Láì ṣe IVF, obìnrin kan bímọ márùn-ún lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lẹ́yìn tó fi ọdún méjìlá yàgàn

Oríṣun àwòrán, Hiwot Fana Specialised Hospital
Oju to n pọn iṣin ki I ṣe apọnku, apọnla ni.
Eyi ni ọrọ ti ọpọ eeyan n sọ bi won ṣe n ba iya kan to bi ọmọ marun-un lẹẹkan naa naa yọ, lẹyin ọdun mejila to fi sunkun airọmọbi.
Bedriya Adem, ẹni ọdun marundinlogoji (35), ni obinrin naa to bi ibaarun lọjọ Iṣẹgun to kọja, lagbegbe Harari, orilẹede Ethiopia.
Ohun to jẹ kayeefi ju ninu ọrọ rẹ ni pe Bedriya ko lo ilana iloyun igbalode; 'In Vitro Fertilization' (IVF) to fi loyun awọn ọmọ marun-un yii.
Ọkunrin mẹrin, obinrin kan ni awon ọmọ naa.

Oríṣun àwòrán, Hiwot Fana Specialised Hospital
"Ọmọ kan ni mo bẹ Oluwa fun, marun-un lo fun mi lẹẹkan ṣoṣo, ọ̀rọ ẹnu ko le ṣapejuwe ayọ to kun inu ati ọkan mi"
Nileewosan Hiwot Fana Specialised Hospital ti Bedriya bimọ si, oun atawọn ọmọ naa wa ni alaafia ara.
BBC ni ko ṣalaye ayọ rẹ lẹyin to di ọlọmọ marun-un lẹẹkan ṣoṣo, Iya Ibaarun naa si dahun pe:
"Ọrọ ẹnu ko le ṣalaye ayọ mi, emi ti ibanujẹ ati inira ti kun ọkan mi tẹlẹ, ko too di pe adura mi gba.
"Ọmọ kan ṣoṣo ni mo ṣe adua fun, Allah fun mi ni marun-un."
Bedriya ti ko bimọ ri laye rẹ ṣugbọn ti ọkọ rẹ ti bimọ kan ni tiẹ, ṣalaye pe ọmọ ọkọ naa n gbe pẹlu awọn.
O ni ọkọ oun maa n sọ pe ọmọ kan yẹn naa to, koun ma da ara oun laamu pe oun tun n wa ọmọ kiri.
"Ṣugbọn ọkan mi maa n gbọgbẹ pupọ, awọn ara abule maa n beere idi rẹ ti mi o fi rọmọ bi."
Ṣugbọn ni bayii ti ọmọ marun-un ti de lẹẹkan ṣoṣo yii, Bedriya sọ pe ibanujẹ igbaani dabi ohun to ti pẹ gidi ni.
O ni oun ko fẹ maa ranti ọdun mejila toun fi n sunkun ọmọ mọ.
"Mo fi ọdun mejila wa ninu inira, mo n gbe ara mi pamọ, mo si n ṣe adua ni gbogbo igba pe ki n bimọ.
"Nigbẹyin, Allah gbọ ohùn ẹbẹ mi."
A ki i ṣe IVF nibi, Bedriya loyun ọmọ marun-un lai ṣe IVF ni - Dokita Abdulahi
Dokita agba nileewosan naa, Mohammed Nur Abdulahi, sọ pe iya atawọn ọmọ naa yoo ṣi wa labẹ itọju lọsibitu.
Iwọn awọn ọmọ naa bi wọn ṣe ṣe akọsilẹ wọn wa laaarin 1.3 ati 1.4kg (3lb).
Dokita Abdulahi sọ fun BBC pe awọn ọmọ ikoko to ba wọ̀n ju kilo kan lọ, ni anfaani lati yè, ki wọn si dagba bo ṣe yẹ.
Dokita naa ṣalaye pe Bedriya loyun rẹ nilana atọrun wa ti obinrin n gba loyun ni.
O ni ko ṣe IVF rara, ati pe ileewosan oun gan-an ki I ṣe IVF.
Dokita Abdulahi sọ pe ida kan ninu miliọnu marundinlọgọta (55 million) lo le loyun ibaarun lai lo ilana IVF.
Iṣẹ abẹ ni dokita sọ pe awon ṣe fun Bedriya lasiko to n rọbi, to fi bi awon ọmọ naa.
"O gba itọju deede bo ṣe yẹ lasiko to loyun, a si sọ fun un pe ọmọ to wa ninu rẹ ji ẹyọkan lọ.
"O ri itọju to peye gba lasiko iloyun titi to fi bimọ."
Bẹẹ ni Dokita Abdulahi wi.
Bedriya funra rẹ naa ṣalaye pe ọmọ mẹrin ni wọn lo wa ninu oun lati ibẹrẹ, amọ nigba toun bi won tan ni wọn ri I pe marun-un ni.
"Agbẹ alarojẹ ni mi, mi o le pese ohun ti ẹbi mi to ti pọ yoo maa jẹ, amọ mo gbagbọ pe Allah yoo pese"
Nigba to n ṣalaye nipa iṣẹ rẹ, Iya Ibaarun sọ pe agbẹ alarojẹ ti oko rẹ ko ju perete lọ ni oun.
O ni ko da oun loju pe oko naa yoo le gbọ bukaata ọmọ marun-un to wọle tọ ounn wa yii.
O loun ko ti i mọ boun yoo ṣe bọ wọn.
"Ṣugbọn mo gbagbọ pe Allah yoo pese, nipasẹ iranlọwọ awọn eeyan agbegbe mi ati ijọba."
Naif, Ammar, Munzir, Nazira ati Ansar ni wọn sọ awọn ọmọ naa.



























