Wo orúkọ àwọn ọmọ Naijiria 124 tí Amẹrika kéde pé àwọn yóò lé kúrò lórílẹèdè náà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹede Amẹrika ti kede orukọ awọn ọmọ Naijiria mẹrinlelọgọfa ti wọn fẹ le kuro lorilẹede naa.
Eyi wa lara awọn atunṣe lori eto bawọn eeyan ṣe wọle si orilẹede Amẹrika ati bi wọn ṣe n jade ti ijọba n ṣe.
Ọrọ yii lo wa ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ijọba Amẹrika to n ri si ọrọ abẹnu fi lede lori itakun ayelujare wọn.
Ileeṣẹ naa sọ pe awọn eeyan mẹrinlelọgọfa yii jẹ awọn ọdaran ti wọn ko ni iwe igbeluu lọwọ.
Ajọ Amẹrika yii ṣalaye ninu atẹjade to fi sita ọhun pe awọn ẹṣọ ICE ati DHS n ṣiṣẹ takun takun lori ileri Aarẹ Donald Trump lati le awọn olugbe Amẹrika to ko ni iwe igbeluu lọwọ danu.
Orukọ awọn eeyan naa gẹgẹ bi o ti wa lori ikanni ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ abẹnu naa ni Sunday Adediora, Sunday Kunkushi, Mkpouto Etukudoh, Marcus Unigwe, Olaniyi Ojikutu, Boluwaji Akingunsoye, Ejike Asiegbunam, Emmanuel Mayegun Adeola, Bamidele Bolatiwa, Ifeanyi Nwaozomudoh, Aderemi Akefe, Solomon Wilfred, Chibundu Anuebunwa, Joshua Ineh, Usman Momoh, Oluwole Odunowo, Bolarinwa Salau, ati Oriyomi Aloba.
Awọn mii ni Oludayo Adeagbo, Olaniyi Akintuyi, Talatu Dada, Olatunde Oladinni, Jelili Qudus, Abayomi Daramola, Toluwani Adebakin, Olamide Jolayemi, Isaiah Okere, Benji Macaulay, Joseph Ogbara, Olusegun Martins, Kingsley Ariegwe, Olugbenga Abass, Oyewole Balogun, Adeyinka Ademokunla, Christian Ogunghide, Christopher Ojuma, Olamide Adedipe, Patrick Onogwu, Olajide Olateru-Olagbegi ati Omotayo Akinto.
Lara awọn to tun wa ninu awọn ti wọn fẹ le kuro l'Amẹrika ọhun tun ni Kenneth Unanka, Jeremiah Ehis, Oluwafemi Orimolade, Ayibatonye Bienzigha, Uche Diuno, Akinwale Adaramaja, Boluwatife Afolabi, Chinonso Ochie, Olayinka A. Jones, Theophilus Anwana, Aishatu Umaru, Henry Idiagbonya, Okechukwu Okoronkwo, Daro Kosin, Sakiru Ambali, Kamaludeen Giwa, Cyril Odogwu, Ifeanyi Echigeme, Kingsley Ibhadore, Suraj Tairu, Peter Equere, Dasola Abdulraheem, Adewale Aladekoba ati Akeem Adeleke.
Bernard Ogie Oretekor, Abiemwense Obanor, Olufemi Olufisayo Olutiola, Chukwuemeka Okorie, Abimbola Esan, Elizabeth Miller, Chima Orji, Adetunji Olofinlade, Abdul Akinsanya, Elizabeth Adeshewo, Dennis Ofuoma, Quazeem Adeyinka, Ifeanyi Okoro, Oluwaseun Kassim, Olumide Bankole Morakinyo, Abraham Ola Osoko, Oluchi Jennifer atiChibuzo Nwaonu naa wa lara awọn ọmọ Naijiria ọhun.
A gbọ wi pe igbesẹ yii wa lara eto ti Aarẹ Trump n ṣe lati le awọn ti ko ni iwe igbeluu lọwọ kuro lorilẹede Amẹrika lati ogunjọ oṣu Kinni to ti pada sfori aleefa gẹgẹ bii aarẹ Amẹrika.



























