Kí ló tún wú ọ̀rọ̀ àkọsílẹ̀ Tinubu pẹ̀lú ọlọ́pàá FBI Amẹrika nípà egbòogi olóró síta? Àlàyé rèé

Aarẹ Bola Tinubu wọ buba olomi buluu ati fila

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ aarẹ orilẹede Naijiria ti sọ pe ẹjọ Aarẹ Bola Tinubu pẹlu ọlọpaa FBI to n lọ lọwọ l'Amẹrika lori ọrọ egboogi oloro kii ṣe nnkan to lagbara rara.

Ileeṣẹ aarẹ ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita pe ọpọ eeyan lo ti n sọ ohun ti wọn o mọ nipa igbẹjọ Aarẹ Tinubu nile ẹjọ ijọba apapọ Amẹrika to wa ni Washington DC.

Ẹjọ naa da lori akọsilẹ Tinubu to wa pẹlu ijọba Amẹrika boya nnkan ti gbogbo aye le mọ nipa rẹ ni.

Ọpọ eeyan papaa julọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ni Naijiria lo beere wi pe ki Amẹrika gbe akọsilẹ igbẹjọ Tinubu lori ọrọ egboogi oloro jade.

Ẹgbẹ alatako gbagbọ wi pe awọn aṣiri kan wa nibẹ to le tu sita.

Ileeṣẹ aarẹ sọ ile ẹjọ ko da Tinubu lẹbi nibi igbẹjọ naa rara.

Ki ni ẹjọ naa da le lori?

Ẹjọ naa bẹrẹ lẹyin ti Aaron Greenspan beere fun atẹjade lori ẹjọ naa lọdun 2022 labẹ ofin FOIA orilẹede Amẹrika.

O beere lọwọ awọn ajọ Amẹrika lati fun un ni akọsilẹ igbẹjọ to ni ṣe pẹlu Tinubu.

Amọ, ile ẹjọ kọ lati gbe akọsilẹ naa sita nigba naa.

Ẹwẹ, ileeṣẹ aarẹ ti gbe lẹta kan ti olu ileeṣẹ Amẹrika gba jade lati ọjọ kẹrin oṣu Keji ọdun 2003 eyi ti wọn fi ṣọwọ si ọga agba ọlọpaa Naijiria nigba naa, Tafa Balogun.

Ileeṣẹ aarẹ sọ pe lẹta naa ṣalaye pe ajọ FBI ko ri ẹsun ọdaran kankan ti le fi kan Tinubu tabi fọwọ ofin mu un.

Eleyii ṣẹlẹ nigba ti Tinubu wa nipo gomina ipinlẹ Eko.

Ileeṣẹ aarẹ tun ti pada sori nnkan to wa ninu lẹta naa lori ọrọ akọsilẹ Aarẹ Tinubu.

Ki lo de ti ijọba Amẹrika ko gbe akọsilẹ Tinubu sita?

Awọn ajọ Amẹrika lo ọrọ kan ti wọn pe ni ''Glomar response.''

Ilana yii ni ijọba Amẹrika maa n lo lori iwadii to ba n lọ.

Orilẹede Amẹrika le lo ilana yii lati kede tabi lati dakẹ lori akọsilẹ to le tu aṣiri eto aabo orilẹede.

Lẹyin o rẹyin, ni ile ẹjọ pada gba ẹbẹ CIA wọle ti o si yọ ọfiisi agbẹjọro agba, ọfiisi to ri si ọrọ ilẹ okeere ati ajọ IRS to n pawo wọle kuro ninu ẹjọ naa.

Amọ, lara ẹjọ naa to da lori FBI ati ajọ DEA to n gbogun ti oogun oloro si wa nile ẹjọ.

Ajọ FBI ati DEA gbe iwe oloju ewe 399 jade

Ileeṣẹ aarẹ Naijiria sọ pe ajọ FBI ati DEA gbe iwe oloju ewe 399 jade.

Amọ, olupẹjọ sọ pe ki awọn ajọ gbe awọn nnkan kan to ko si lara ohun ti wọn gbe jade sita.

Ṣugbọn FBI ati DEA sọrọ nipasẹ ẹka eto idajọ wi pe awọn akọsilẹ kan ko gbọdọ lu sita labẹ ofin.

Lara awọn nnkan ti ileeṣẹ aarẹ sọ pe ajọ FBI ati DEA ni awọn akọsilẹ kan wa to nilo idaabobo ti ko gbọdọ lu sita.

Wọn ni agbẹjọro Tinubu tun beere idaabobo akọsilẹ onibaara rẹ eyi lo wa ni ibamu pẹlu ofin FOIA.

Ki lo tun wu ọrọ naa jade bayii?

Igbẹjọ naa to bẹrẹ lọdun 2023 tun ti lu sita eyi tawọn ẹgbẹ oṣelu alatako naa si n beere pe ki ajọ FBI gbe akọsilẹ Tinubu sita.

Amọ, ileeṣẹ aarẹ sọ pe ẹjọ yii kii ṣe ẹjọ ọdaran rara.

Ileeṣẹ aarẹ ni ko si ẹni to fi ẹjọ ọdaran kankan kan aarẹ Naijiria.

Ṣugbọn ọpọ Naijiria lo n kọminu lori ẹjọ ti agbẹjọro Tinubu pe wi pe ki ajọ FBI ma gbe akọsilẹ Tinubu lori egboogi oloro jade.

Eleyii waye pẹlu bi eto idibo 2027 sẹ n kan lẹkun ti Tinubu si fẹ dupo aarẹ fun saa keji.

Ẹjọ yii wa lara nnkan ti ẹgbẹ oṣelu alatako n lo lati ri wi pe Tinubu fidirẹmi ninu ibo aarẹ ọdun 2027.