Ìtàn mánigbàgbé: Bí ilà kíkọ ṣe bẹ̀rẹ̀ nílẹ̀ Yorùbá àti bí wọn ṣe fi ilà kíkọ kó ìlú kan lógun

Ọkunrin mẹta joko, ọkan kọ ila mẹjọ ninu wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ní ilẹ Yoruba, ila kíkọ jẹ ohun pàtàkì láyé àtijọ́ torí ó ń jẹ ka dá àwọn èèyàn ìlú kan tàbí ẹbi kan mọ yàtọ̀ sí òmíràn.

Bi o tilẹ jẹ pe ọ̀pọ̀ ìlú àti ẹbi ni kò fi bẹẹ kọ ila mọ lóde òní àmọ́ anfaani ila kíkọ láyé àtijọ́ kii se kékeré.

Lásìkò yìí, ọ̀pọ̀ ọmọ Kaarọ Oojire ni ko mọ ìtàn tó rọ̀ mọ́ ila kíkọ àti bó ṣe bẹ̀rẹ̀.

Ìdí rèé tí BBC News Yorùbá ṣe wọ inú ìtàn lọ, láti ṣe ilanilọyẹ lórí ohun tó fà á, tí ìran Yoruba ṣe ń kọ ila.

Bákan náà, a tún mọ ọna ti wọn gba fi ogún ja ìlú kan, ko ìlú kan lẹru torí ilà kíkọ.

Obinrin agbalagba to kọ ila

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹ́gẹ́ bi ìtàn ṣe fi yẹ wá látinú ìwé ìtàn nípa ilẹ Yoruba ti Àlùfáà Samuel Johnson kọ, aye Alaafin Sango nilu Oyo ni ìtàn ila kíkọ ti bẹ̀rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ́, Sango jẹ ọmọ bibi inú Oranmiyan tíì ṣe ọmọ Okanbi to jẹ ọmọ Oduduwa tíì ṣe ẹni to ṣẹ ìran Yoruba silẹ.

Lara awọn ọmọ Oranmiyan ni Sango àti Ajaka, tíí ṣe Aláàfin kẹrin nilu Oyo, to jẹ ìlú to tóbi, tó sì ń ṣe akoso ilẹ̀ Yorùbá lapapọ.

Sango jẹ alágbára tí kò gbà gbẹrẹ, ó ní ẹ̀rù lára pupọ, ó sì máa ń yọ èéfín àti iná ni ẹnu èyí tó mú káwọn èèyàn bẹru rẹ pupọ.

Bákan náà, ọba ìlú Òwu, tí a mọ̀ sí Olowu náà lágbára pupọ, kódà ju ọba Ọ̀yọ́ lọ nígbà náà,

Sango jẹ alagbara, ọ̀pọ̀ èéfín àti iná ń yọ ní ẹnu àti ihò imú rẹ èyí tó ba ni lẹru pupọ

Bi Oranmiyan to tẹ ìlú Oyo do sì ṣe wàjà, tí Ajaka jọba, ní Olowu pàṣẹ fáwọn èèyàn ìlú Oyo láti máa san isakọlẹ fún òun.

Aláàfin Ajaka jẹ ọba oníwà tútù bíi àdàbà, isakọlẹ to gba láti san fún Olowu sì ló mú káwọn èèyàn ìlú Oyo ṣe rọ ọ lóye Aláàfin.

Lẹyin rẹ ni wọn fi Sango jẹ Aláàfin, ó sì jẹ ọmọdé, bẹ́ẹ̀ ni Olowu tún fẹ rẹ ẹ jẹ torí pé ọmọdé ni.

Àmọ́ Ata kéré, ìjà jù ú ní Aláàfin Sango, bí Olowu ṣe tún pàṣẹ fún un láti máa san isakọlẹ fún òun, ní Aláàfin Sango fọnmú.

Sango ni láéláé, òun kọ́ lè forí balẹ̀ fún Olowu tàbí kí òun sìn-ín, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olowu dunkooko láti kó aya àtàwọn ọmọ rẹ ni ẹrú.

Lẹyin ó rẹyìn, ìjà ńlá bẹ silẹ nílùú Oyo laarin Olowu àti Aláàfin Sango, Olowu sì kó ogun wọ ìlú Oyo.

Sango àfihàn agbára rẹ, o dúró bíi Akọni to jẹ, ọ̀pọ̀ èéfín àti iná ń yọ ní ẹnu àti ihò imú rẹ èyí tó lágbára pupọ.

Ọkunrin kan to kọ ila mẹrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Òkò ni ibujoko ìjọba Oyo nigba naa, èyí tí wọn ń pè ní Ọ̀yọ́korò, Aláàfin Sango sì ń gbìyànjú láti kó ibujoko ìjọba wá sí Ọyọ

Wọn ni bí ọmọdé bá dé ibi ẹ̀rù, ẹ̀rù yóò bá a, jinni-jinni bo Olowu atawọn ọmọ-ogun rẹ, ṣe ni wọn fojú ìjà silẹ, wọn salọ kúrò lójú ogún.

Lẹyin èyí, Sango já ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun, ó sì ṣẹgun, ó di ẹrú jẹjẹ tí gbogbo èèyàn ń bẹru rẹ, o si di Aláàfin tí ẹnikẹni kò le gbe iná woju rẹ.

Láyé ìgbà náà, ìlú Òkò ni ibujoko ìjọba Oyo, èyí tí wọn ń pè ní Ọ̀yọ́korò lásìkò náà, tí Aláàfin Sango sì ń gbìyànjú láti kó ibujoko ìjọba wá sí Ọyọ.

Lọ́nà àti mú àfojúsùn rẹ yìí ṣẹ, Sango fẹ́ rúbọ ní ojú orori ìyá rẹ àmọ́ kò mọ orúkọ ìyá rẹ mọ torí pé ọmọ ọwọ́ lo wa nígbà tí ìyà rẹ kú.

Iya Sango jẹ ọmọọba Elempe tíì ṣe ọba Nupe tí a tún mọ si Tapa.

Èyí sì lo mú kí Sango rán Tetu, iranṣẹ rẹ àti Hausa kan to jẹ ẹrú rẹ láti lọ bá Bàbá ìyá rẹ tíì ṣe Elempe pé ko fun òun ni ẹṣin àti màálù tí òun yóò fi ṣe ìrúbọ ètùtù to fẹ ṣe náà.

Wọn fi abẹ ya ara ati ojú ẹrú Sango ni ọna mejilelọgọfa (122) gẹ́gẹ́ bíi ìjìyà rẹ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àmọ́ Sango kìlọ̀ fún Tetu àti ẹrú rẹ náà pé tí awọn Nupe ba ti n se ètùtù naa ni ojú orori ìyá òun, kí wọ́n tẹti silẹ láti gbọ orúkọ ìyá òun ti wọn yoo da lásìkò tiwọn bá ń pe ọfọ̀, kí wọ́n sì wá sọ orúkọ náà fún òun, torí orúkọ ìyá òun ni.

Àmọ́ nígbà tí wọn dé ilẹ̀ Nupe, Elempe, baba ìyá Sango gba Tetu àti ẹrú to tẹle náà tọwọ tẹsẹ, wọn ṣe wọn ní àlejò pupọ, àmọ́ ẹrú gbàgbé ohun tí wọn ba lọ, ó sì mú ọtí yo.

Àmọ Tetu ko ara rẹ ní ìjánu, ó fetí silẹ lásìkò tí wọn ń pè ọfọ̀ lójú orori Iya Sango.

O gbọ ti ẹni tó ń ṣe ètùtù náà ni "Torosi, ìyá Gbodo, tẹti si wa, ọmọ rẹ Sango lo wa ṣe ètùtù fún ọ"

Tetu tètè ṣe àkíyèsí ọ̀rọ̀ náà, ó sì fi pamọ́ ṣùgbọ́n ẹrú to mú dání tí mutí yo, kò sì rántí ohunkóhun tí wọn sọ nibẹ.

Nígbà tí wọ́n padà dé ọdọ Sango, Tetu nìkan lo jisẹ naa dáadáa, tí ẹrú kò sì lè sọ ohunkóhun, ìdí rèé tí Sango ṣe ni kí wọn fi ìyà ńlá jẹ ẹru, o si fún Tetu ni ọpọlọpọ ẹ̀bùn.

Wọn fi abẹ ya ara ati ojú ẹrú náà ni ọna mejilelọgọfa (122) gẹ́gẹ́ bíi ìjìyà rẹ.

Ojú ọgbẹ ti wọn ti na ẹru jìnnà, ó sì di ojú àpá to rẹwà pupọ, èyí tí àwọn ayaba atawọn ọmọọba ń jowú rẹ

Nígbà tí ojú ọgbẹ náà jìnnà tán, ó sì di ojú àpá to rẹwà pupọ, èyí tí àwọn ayaba atawọn ọmọọba ń jowú rẹ.

Wọn wá sọ pàṣẹ pé àwọn ìdílé ọba nìkan ni kí wọn máa ya ni abẹ́ báyìí, kí ìyàtọ̀ le e wa laarin awọn ìdílé ọba àti aráàlú.

Sango gan fúnra rẹ lo kọkọ fa ara rẹ kalẹ fún àwọn Olowola, tí a tún mọ si Oloola, orúkọ wọn ní jẹ́ Babajegbe Ọsan àti Babajegbe Òru.

Àmọ́ eemeji péré ni wọn yà Aláàfin Sango ni abẹ́ ni apa otun àti Òsì, to fi yarí pé òun kò le fara da oro abẹ náà mọ.

Ila apá ọ̀tún àti òsì yìí ni wón ń pè ní Ẹyọ, wọn si n kọ abẹ́ méjì yìí ni ìdílé ọba titi di òní èyí tó jẹ́ àmì ìdámọ̀ ni ìdílé ọba.

Ìdí rèé tí wọn ṣe ń pè àwọn ìdílé ọba ní Akẹ́yọ̀ èyí tíì ṣe àpá to la láti ọrùn ọwọ́ dé èjìká.

Obinrin kan to lo ibori alawọ buluu fa ila kọọkan soju, o n rẹrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi Sango se lo ilà kíkọ láti kó ogun ja ìlú Ọ̀yọ́korò, kò lè gbé ibujoko ìjọba Oyo kúrò ni Oyokoro

Lẹyin ti ojú ọgbẹ ara Sango àti ìdílé ọba san tán, Aláàfin wá ronú jìnlẹ̀ pé òun le lo ìlànà ila kíkọ náà láti kó ogun ja ìlú Ọ̀yọ́korò.

O wa fi ẹrú tí wọn fi abẹ́ yà ara rẹ ránṣẹ́ si Ọlọ́yọ̀ọ́korò pe ko wo bí ara rẹ ṣe ni ẹwà tó pẹlu ila kíkọ.

O fikùn pé, àwọn ìdílé ọba tí òun ti gba lati maa kọ ila yìí, tí òun sì ń rọ Olọ́yọ̀ọ́korò láti kọ ila náà fún ara rẹ àti ìdílé rẹ gẹ́gẹ́ bíi àmì ìdámọ̀ fún ìdílé ọba.

Bákan náà, Sango ni òun fúnra òun ti kọ ila náà, tó sì gba Olọ́yọ̀ọ́korò ni Ìmọ̀ràn láti tún kọ ila náà fáwọn ìjòyè àti jagunjagun rẹ.

Olọ́yọ̀ọ́korò gba láti ṣe bẹ́ẹ̀, wọn si rán àwọn Oloola méjèèjì, Babajegbe Ọsan àti Babajegbe Òru lọ sí Ọ̀yọ́korò láti lọ kọ ila fún wọn nibẹ.

Àmọ́ nígbà tó di ọjọ́ kẹta tí Olọ́yọ̀ọ́korò, ìdílé ọba, àwọn ìjòyè àtàwọn jagunjagun rẹ kọ ìlà tán, tí oró ojú ọgbẹ náà sì ń kàn wọn gidigidi, Aláàfin Sango kò ogún ja ìlú náà.

O pa Olọ́yọ̀ọ́korò, àwọn ìdílé rẹ àtàwọn ọ̀pọ̀ èèyàn nilu náà, ó sì gbé ibujoko ijoba kúrò ní ìlú Òkò wá sí ìlú Oyo tí a tún mọ si Katunga.