Afurasí ajínigbé pa ṣọ́jà ní Mowe, ìkejì farapa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nnkan ko fararọ fawọn ologun meji kan lọjọ Aje, ọjọ kẹjọ oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii, nigba ti awọn kan ti wọn fura si pe ajinigbe ni wọn, kọlu agbegbe Magbon -Etido, Mowe nipinlẹ Ogun, ti wọn pa sọja kan, ṣe ikeji leṣe.
Bo tilẹ jẹ pe awọn agbebọn ni awọn ara agbegbe naa tilẹ kọkọ ro pe wọn ya de, ileeṣẹ ọlọpaa Ogun fidi ẹ mulẹ pe iṣẹlẹ naa ki i ṣe ti bandiiti rara.
Magbon-Etido, ni Mowe, wa nijọba ibilẹ Obafemi Owode, ipinlẹ Ogun.
Ki lo ṣẹlẹ gan-an?
Ọwọ aarọ ọjọ Aje naa ni iṣẹlẹ yii waye gẹgẹ bi awọn o ṣoju mi koro ṣe sọ.
Olugbe agbegbe naa kan ti ko darukọ ara rẹ nitori aabo, ṣalaye pe toguntogun ni awọn ajinigbe naa de.
O ni bi wọn ṣe de ni wọn dojukọ ibi ti wọn fẹẹ kọlu.
Bakan naa ni fọnran ohun kan to jade lori ayelujara, ti ẹnikan to pe ara rẹ ni Jimoh Owolabi to ni oun ni Alaga agbegbe Onidagbasoke Ajumoni ṣe, ṣalaye pe ọkunrin kan to n wa kusa yẹpẹ, ti awọn mọ si Kapo, ni awọn ajinigbe naa fẹ ji gbe lọ.
Lati dena ijinigbe naa ni awọn ṣọja meji to n ṣọ Kapo fi koju awọn ajinigbe ọhun bo ṣe wi, nigba naa si ni wọn yinbọn fun wọn.
Jimoh tẹsiwaju pe ibọn naa lo pa ṣọja kan, ti ikeji si faragbọta ṣugbọn ti ko ku ni tiẹ.
"Ko si bandiiti ni Magbon, awọn ajinigbe lo wa koju awakusa yẹpẹ kan ta a mọ si Kapo.
"Lasiko ikọlu naa ni ẹṣọ to n ṣọ ọ pade iku, ti ikeji rẹ si farapa."
Bẹẹ ni fọnran ohun to jade lori ayelujara naa ṣalaye, pẹlu afikun pe iroyin eke ni pe bandiiti ti wọ Magbon Etido, ni Mowe, ipinlẹ Ogun.
O fi kun un pe awọn ọlọpaa, ologun atawọn ẹṣọ alaabo mi-in ti wa ni lagbegbe naa tẹlẹ ti wọn n ṣọ ibẹ, kawọn eeyan yee gbe ohun ti ko ṣẹlẹ kiri.
Alaye ileeṣẹ ọlọpaa Ogun
Lalẹ ọjọ Aje naa ni Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Oluseyi Babaseyi, fi atẹjade kan sita lori iṣẹlẹ yii.
Ninu atẹjade naa lo ti fidi iku ṣọja kan mulẹ, ati pe ikeji n gba itọju nileewosan.
DSP Babaseyi sọ pe ko sohun to jọ bandiiti tabi agbebọn ninu iṣẹlẹ ọhun, bi ko ṣe pe iṣẹlẹ iwa ọdaran lasan ni.
"Lẹyin iṣẹlẹ naa, ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu ajọṣepọ awọn ologun, tete ko awọn ẹṣọ alaabo lọ si agbegbe naa, wọn si bẹrẹ iṣẹ lati mu awọn to lọwọ si i.
"Iwadii wa ko fi han pe iṣẹlẹ naa ni ohunkohun lati ṣe pẹlu bandiiti, bẹẹ ni iwadii ati iṣẹ ọpọlọ n lọ lọwọ."
O fi kun alaye naa pe ki araalu fi ọkan balẹ, ohun gbogbo wa labẹ akoso pẹlu bawọn ṣe ti ṣafikun agbofinro sagbegbe naa.
























