun fura si i.
Ailesọ ede Yoruba ati ede Oyinbo daadaa awọn ọmọbinrin mejeeji tun jẹ ki ọpọ maa fura si ọkunrin naa wi pe o ṣee ko jẹ ajinigbe.
Eyi gan an lo jẹ kawọn eeyan kan le e, ti wọn si bẹrẹ sii ni lu u kawọn ọlọpaa to doola rẹ.
Wọn ni lati gbe ọkunrin naa lọ si ile iwosan fun itọju lẹyin tawọn ọlọpaa doola rẹ tan.
Ileeṣẹ ọlọpaa n wa gbogbo eeyan to lu dokita oniṣegun oyinbo n'Ibadan, ti wọn tun dana sun ọkọ rẹ
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti kede pe awọn n wa gbogbo eeyan to dawọ jọ lu dokita oniṣegun oyinbo to wa lati Amẹrika lagbegbe Ologoeru n'Ibadan lori ẹsun pe o ji eeyan meji gbe.
Nibi iṣẹlẹ ọhun to waye lọjọ Aje ọsẹ yii ni ọpọ ero tun ti dana sun ọkọ Lexus RX 330 SUV ọkunrin naa.
Awọn ọlọpaa to pada doola ọkunrin naa fidi rẹ mulẹ pe irọ nla lẹsun ijinigbe ti wọn fi kan ọkunrin to wale naa lati orilẹede Amẹrika.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe Arabinrin kan to n jẹ Idowu Abimbola lo ko awọn ọdọbinrin meji to wa ninu ọkọ Dokita Afolabi fun un wi pe ki wọn lọ ṣeranwọ fun un nile.
Obinrin naa si jẹẹri sọrọ ọhun lasiko tawọn ọlọpaa ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun un, awọn ọmọbinrin naa si jẹẹri si i pẹlu.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni nigba ti ọkunrin naa lọri ọkọ rẹ lati kuro lọdọ awọn ẹṣọ eleto aabo ni geeti Poly Ibadan, lawọn eeyan bẹrẹ sii fura si i.
Dokita Afolabi fara ṣeeṣe lẹyin ti eero to pejọ lu u kawọn ọlọpaa to doola rẹ.
Ọlọpaa bu ẹnu ẹtẹ lu bawọn eeyan ṣe lu Dokita Afolabi lori ẹsun ijinigbe
Ẹwẹ, Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, CP Abimbola Olugbenga, ti bu ẹnu ẹtẹ lu bawọn eeyan ṣe lu Dokita Afolabi lori ẹsun ijinigbe.
CP Olugbengba kilọ fawọn eeyan wi pe ki wọn yago fun ṣiṣe idajọ ọwọ ara ẹni.
O tun rọ araalu lati yago fun gbigbe iroyin ti wọn ko le fidi rẹ mulẹ kaakiri ori itakun ayelujara.
Kọmiṣọna ọlọpaa wa paṣẹ iwadii iṣẹlẹ naa, bakan naa ni o pe fun fifi ọwọ ṣinkun ofin mu gbogbo eeyan to lọwọ ninu lilu Dokita Afolabi atawọn to dana sun ọkọ rẹ.