Agbébọn jí àbúrò mínísítà fún ohun àmúṣagbára tẹ́lẹ̀, Adebayo Adelabu àti ìbejì rẹ̀ gbé lọ ní Ibadan: ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images/adebayo adelabu
Awọn agbebon ji Aburo minisita fun Ina monamona tẹlẹri ati ọmọ rẹ meji lọ nilu Ibadan
Awọn afurasi agbebọn ti ji aburo obinrin minisita fun ina mọnamọna tẹlẹ, Bayo Adelabu ati awọn ọmọ rẹ ti wọn jẹ ibeji gbe lọ lagbegbe Elewura, Challenge, niluu Ibadan.
Isẹlẹ naa lo waye ni nnkan bii aago meje aabọ arọ oni ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun 2026.
A gbọ pe akoko ti Olaide Busayo Adegoke John-Paul atawọn ibeji rẹ, Peter ati Paul nclọ si ile ẹkọ wọn ni isẹlẹ ijinigbe ọhun waye.
Inu ọkọ ayọkẹlẹ Hundai pupa kan ni awọn eeyan naa wa ninu rẹ ki wọn to ji wọn gbe gẹgẹ biee fọran kan to ti n milẹ titi lori ayelujara bayii ti akọroyin BBC Yoruba ri.
"Aburo mi n palẹmọ lati lọ ba ọkọ rẹ niluu Amerika"
Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ fun awọn akọroyin, Femi Awogboro to jẹ agbenusọ fun Oloye Bayo Adelabu ṣalaye pe lootọ ni awọn agbebọn ji aburo oloṣelu naa lọ toun ti awọn ibeji rẹ.
Atẹjade naa tẹnumo wi pe, inu ibanuje ọkan ni Adelabu ati gbogbo idilẹ wọn wa bayii lẹyin iṣẹlẹ naa.
Idile naa tẹnumọ wi pe awọn ni igbagbọ ninu iṣẹ awọn agbofinro lati ri daju wi pe awọn ti wọn ji gbe ri ominira gba laipẹ.
Arabinrin John-Paul lo ti fi igba kan ri jẹ oṣiṣẹ ile ifowopamo kan ko to kọwe fi ipo naa silẹ to si n gbaradi lati lọ pade ọkọ rẹ to wa ni Amẹrika.
Idile ọhun wa rọ ẹnikẹni to ba ni iroyin to le ran awọn ọlọpaa lọwọ lori ibi ti awọn agbebọn naa gbe arabinrin John-Paul ati awọn ọmọ rẹ mejeji si lati fi to awọn ẹṣọ alaabo leti.
A ti bẹrẹ iwadii - Ọlọpaa
Alukoro ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Oyo, Ayanlade Olayinka ninu atẹjade to fi lede, fidi iṣẹlẹ naa mule.
Ayanlade ṣalaye wi pe ni kete ti ọlọpaa ipinlẹ Oyo gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni wọn ti ran eka ọtẹlẹmuyẹ wọn lati bẹrẹ si n fi imu finlẹ lori ijinigbe ọhun.
Ọlọpaa wa rọ awọn to ba ni iroyin to le ran wọn lọwọ lati yọju ki wọn si sọ ohun ti oju wọn ri.
ileeṣẹ naa rọ awọn olugbe ipinlẹ Oyo lati fi ọkan balẹ nitori ọlọpa yoo sa gbogbo ipa rẹ lati daabo bo ẹmi ati dukia wọn.

























