Ngozi Nwosu, gbajúmọ̀ òṣèré tún ń bẹ̀bẹ̀ fún ₦30m láti ṣiṣẹ́ abẹ mẹ́ta, lẹ́yìn ọdún 13 tó lọ fún ìtọ́jú àìsàn ní Germany

Agba oṣerebinrin Ngozi Nwosu ree nigba ti ara rẹ da ṣaka, ati nigba to wa lori idubulẹ aisan, lasiko to n rawọ ẹbẹ si awọn ololufẹ rẹ lati ran an lọwọ

Oríṣun àwòrán, Ngozi Nwosu/Screenshot

Àkọlé àwòrán, Oṣerebinrin Ngozi Nwosu
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

L'Ọjọbọ, ọsẹ yii ni gbajugbaja agba oṣerebinrin ilẹ Naijiria nni, Ngozi Nwosu pariwo sita lori idubulẹ aisan wi pe ki awọn eeyan ran oun lọwọ, ki wọn ma si ṣe jẹ koun ku lojiji.

Nwosu sọ pe oun nilo ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira lati fi ṣiṣẹ abẹ mẹta ọtọọtọ ti yoo doola ẹi oun lọwọ iku ojiji.

Lati bi ọsẹ mẹta sẹyin la gbọ pe oṣerebinrin nni ti wa nile iwosan, to si ti na ọpọlọpọ owo lati fi tọju ara rẹ, ṣugbọn to jẹ pe agbara rẹ ko gbe awọn owo itọju to n san naa mọ.

"Mo ti wa lori idubulẹ aisan nile iwosan lati bi ọsẹ mẹta sẹyin, ẹ ma jẹ ki n ku, o kọja agbara mi, kii ṣe ohun ti mo le da ṣe"

Ninu fọnran ti Nwosu ṣe, eyi to gbe sori ikanni ayelujara ti Instagram rẹ, lo ti n rawọ ẹbẹ si awọn ololufẹ rẹ, mọlẹbi ati awọn alabaṣiṣẹpọ nidi iṣẹ tiata to yan laayo.

"Ẹyin eeyan mi, ẹyin ololufẹ mi, ẹyin mọlẹbi mi, mo mọ pe o pẹ ti ẹ ti ri mi kaakiri.

Mo ti wa lori idubulẹ aisan nile iwosan lati bi ọsẹ mẹta sẹyin, ẹ dakun, ki ni naa ti kọja agbara mi, ati ohun ti mo le da ṣe," Nwosu sọ bẹẹ.

Siwaju sii lo bẹbẹ pe, "Mo nilo iranlọwọ yin. Ẹ ma jẹ ki n ku. Mo mọ pe gbogbo yin ko tii kọ mi silẹ ri, mo si mọ pe Ọlọrun a ko mi yọ.

Sugbọn mo n bẹ yin, ẹyin ololufẹ mi, ẹyin mọlẹbi mi, ẹ ma jẹ ki n ku, nitori pe ọpọ nnkan ni mo n la kọja, irora nla lo n ba mi finra.

"Mo ṣi ni iṣẹ abẹ mẹta to yẹ ki n ṣe, ẹ dakun ẹ ma jẹ ki n ku. Bi ohunkohun ba wa ti ẹ fẹẹ ṣe fun mi, ẹ dakun, ẹ kan si ileeṣẹ alabojuto mi. Ẹ ṣeun, Ọlọrun a bukun fun un yin.

"Aisan to n ṣe mi ko nii jẹ ipin ẹnikẹni lorukọ Jẹsu. Ẹ ṣeun."

"Apapọ owo ti mo nilo fun gbogbo iṣẹ abẹ yii jẹ ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira"

Bakan naa ninu ọrọ ti Nwosu kọ si abẹ fọnran to gbe jade yii, lo ti jẹ ko di mimọ pe kii ṣe nnkan to rọrun fun oun lati jade sita bẹbẹ fun iranlọwọ.

Ṣugbọn o sọ pe niwọn igba ti ko ti si ọna abayọ miran, lo jẹ koun jade sọrọ.

"Ẹyin ololufẹ mi, ọrẹ mi, molẹbi ati alabaṣiṣẹpọ mi, eyi jẹ ohun le fun mi lati ṣe, ṣugbọn nko le dakẹ mọ, Mo nilo iranlọwọ pajawiri lati ṣiṣẹ abẹ mẹta ti yoo da ẹmi mi si.

"Mo bẹ yin, ẹ ma ṣe kọja lasan. Ẹ ba mi pin ohun ti mo ṣe yii fun gbogbo eeyan lati dide iranlọwọ, ki ẹyin naa si ran mi lọwọ bi ẹ ba lagbara," O kọ ọ bẹẹ.

O tun wa fi kun ọrọ naa pe owo toun nilo lati ṣe awọn iṣẹ abẹ mẹta naa jẹ ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira.

"Apapọ owo ti mo nilo fun gbogbo iṣẹ abẹ yii jẹ ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira. Ọlọrun a bukun fun un yin, ẹ ko si nii mọ ipọnju, to ti wu ko kere mọ," o sọ bẹẹ.

Fidio ti Ngozi Nwosu se si oju opo Instagram rẹ lati bẹbẹ fun iranwọ owo

Oríṣun àwòrán, officialngozinwosu/Instagram

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ ṣáájú nipa aisan Kindinrin to n ba Ngozy Nwosu finra lati ọdun 2013?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Kii ṣe igba akọkọ ree ti agba oṣere naa yoo maa dubulẹ aisan, ti awọn eeyan yoo si maa dide iranlọwọ owo fun un.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọdun 2012 ni Nwosu dubulẹ aisan, to si nilo iranlọwọ owo to pọ diẹ.

Miliọnu mẹfa naira ni Nwosu sọ pe oun nilo nigba naa lati fi ṣisẹ abẹ nilu Oyinbo, to si jẹ pe awọn eeyan dide fun un lọdun naa.

Laaarin oṣu Kejila, ọdun 2012 si osu Kinni, ọdun 2013, miliọnu meji aabo naira ni awọn eeyan ri ko jọ fun agba oṣere ọhun.

Igba ti wọn ko tete ri owo naa ṣa jọ, lo jẹ ki gomina ipinlẹ Eko nigba naa, Babatunde Raji Fashola gbe miliọnu mẹrin aabọ naira kalẹ, ki owo naa le pe fun itọju rẹ.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ Nwosu nigba naa, Seun Oloketuyi ṣe sọ, o ni, "Ijọba ipinlẹ Eko ti san owo to ku ninu owo ti a n gbiyanju lati ko jọ lati ọjọ yii, fun idi eyi, igbesẹ ti bẹrẹ. O ti ṣe gbogbo awọn ayẹwo to yẹ ko ṣe.

"O ti san owo to yẹ ko san si ile iwosan to ti fẹ lọ gba itọju, yoo si mu gbogbo awọn iwe ẹri naa lọ si ileeṣẹ ọkọ ofurufu ti orileede Germany lọjọ Aje. O ṣee ṣe ko tẹsiwaju irin ajo lọsẹ to m bọ pẹlu ogo Ọlọrun."

Iru aisan wo lo da a dubulẹ?

Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to le fidi aisan rẹ mulẹ nigba naa, oniruuru awuyewuye lo jade sita nipa iru aisan to n ba a finra.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe arun kogboogun HIV/AIDS lo ko, bẹẹ ni awọn kan n sọ pe aisan inu jẹjẹrẹ tinu ẹjẹ ni, ṣugbọn ti ko sẹni to le fidi rẹ mulẹ.

Igba to ya ni iroyin miran tun jade sita wi pe aisan to nii ṣe pẹlu ọkan ati kindirin lo gbe Nwosu ṣanlẹ.

A gbọ pe ohun to lọ gba itọju fun nile iwosan ilẹ Gẹẹsi niyẹn, sibẹ, ko sẹni to le fidi rẹ mulẹ.

Ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kejila, ọdun 2012 ni Nwosu farahan lori amohunmaworan, iyẹn lori eto to gbajumọ daadaa nigba naa, eyi ti wọn pe ni 'Who Wants To Be A Millionaire'

Asiko naa lo jẹ ko di mimọ pe irọ to jinna si otitọ ni awuyewuye ti wọn n gbe kaakiri nipa aisan to n ṣe oun, to si loun ko ni arun kogboogun HIV/AIDS.

Ṣeun Oloketuyi lo gba ẹnu rẹ sọrọ lọdun naa, to si jẹ ko di mimọ pe obinrin naa lo sọ f'oun funra rẹ.

Ta a ni Ngozi Nwosu?

Gbajugbaja agba oṣere ni obinrin naa ti wọn bi lọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, ọdun 1963, lo jẹ ọmọ bibi ilu Arochuckwu nipinlẹ Anambra.

Ilu Eko ni obinrin naa dagba si, to si ka gbogbo ẹkọ rẹ nipinlẹ Eko, ko to di pe o bẹrẹ iṣẹ tiata pẹlu awọn ti Yoruba.

O kọkọ lọ silẹ ẹkọ tiata ti Royal Theatre Art Club School labẹ alakoso Fabian Oko.

Oniruuru ere ori itage ni Nwosu ti kopa, to si tun kopa gẹgẹ bii 'Madam V-Boot' ninu ere afihan oloyinbo ti ọlọsẹ-ọsẹ nni, eyi ti wọn pe ni 'Ripples' lọdun naa lọhun.

Nwosu ni ogo rẹ tayọ nigba to kopa ninu agbelewo ti wọn ṣe lede Igbo, eyi ti wọn pe akori rẹ ni 'Living in Bondage'. Bẹẹ ni ko tun gbẹyin ninu ere ọlọsẹ-ọsẹ apanilẹrin nni, 'Fuji House of Commotion', nibi to ti kopa gẹgẹ bii 'Peace'.

Yatọ si pe obinrin yii n ṣiṣẹ tiata, o tun ti kopa ninu awọn orin ti awọn gbajugbaja olorin bii Chidinma Ekile, Fair Prince ati Davido gbe jade.

O jẹ ohun iyalẹnu pe asiko ti agba oṣere yii n palẹmọ fun ayẹyẹ igbeyawo rẹ, lo kede pe oun ko ṣe mọ, lẹyin to fẹsun kan ọlọlufẹ rẹ, wi pe o lu oun toyun-toyun ninu.

Kolonka iṣẹ fiimu agbelewo ti Nwosu ti kopa ninu rẹ, to si jẹ pe bo ṣe gbọ ede Igbo to ti wa, naa lo gbọ ede Oyinbo ati Yoruba dijudiju lai kọ ọ lẹnu.