Ajínigbé fi ayédèrú iṣẹ́ tàn mi lọ sí Zamfara, wọ́n tún fowó ọkọ̀ ránṣẹ́ kí n lè tètè wá - Akẹ́kọ̀ọ́jáde Fásitì

John Arum Azi ti wọn fiṣẹ tan wọ akata ajinigbe, ori ikunlẹ lo wa ninu aworan yii.

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àkọlé àwòrán, John Arum Azi ti wọn fiṣẹ tan wọ akata ajinigbe ni Zamfara.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ọna ọfun ọna ọrun, ati pe iṣẹ aje ṣe koko lo mu ọmọkunrin kan, John Arum Azi, lugbadi ijinigbe, to si ṣe bẹẹ kuro ni Kaduna, to fi ẹsẹ ara rẹ rin wọ ibi ti wọn ti ji i gbe nipinlẹ Zamfara.

Ọna keyeefi ti eeyan ko le rokan rẹ ni awọn ajinigbe naa gba pitu ọwọ wọn fun Arum Azi to kẹkọọ gboye ni Yunifasiti Jos, ipinlẹ Plateau.

Wọn ni ko waa ba awọn ṣiṣẹ jorin-jorin ti a mọ si Wẹda ni wọn fi mu un sigbekun fọjọ mọkanla.

Bẹẹ, funra wọn ni wọn tun fowo ọkọ ranṣẹ si I ko too lọ ba wọn.

Bawo niṣẹlẹ yii ṣe ṣẹlẹ gan-an?

Gẹgẹ bi akẹkọọ gboye naa ṣe ṣalaye ohun to ṣẹlẹ si I lasiko to n jẹrii si agbara Oluwa ni ṣọọṣi kan to wa lagbegbe Tundun Wada, ni Jos lọjọ Aiku to kọja, o ni:

"Airiṣẹ ṣe ati bo ṣe ka mi lara to lati maa ribi iṣẹ kan lọ lo fa ohun to ṣẹlẹ si mi, lẹyin to ṣẹlẹ tan ni mo mọ pe ọdọ awọn ajinigbe ni mo waṣẹ lọ.

"Iṣẹlẹ yii bẹrẹ pẹlu awon eeyan oriṣiriṣi to n pe mi lori aago, ti wọn n ṣeleri iṣẹ fun mi, iyẹn iṣẹ jorinjorin.

"Wọn ṣaa n pe mi ni, wọn ni ki n wa ba awọn ṣiṣẹ. Koda, wọn fi owo ọkọ ranṣẹ si mi nibi to le de.

"Eyi lo jẹ ki n gbagbọ pe ojulowo iṣẹ to ba ofin mu ni wọn n pe mi fun."

O ni loun ba gbera lati Jos lọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin ọdun 2026, o di ilu Kaduna, lati ṣiṣẹ lọdọ awọn to ti n pe oun tipẹ naa.

Akẹkọọ gboye ti ko niṣẹ lọwọ naa tẹsiwaju pe nigba toun de Zaria, oun pe awọn to fẹ gba oun siṣẹ naa lori aago, wọn si ni koun gbe ọkada lọ si abule kan.

"Ara bẹrẹ si I fu mi, amọ mo tun n sọ lọkan mi pe o le jẹ awọn to maa ran mi lọwọ ree, nitori mo nilo iṣẹ gan-an. Mi o mọ pe ajinigbe ni wọn."

"Mo fẹsẹ ara mi rin wọ aarin awọn ajinigbe, mo foju kan ibọn ti mi o ri ri laye mi"

John Arum Azi nibuba awọn ajinigbe naa, o kunlẹ, o n wo ajinigbe kan to n ba a sọrọ

Oríṣun àwòrán, Others

Ni itẹsiwaju irinajo iṣẹ to wa de abule naa, Azi sọ pe boun ṣe debẹ ni ọkunrin kan waa ba oun.

O ni ọkunrin naa sọ foun pe oun loun maa n pe e lori aago fun iṣẹ.

Lẹyin naa lo ni awọn jọ gun ọkada kan, ọkunrin naa si n gbe oun lọ sinu igbo kijikiji kan, nibi ti ọkunrin mi-in to dihamọra ogun pupọ ti n duro de awọn.

"Mo ri ibọn ti mi o ri ri laye mi. Ọkunrin naa sọ fun mi pe ki n ma bẹru, o ni ọlọdẹ ni ẹni to dihamọra ti mo ri, ṣugbọn ninu ọkan mi, mo mọ pe wahala ti de."

O ni lẹsẹkẹsẹ ni wọn ti fi tulaasi mu oun kunlẹ, wọn si bẹrẹ si I yẹ ara oun wo finni-finni.

Wọn gba foonu lọwọ rẹ gẹgẹ bo ṣe wi, wọn gba apo iṣẹ to gbe wa pẹlu pẹlu awon nnkan mi-in to ni lọwọ ki wọn too ko aṣo to ṣe ajeji si I lọrun, ti wọn si fun un ni iboju lati bo oju rẹ.

Lẹyin eyi ni wọn gbe e lati Kaduna lọ si Zamfara, lẹyin ti wọn fi ọpọ wakati rin irinajo naa pẹlu ọkada, ti wọn n gba inu igbo atawọn ọna to da paroparo.

"A lo to wakati mẹfa loju ọna ka too de ibuba awọn ajinigbe, mo sẹ́ pe mi o ki n ṣe Kristẹni ki wọn ma baa pa mi"

"O fẹẹ to wakati mẹfa ta a fi rin inu igbo lori ọkada, ko si ibudo aabo nibi kankan ta a fi de ibugbe awon ajinigbe naa.

"Nigba ta a debẹ, wọn so ọwọ ati ẹsẹ mi, wọn si pe awon ẹbi mi lati fi ọgbọn miliọnu naira (30m) ranṣẹ bi wọn ba fẹ ki n gba itusilẹ."

Azi sọ nipa bi wọn ṣe fẹẹ lu oun pa, ti wọn si n beere pe iru ẹsin wo loun n ṣe.

"Bi wọn ṣe n beere pe ẹsin wo ni mo n ṣe ni wọn n yinbọn, ibẹru pe wọn le pa mi lo jẹ ki n purọ fun wọn pe mi o ki n ṣe Kristẹni."

Ọmọkunrin naa tẹsiwaju pe lilu alubami ti wọn n lu oun naa lo pada fi han pe Kristẹni loun.

"Laarin kan nigba ti wọn n lu mi yẹn, mo pariwo 'Jesu' lojiji, nigba naa ni won mọ pe Kristẹni ni mi."

"Titi ti mo fi kuro nibẹ, pasitọ ni wọn n pe mi."

O ni bi wọn ṣe fiya jẹ oun to, ohun kan ṣoṣo toun n gba ladura nibẹ ni pe ki Ọlọrum da aabo bo oun.

Adura gbogbo igba ati igbagbọ ninu Oluwa lo ni o gbe oun ro fun gbogbo ọjọ mọkanla ti oun lo nigbekun naa.

Wọn pada din 30m ti won fẹ gba ku si miliọnu mẹfa

John Arum Azi ti wọn fiṣẹ tan wọ akata ajinigbe lati Kaduna lọ si Zamfara.

Oríṣun àwòrán, John Arum Azi

Àkọlé àwòrán, John Arum Azi

Azi ṣalaye pe awon ajinigbe naa pada gba miliọnu mẹfa naira, dipo ọgbọn ti wọn kọkọ beere fun, lẹyin idunaa dura pẹlu awọn ẹbi oun.

Ọ ni won ko tete fi oun silẹ lẹyin ti wọn gba owo naa tan, niṣe ni wọn tun ni awọn yoo gba miliọnu mẹrin naira mi-in si I ti yoo fi me miliọnu mẹwaa.

Azi fi kun un pe wọn tun bẹrẹ si I lu oun nitori afikun miliọnu mẹrin naa, oun si tilẹ ti ro o pe ibi toun yoo pari aye oun si niyẹn ni, koun too pada ri aanu gba.

Akẹkọọ gboye ti iṣẹ sọ ọ dẹni to wọ ibuba iku naa sọ pe oun pada dele loootọ, amọ idaamu ọkan ti iriri naa mu ba oun ko kuro rara.

Bo tilẹ jẹ pe oun n fopẹ f'Oluwa pe oun ko ba iṣẹlẹ naa lọ.