Àwọn èèyàn fi àìrọ́mọbí bú mi lójú mi rí-Ooni Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, Ooni Ile ife
Tọ̀sán-tọ̀sán ni oju n pọn Aitalẹ, to ba di alẹ a di olounjẹ.
Ati pe to ba pẹ titi ti eeyan ti n da obi, to ba ya, obi yoo pada yan ni.
Eyi ni akawe to ba Ọọni Ile Ife; Ọba Enitan Adewoye Ogunwusi, mu, bi Kabiyesi naa ṣe ṣalaye ohun ti oju rẹ ti ri laye ri, ẹgan to ti fi ara gba ri ko too pada ja si ọpẹ ati ayọ lonii.
Lọjọ Abamẹta to kọja ni Ọọni Adeyeye ṣalaye itan aye rẹ, paapaa labala aitete di ọlọmọ lẹyin to gun ori itẹ, to bẹẹ to ni awọn kan tile fi aibimọ naa bu oun loju oun.
"Irinajo mi kun fun idojukọ ti mi o rokan, mi o rokan lati fẹ iyawo pupọ laye mi"
Atẹjade kan ti Akọwe iroyin Ọọni, Moses Olafare, fi sita lọjọ Abameta naa lo ṣalaye awọn nnkan to ti ṣẹlẹ si Ọọni Ogunwusi ri, to fi pada n kọrin idupẹ bayii.
Nibi ayẹyẹ ti awọn alabaaṣe ti waa ba Kabiyesi Adeyeye yọ n'Ile Ife, fun ti ibeji ti Yeyeluwa, Mariam Anako Ogunwusi bi ni Ọọni ti ṣalaye ọrọ pe:
"Mo dupẹ fun Ọlọrun fun ọjọ oni, ko sohun ti Ọlọrun ko le ṣe."
Gẹgẹ bi Kabiyesi Ogunwusi ṣe wi, o ni irinajo aye oun kun fun idojukọ ti oun ko rokan atawọn nnkan iyanu oriṣiriṣi.
Ọọni sọ pe ọmọ ọdun mọkandinlogun pere (19) ni oun wa nigba ti oun kọkọ di ọlọmọ laye.
O ni igbesẹ naa ka oun laya nigba naa, o si ju ọjọ ori oun lọ.
"Ọpẹlọpẹ iya mi to gba mi niyanju lati tẹsiwaju"
Kabiyesi tẹsiwaju ninu itan aye rẹ naa, pe ọpẹlọpẹ iya to bi oun lọmọ, to duro tan nigba naa to si gba oun niyanju lati ma ṣe rẹwẹsi, ṣugbọn ki oun tẹsiwaju ninu irinajo aye.
Ọọni sọ pe loun ba bẹrẹ si I ba a bọ bẹẹ, ṣugbọn oun ko ro o ri pe oun yoo pada ni iyawo pupọ laye oun.
Kabiyesi sọ pe lẹyin ti oun gun ori itẹ Oduduwa bii ọba tan, awọn ohun to n ṣẹlẹ ati awon ohun ti Iṣẹṣe beere fun, pa irinajo aye oun da labala ọrọ obinrin.
"Mo koju idojukọ gidi ni kete ti mo jọba tan, won n le mi lere pe ki n tete bẹrẹ iṣẹ igbeyawo ati ọmọ bibi."
Ọọni Ogunwusi sọ nipa bo ṣe bẹ iyawo rẹ igba naa lati ko ẹru wa si Ile Ifẹ lati maa ba ọba gbe.
O ni awon lọbaloba nla nla da si i ṣugbọn olori naa ko ko wa sile.
Eebu ati awọn ọrọ to n bani lọkan jẹ ni Ọọni sọ pe oun koju latọdọ awọn eeyan nigba naa, ti wọn n bu oun nipa ailobinrin ati aitete ri ọmọ bi.
Kabiyesi sọ pe niṣoju oun bayii ni awon eeyan kan ṣe fi airọmọbi laafin bu oun.
"Mo dupẹ lọwọ Olodumare, pe ọmọ ti pọ laafin wayi"
Amọ lasiko yii, Ọọni loun dupẹ lọwọ Olodumare, pe ọmọ ti sun oun bọ daadaa.
Kabiyesi ni oun dupẹ pe aafin ti kun fun awọn ọmọ lasiko yii, pẹlu afikun ibeji ọkunrin meji ti Olori Maryam ṣẹṣẹ bi si Canada.
Awọn Ẹdunjọbi to tun de yii ni Ọọni sọ pe wọn ti mu ẹnu to bu oun ri maa ki oun ku oriire ati ayọ ọmọ bayii.
Olori Maryam paapaa n fi ikini ati idupẹ ranṣẹ lati Canada ni Kabiyesi Ogunwusi wi, bi kaluku ṣe n ba Aafin Adimula Ile Ifẹ yọ ayọ ọmọ meji lẹẹkan ṣoṣo.


























