Àwọn agbébọn ṣèkọlù sínú oko, pa àgbẹ̀ mẹ́rìnlá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Egbinrin ọtẹ bi a ṣe n pana ọkan ni omiran n ru.
Ko din ni agbẹ mẹrinla ti wọn ti padanu ẹmi wọn nigba ti awọn agbebọn tun ṣe ikọlu si awọn ilu meje ni ijọba ibilẹ Isa ati Sabon Birni, ipinlẹ Sokoto.
Iroyin ni niṣe ni awọn agbebọn naa lọ ṣe ikọlu sawọn agbẹ naa lasiko ti wọn n ṣiṣẹ oko lọwọ ninu oko wọn, eyi to ṣokunfa iku eeyan mẹrinla, to si tun da ipaya silẹ laaarin awọn araalu.
Họnọrebu Muhammad Sa'idu Bargaja to n ṣoju ẹkun Isa ati Sabon Birni ni ile igbimọ aṣojuṣofin ni ilu Abuja sọ fun BBC pe awọn agbebọn naa ṣọ igba ti ojo n rọ, tawọn agbẹ naa wa loko lati gbin ireke ki wọn to ṣe ikọlu naa.
O ṣalaye pe ilu Isa, Tidibale, Mansalawa, Tsabar, Hadawa, Masawa ati Gidan Nagor ani wọn ti ṣe awọn ikọlu naa.
O sọ pe yatọ si awọn ti wọn pa, niṣe ni awọn ajinigbe naa tun ji ọpọlọpọ eeyan gbe wọ inu igbo lọ.
Aṣofin naa sọ fun BBC pe ni ọsẹ to kọja ni awọn agbebọn naa ti kọkọ ṣọṣẹ, nibi ti wọn ti ṣe ikọlu sawọn eeyan, ti wọn si pa bii eeyan meje ni awọn ilu ọtọọtọ.
Awọn olugbe awọn agbegbe yii ni ikọlu yii lo n waye nigba lasiko ti eto ọgbin n bẹrẹ ni pẹrẹu, eyi to n da ibẹru sọkan awọn agbẹ lati jina soko.
Niṣe ni ibẹrubojo ti gbilẹ bayii pe o ṣeeṣe ki ipenija aabo to n ba Naijiria finra ni ipa lori eto ọgbin lọdun yii pupọ, paapaa ti ko ba si amojuto to peye lati fi da aabo bo awọn agbẹ.
Ki nipa ti aisi aabo le ni lori ipese ounjẹ ni ọdun yii?
Ipinlẹ Sokoto wa lara awọn ipinlẹ ni ẹkun iwọ oorun ariwa Naijiria nibi ti awọn agbebọn ti n ṣọṣẹ julọ paapaa ni awọn ijọba ibilẹ to paala pẹlu orilẹ ede Niger Republic.
Lati bii ọdun diẹ sẹyin bayii ni awọn agbegbe bii Isa, Sabo Birni, Goronyo, Tangaza ati Gudu ti n koju ipenija ikọlu awọn agbebọn, ijinigbe eyi to ti mu ki ọpọ awọn araalu sa fi ile won silẹ.
Ipenija aabo naa ko mọ ni ipinlẹ Sokoto nikan, niṣe ni awọn ipinlẹ Zamfara ati Katsina ti wọn paala pẹlu Sokoto naa n koju ijinigbe lati fi gba owo, ipaniyan ati ikọlu awọn agbebọn ni gbogbo igba.
Awọn onimọ atawọn alaṣẹ ti fori ipenija sọ aisi aabo to peye lawọn ilu ẹsẹ kuku, bi lilo ohun ija ṣe di tọrọ fọnka sile ati ayipada si igbeaye awọn ni ẹsẹ kuku.
Bakan naa ni wọn ṣekilọ pe ikọlu gbogbo igba sawọn agbẹ maa ni ipa lori ipese ounjẹ ni ọdun yii nitori bi ibẹru ko ṣe jẹ kawọn agbe lọ dako.
Ọpọ awọn olugbe agbegbe yii lo ti ke pe ijọba atawọn ẹṣọ aabo lati ji giri si ojuṣe wọn, ki wọn pọnku igbesẹ wọn lati da aabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan, ki wọn si pese aabo to peye fawọn agbẹ ki asiko ọgbin to wa sopin.

























