Ẹgbẹ́ alákatakítí ISIS, Al Shabaab àti Al Qaeda tí a lé ní Iraq àti Syria, ti fi ìwọ̀ oòrùn Afrika ṣe ibùba – Ìjọba Amẹrika kìlọ̀

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ilẹ Amẹrika ti kede Naiijiria ati agbegbe Lake Chad Basin gẹgẹ bii ọkan lara awọn ibi ti yoo ti maa gbogun ti igbesunmọmi lọdun 2026, o tun juwe ilẹ Afrika gẹgẹ bii agbegbe ti aye ti gba agbesunmọmi lọwọ yii.

Ninu iwe kan to sọ nipa awọn ohun ti yoo ṣe lọdun yii lori eto abo, Amẹrika ni iwọ oorun Afrika, paapaa awọn ilẹ bii Lake Chad Basin, Mozambique, Sudan ati Somalia wa lara awọn ibi ti igbesunmọmi ti le kenka julọ.

Iwe ọhun ṣalaye pe awọn agbebọn Islamic State atawọn alakatakiti ẹsin mii ti korajọ si Afrika lati maa ṣọṣẹ latari eto abo to mẹhẹ nibẹ.

Iwe naa ni "Aarẹ Trump gbe ogun to lagbara julọ lagbaye ti awọn agbesunmọmi ni Iraq ati Syria, laarin ọsẹ diẹ lẹyin naa ni gbogbo wọn poora.

"Idi ree ti awọn kereje to ku lara awọn agbesunmọmi naa fi salọ si Afrika ati aringbungbun Asia lati lọ maa ṣọṣẹ nibẹ.

"Fun idi eyii, awọn agbegbe kan wa ni Afrika ti igbesunmọmi ti di ohun ti ko ṣe e fọwọrọ sẹyin.

"Lara awọn ibi ti wọn wa naa ni iwọ oorun Afrika, agbegba Sahel, Lake Chad Basin, Mozambique, Sudan, ati Somalia nibi ti awọn agbebọn ISIS ati Al Shabaab fi ṣe ibuba."

Ijọba Amẹrika sọ pe afojusun oun ni lati ri daju pe awọn agbesunmọmi to n ṣọṣẹ ni Afrika ko lagbara to lati ṣe ikọlu si oun tabi awọn ti oun ni ibaṣẹpọ pẹlu lati ilẹ Afrika.

O ni "A oo tẹsiwaju lati maa ṣiṣẹ pẹlu awọn ijọba ti awọn ọmọ ẹgbẹ ISIS ati al Qaeda n dunkoko mọ."

"A ko ni kọ awọn ọmọlẹyin Krisiti silẹ"

Iwe ijọba Amẹrika naa tun sọ siwaju si pe lara awọn nnkan ti awọn yoo gbajumọ ni ọna lati daabo bo awọn Kristẹni ti awọn alakatakiti ẹsin Islam n doju ija kọ.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, Washington yoo tẹsiwaju lati maa ṣe iranlọwọ to yẹ fun awọn ijọba ilẹ Afrika lati koju igbesunmọmi, bo tilẹ jẹ pe ko ni maa ja ija naa fun wọn.

Ẹwẹ, ijọba Trump tun bu ẹnu atẹ lu ijọba Aarẹ ana nibẹ, Joe Biden, pe aibikita rẹ lati pana igbesunmọmi lo ro awọn agbesunmọmi lagbara lati lọ korajọ si ilẹ Afrika.

O ni "Pẹlu igbesẹ ti Aarẹ Trump gbe ni Naijiria, eyii n ṣapẹrẹ pe yoo ṣoro lati maa pa awọn Kristẹni nibẹ lai jẹ iya to tọ."

Amẹrika ni oun ko ni maa fi ọmọ ogun ṣọwọ si Afrika bo tilẹ jẹ pe oun yoo tẹsiwaju ati maa ṣe awọn iranlọwọ mii lati ro eto abo rẹ lagbara.