BBC tú àṣírí àwọn tó ń fi ajá lu jìbìtì orí ayélujára

Aja ti wọn fi aṣọ bo lara
    • Author, Chiara Francavilla
    • Author, Godfrey Badebye
    • Author, Catherine Namugerwa
    • Role, BBC Africa Eye
    • Reporting from, Mityana
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Aworan aja kan kọkọ farahan loju opo TikTok, aja naa wa ninu irora.

Ohun kan to n sọrọ labẹ fidio naa sọ pe aja ọhun ko sinu ijamba ọkọ kan, ẹni naa si rọ awọn eeyan ki wọn maa da owo jọ lati ṣe itọju rẹ.

Laarin ọsẹ diẹ ti fidio naa jade lori ayelujara lọjọ kẹjọ, oṣu Kinni, ọdun to kọja, eeyan bii mejila mii tun ti fi aja kan naa tọrọ owo.

Ẹnikan lati UK sọ orukọ aja ọhun ni Russet, eyii to n ṣafihan awọ aṣọ rẹ.

Ẹgbẹgbẹrun owo dọla lawọn eeyan ti da jọ fun itọju aja naa, sibẹsibẹ, ara aja naa ko da.

Ikọ oluwadii BBC Africa Eye ti ṣawari pe aja naa to wa ni Uganda jẹ eyii ti awọn eeyan kan fi n lu jibiti lati gba owo lọwọ awọn eeyan.

O ṣoro lati sọ ni pato ohun to ṣokunfa ijamba aja naa tabi ibi ti awọn apa ara rẹ ti wa.

Awọn to n lo aja naa ni Uganda n lo aanu ti awọn eeyan mii lagbaye ni fun aja lati fi ọna eburu gba wo lọwọ wọn.

Ninu iwadii BBC, aja naa wa niluu Mityana, to jẹ ibi ti awọn eeyan ti n ṣowo ni ọpọ kilomita siluu Kampala, to jẹ olu ilu Uganda.

Ilu ọhun gbajumọ fun didoola aja.

Awọn onijibiti n iUganda ti ri pe awọn eeyan nilẹ Europe, North America ati Australia fẹran aja, wọn si n lo ifẹ ti awọn eeyan naa ni fun aja lati mọọmọ maa gba owo lọwọ wọn.

Alaga ajọ to n daabo bo ẹranko ni Uganda, Bart Kakooza sọ fun BBC pe "Ọpọ awọn ọdọ ni Uganda lo n gbiyanju lati wa nnkan rere ṣe lori ayelujara.

"Fun awọn mii, wọn n lo ifẹ ti awọn eeyan nilẹ okeere ni fun aja lati lu wọn ni jibiti."

O ṣoro lati sọ ni pato iye oju opo ti wọn ṣi ni Mityana yii, amọ ọpọ oju opo bẹẹ lo ti wa ni Instagram, TikTok, Facebook ati YouTube nibi ti wọn ti n gbe aworan awọn ẹranko ti iya n jẹ lede ti wọn si n bere iranlọwọ fun itọju wọn.

Oju opo Instagram to n ṣafihan ọpọ aworan aja

Lara awọn fidio ti wọn maa n gbe jade ni eyii to n ṣafihan aja ti wọn kọ oniruru akọle si lara.

Lara irufẹ akọle bẹẹ ni "ebi n pa awọn aja wa" tabi "ko si ounjẹ fun awọn aja wa, ẹ ran wa lọwọ."

Wọn maa n ṣafihan ebi ati iṣẹ pẹlu arọwa si awọn to fẹran aja ki wọn fi owo ranṣẹ fun iranlọwọ awọn aja naa.

Iwadii BBC Africa Eye ṣafihan pe awọn fidio naa n ṣiṣẹ daadaa nitori awọn eeyan ọhun n pada ri owo lati ara awọn fidio naa.

Laarin ọdun marun un, iwadii wa fi han pe owo to le ni $730,000 (£540,000) lawọn eeyan ti fi ranṣẹ si Uganda lati ṣetọju aja lati oju opo GoFundMe.

Iwadii wa tun fi han pe nnkan bii ida 40% owo naa lo lọ si Mityana.

Aworan awọn aja ti a so pọ

Nigba ti a ran akọroyin wa lọ sibẹ ni bonkẹlẹ, o ṣawari aja marundinlogun ti wọn ko sinu ago kan ṣoṣo, ti wọn si n sun sinu igbọnsẹ wọn pẹlu ọpọ ebi.

Wọn sọ fun wa pe ile awọn aja ọhun ko wa fun ati tọju wọn lati ibẹrẹ pẹpẹ amọ o wa lati pa owo wọle fun awọn to ni ibẹ.

Ọkan lara awọn onijibiti naa ti akọroyin wa ba sọrọ ni idankọkọ lai mọ pe akọroyin loun n ba sọrọ, Lubajja, sọ pe oniruru ọna ni wọn fi n pa owo ọhun wọle, lara rẹ ni:

  • Wọn maa n dibọn pe onile wọn fẹ le awọn jade, wọn si nilo owo lati gba ibomiran lati maa tọju aja
  • Yiya aworan itọju aja bo tilẹ jẹ pe ko si itọju kankan
  • Fifikun iye owo ti wọn n ta aja ni ilọpo mọkanla
Nicola Baird to n gbogun ti iwa fifi aja lu jibiti ni Uganda
Àkọlé àwòrán, Nicola Baird to n gbogun ti iwa fifi aja lu jibiti ni Uganda

Nicola Baird, oludasilẹ ajọ "We Won't Be Scammed" n ṣewadii, o si n gbogun ti awọn onijibiti naa.

O sọ fun BBC pe "Mo korira awọn onijibiti yii. Iwa buburu gbaa ni wọn n wu."

Wọn ti lu Nicola Baird funra rẹ naa ni jibiti ri lẹyin to fi owo ranṣẹ si Mityana lati tọju aja.

Ni bayii, oun atawọn ogun eeyan mii n gbogun ti iwa jibiti ọhun bayii lẹyin ti wọn gba wọn tan.

 Charles Lubajja lasiko to n ba akọroyin wa sọrọ lai mọ pe akọroyin ni

Charles Lubajja fidi rẹ mulẹ fun akọroyin idakọnkọ wa pe nigba mii awọn onijibiti ọhun maa n mọọmọ ṣe ipalara fun awọn aja naa lọna ati gba owo itọju wọn lori ayelujara.

Amọ o fidi rẹ mulẹ pe ọna ti awọn onijibiti ọhun n lo ti n yatọ si ti atijọ bayii latari pe awọn eeyan ti n fura.

Ajọ We Won't Be Scammed atawọn eeyan mii gbagbọ pe Russet, aja ti a kọkọ mẹnuba jẹ eyii ti wọn mọọmọ kan ẹsẹ rẹ.

Lunajja fi Russet han wa, o si fidi rẹ mulẹ pe ọkan lara awọn aja oun ni.

O ni ọkọ kan lo gba aja naa niwaju ita ile ti wọn n gbe ki wọn to gbe aworan rẹ sori ayelujara fun iranlọwọ.

X-ray Russet

Lẹyinorẹyin, a jẹ ko ye Lubajja pe iwadii jibiti ti wọn n fj aja ṣe la n ṣe, a si bere erongba rẹ lori iwa naa.

Lẹyin to mọ pe akara ti tu sepo tan, o ni oun ko ri Russet ri, koda, o ni ki n ṣe aja oun bo tilẹ jẹ pe o sọ ṣaaju pe oun lo ni aja ọhun.

O tun sọ pe oun ko mọọmọ ṣe ipalara kankan fun ẹranko lati mọọmọ maa fi pa owo wọle.